Wo àwọn ọ̀nà tí o lè fi dáàbò bo ọmọ rẹ níbi àpéjọ elérò púpọ̀

Eero to pọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

    • Author, Olumide Owaduge
    • Reporting from, Lagos, Nigeria
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Inu ọsẹ yii ni iṣẹlẹ abaninujẹ kan waye niluu Ibadan ti ẹmi ọmọde marundinlogoji sọnu si.

Gẹgẹ bii iroyin ṣe sọ, Olori Ooni Ile-Ife nigba kan, Naomi Silekunola Ogunwusi lo ṣe agbekalẹ eto kan lati fun araalu ni ounjẹ ọdun ọfẹ, to fi mọ eto ẹkọ ọfẹ, ninu eyii to pe ọpọ awọn ọmọde si.

Amọ ibanujẹ nla lo jẹ pe awọn eeyan tẹ ara wọn pa nibi eto naa, ti awọn mii si dero ile iwosan.

Ọpọ eeyan lo ti bẹrẹ si n ba awọn obi awọn ọmọ naa kẹdun kaakiri agbaye lẹyin iṣẹlẹ ọhun.

Lara awọn to ti fi ọrọ ikẹdun ranṣẹ ni Aarẹ Naijiria, Bola Ahmed Tinubu, atawọn mii.

Wayi o, ọpọ eeyan lo n woye irufẹ aṣiṣe to ṣe e ṣe ko waye ni gbagede eto naa to fi di pe wọn n tẹ ara wọn pa nibẹ, eredi ree ti BBC Yoruba fi ṣe akojọpọ awọn alakalẹ to yẹ ko waye ṣaaju irufẹ eto bayii.

Awọn alakalẹ ti a ko jọ yii wa fun awọn to gbe eto kalẹ ati fun awọn ti yoo kopa ninu irufẹ eto bẹẹ, paapaa awọn ti yoo ko ọmọ wọn lọ si irufẹ eto bẹẹ.

Bakan naa ni awọn ilana yii wulo fun oniruuru ayẹyẹ - igbeyawo, ọjọ ibi, oku agba, iṣile, ati bẹẹbẹẹ lọ.

Awọn ohun to yẹ ki ẹni to n gbe eto kalẹ ṣe

Crowd control

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Kede gbedeke iye eeyan ti eto naa wa fun

O gbọdọ ṣe eyii ni ọjọ diẹ ṣaaju eto ọhun lọna ati dena ero to pọju ni gbagede eto.

Iforukọsilẹ ṣaaju eto - O ṣe pataki lati ṣe eto iforukọsilẹ awọn ti o fẹ wa si gbagede eto naa, iyẹn lẹyin ti o ba ti kọkọ kede iye eeyan ti o ṣetan lati gbalejo wọn.

Ni kete ti iye eeyan ti o n reti ba ti to, o gbọdọ tun kede faraye pe o ko ni le gba awọn mii mọ.

Ya bi gbagede eto naa yoo ṣe ri – lara eyii ni mimọ ibi ti awọn eeyan yoo duro tabi joko si, ibi ti wọn yoo gba wọle ati jade, ibi ti awọn eeyan ko gbọdọ gba kọja, ibi ti wọn le ṣe igbọnsẹ si, eti bẹẹ lọ.

Ṣe idanilẹkọọ fun awọn oṣiṣẹ rẹ – Lara idanilẹkọọ naa ni bi wọn yoo ṣe maa dari awọn eeyan ati ohun ti wọn gbọdọ ṣe ti iṣẹlẹ pajawri ba waye.

Gbe oniruru akọle si gbagede eto – Lara awọn akọle naa ni ibi ti awọn eeyan ko gbọdọ de, ibi ti wọn le gba wọle ati jade, ati bẹẹ lọ

Gba awọn ẹṣọ alaabo to mọ iṣẹ – Ko si ẹni to le ko iyan awọn akọṣẹmọṣẹ ẹṣọ alaabo kere nibi ti ero ba pọ si. Nitori naa o ṣe pataki ki wọn wa nibẹ lati ba ọ dari awọn ero.

Awọn ohun to yẹ ki o ṣe ti o ba n mu ọmọ rẹ lọ ibi apejọ elero pupọ

Wọ aṣọ to tan – Wọ aṣọ to tan tabi to n dan fun ọmọ rẹ ki o le tete da a mọ laarin ọpọ ero ti wahala ba ṣẹlẹ.

Ami idanimọ – Fun ọmọ rẹ ni ami idanimọ fun ayẹyẹ naa. Fun apẹrẹ, o le so nnkan mọ ọwọ rẹ tabi o kọ orukọ rẹ̀ ati nọmba ẹrọ ilewọ rẹ si ara aṣọ ọmọ naa.

Kọ ọmọ rẹ ni ohun to yẹ ko ṣe lasiko pajawiri – Ki ẹ to kuro nile, o gbọdọ jẹ ko ye ọmọ rẹ awọn ohun ti ko gbọdọ ṣe, ibi ti ko gbọdọ ya si, paapaa o gbọdọ jẹ ko mọ pe ko gbọdọ jina si iwọ tabi agbalagba to ba tẹle lọ gbagede naa.

Fenukọ lori ibi ipade – Ni kete ti ẹ ba ti de gbagede eto iwọ ati ọmọ rẹ gbọdọ fẹnuko lori ibi ti ẹ o ti pade lasiko pajawiri.

Fi 'tracker' si ọmọ rẹ lara – O le ra aago to ni imọ ẹrọ ti yoo maa sọ ibi ti ọmọ rẹ wa fun ọ ni gbogbo igba. Irufẹ aago ọwọ bẹẹ yoo wulọ ti rogbodiyan ba bẹ silẹ fun ọ lati tete wa ọmọ rẹ ri, yoo si tun wulọ un ọ lọjọ mii.