Ìjọba ológun orílẹ́èdè Niger ti fòfin iléeṣẹ́ ìròyìn BBC

Oríṣun àwòrán, AFP
Ijọba ologun orilẹede Niger ti fofin de ileeṣẹ iroyin BBC fun oṣu mẹta lori ẹsun pe o n gbe iroyin ofege nipa orilẹede naa kiri.
Ijọba ologun to wa lori oye lorilẹede naa sọ pe iru awọn iroyin ti BBC n gbe yii le da omi alaafia ilẹ naa ru, ati pe irufẹ iroyin bẹẹ tun le domi tutu s'awọn ọmogun to n doju ija kọ awọn alakatakiti ẹsìn lọkan.
Minisita eto iroyin lorilẹede naa, Raliou Sidi Mohamed, lo kede igbesẹ ijọba naa.
Awọn eto ti BBC n ṣe lede Hausa to jẹ ede t'awọn eeyan orilẹede naa n sọ julọ ati awọn eto mii lede Faranse ni eeyan to din diẹ ni miliọnu meji ati aabọ n gbọ lọdun yii nikan.
Iye awọn eeyan yii si jẹ ida mẹtadinlogun awọn eeyan to ti dagba ni Niger.
Bo tilẹ jẹ pe, ijọba Niger ti da eto redio BBC duro, awọn eeyan si lanfaani lati lọ sori ikanni BBC Hsusa fun iroyin.
Ijọba Niger ko sọ eto kan gboogi to bi igbesẹ yii, amọ, BBC gbe iroyin kan jade lọjọ Iṣẹgun eyi to sọ pe awọn alakatakiti ẹsìn kan ṣekupa sọja mọkanlelaadọrun un atawon araalu to din diẹ ni aadọta.
Ijọba ologun Niger ni iroyin yii ko lẹsẹ nlẹ, ati pe o jẹ iṣẹ ọwọ awọn ọta orilẹede Niger ti wọn dami tutu s'awọn ọmogun lọkan.
Ileeṣẹ iroyin orilẹede France, France24 ati ileeṣẹ redio RFI ni ti di didaduro lati igba t'awọn ologun ti gba ijọba losu Keje lọdun 2023.
Nnkan o fararọ fun Ileeṣẹ ologun Niger lori b'awọn ajijagbara alakatakiti ẹsìn sẹ n tẹsiwaju si maa ṣe ikọlu s'awọn ọmogun.
Ara nnkan ti ijọba ologun sọ nigba ti wọn gbajọba ni pe awọn yoo ṣegun awọn alakatakiti ẹsìn to n da omi alaafia Niger ru.
Ni gbogbo awọn orilẹede iwọ oorun Afrika bii Mali, Burkina Faso, Niger ati Mali ti ologun ti gbajọba ni wọn dawọn ileeṣẹ iroyin ilẹ okeere duro.
Ọkan gboogi lara iṣoro t'awọn orilẹede yii n koju ni awọn ajijagbara alakatakiti ẹsìn lẹkun Sahel ni iwọ oorun ilẹ Afirika.
Fun apẹẹrẹ, agbegbe Tillaberi ni Niger jẹ agbègbè to lewu gan an lẹgbẹ ibode Mali ati Burkina Faso.















