Ìdí tí ìjàmbá ọkọ̀ tó ṣẹlẹ̀ sí ẹbí mi fi jẹ́ nǹkan mánigbàgbé - Tijani Babangida

Aworan Tijani Babangida ati Maryam Waaziri

Oríṣun àwòrán, Maryam Waziri

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Agbabọọlu fun ikọ Super Eagles tẹlẹ ri, Tijani Babangida, ti sọ pe ọjọ ti oun ko le gbagbe laelae lọjọ ti ijamba ọkọ ṣẹlẹ soun ati ẹbi oun lopopona Kaduna si Zaria.

Babangida ni iyawo oun to jẹ gbajumọ oṣere tiata Hausa, Maryam Waziri padanu oju rẹ kan ninu ijamba ọkọ naa.

Bakan naa ni o sọ pe Maryam tun ṣe iṣẹ abẹ lori awọ ara latari akoba ti ijamba naa ti ṣe sara rẹ.

Ni ọjọ kẹsan an oṣu Karun un ọdun yii ni ijamba ọkọ naa ṣẹlẹ si ẹbi Babangida ninu eyi ti aburo rẹ ọkunrin, Ibrahim Babangida ti padanu ẹmi rẹ.

Ninu ifọrọwerọ ti o ṣe laipẹ yii pẹlu ikọ agbabọọlu Ajax eyi to ti gbabọọlu fun un tẹlẹri ni o ti sọ pe oun si maa n ranti iṣẹlẹ laabi yii ni gbogbo igba.

Lódun 2021 ni Maryam Waziri, gbajugbaja oṣere tiata Kannywood Hausa ṣe igbeyawo pẹlu Babangida.

Iyawo mi ko le ranti nkan kan mọ lẹyin ijamba ọko ti a ni - Babangida

Loju ẹsẹ ni Ibrahim to aburo Tijani Babangida ku ninu iṣẹlẹ ijamba ọkọ naa, nigba ti ọmọ rẹ to kere julọ, Fadil, ku nile iwosan lẹyin ọjọ diẹ.

Ẹni to n bawọn tọju ile toun naa wa ninu ọkọ pẹlu wọn kan lẹsẹ.

Babangida ni oun naa fẹsẹ ṣeṣe ninu ijamba ọkọ ọhun.

Agbabọọlu Super Eagles tẹlẹ ri ni iyawo oun ni ifarapa to pọ eyi to jẹ koun gbe lọ si orilẹede Netherlands fun itọju.

Babangida sọ pe iyawo oun ko ranti nkan kan mọ lẹyin to lo oṣu mẹta nile iwosan lorilẹede Netherlands.

O ni nigba naa loun sọ fun Maryam iyawo oun pe ọmọkunrin awọn to kere julọ naa fara kaasa ninu ijamba ọkọ naa, amọ, Babangida ni ko tiẹ ranti orukọ rẹ gan an mọ tori ko le ranti nkan kan mọ.

Babangida ko ṣai gboriyin fun ikọ agbabọọlu Ajax to gba bọọlu fun tẹlẹ pẹlu bi wọn ṣe ṣe iranlọwọ fun un.

O ni ikọ agbabọọlu Ajax lo bẹrẹ si ni kowo jọ foun lati tọju iyawo oun ti yoo wa nile iwosan fun ọdun kan.