Ìjọba FCT gba ilẹ̀ lọ́wọ́ Buhari Foundation, Akume, Okorocha, Melaye àti àwọn mìí nítorí gbèsè

Oríṣun àwòrán, Nigeria Presidency
Minisita fun FCT, Nyesom Wike ti buwọ lu gbigba ilẹ awọn gbajugbaja oloṣelu kan ti wọn ra silu Abuja lori ẹsun wi pe wọn kọ lati san owo iwe-ẹri emi-ni-mo-ni-ilẹ, eyi ti a mọ si 'CofO' fun ọdun pipẹ.
Agbegbe Maitama to wa niluu Abuja, FCT ni awọn ilẹ naa wa, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.
Ilẹ kan to jẹ ti alaanu to ni nnkan ṣe pẹlu aarẹ Naijiria tẹlẹ, Mohammadu Buhari; ilẹ gomina ipinlẹ Imo tẹlẹ, Rochas Okorocha; gomina ipinlẹ Benue tẹlẹ, George Akume, Dino Melaye to ti fi igba kan jẹ ọmọ ile aṣofin, ati awọn miran wa lara awọn ti minisita kede pe awọn ti gba ilẹ wọn pada.
Owo to le diẹ ni biliọnu kan (N1.234bn) naira ni wọn sọ pe ajọ Muhammadu Buhari Foundation jẹ lori ilẹ ti wọn ya sọtọ fun wọn.
"Lẹyin ti asiko oore ọfẹ ti Minisita fun ilu Abuja fun wọn ti pe...a ti gba awọn iwe aṣẹ ati iwe ẹri awọn ilẹ ati dukia naa pada," awọn alakoso FCT lo sọ eyi ninu atẹajde ti wọn gbe sita.
Gẹgẹ bi wọn ṣe sọ, igbesẹ naa ni wọn lo wa ni ibamu pẹlu ofin to de ọrọ ilẹ, iyẹn Land Use Act ti ọdun 1978, to sọ pe bi eeyan ko ba mu adehun ṣẹ lori ilẹ ti wọn ya sọtọ fun un, ijọba ni agbara lati gba ilẹ naa pada.
Ọpọ awọn orukọ nla-nla ni lorileede Naijiria ni ọrọ naa kan, to fi mọ akọwe agba fun ijọba Naijiria, George Akume ati iyawo rẹ, Regina, ti wọn ni apapọ owo ti wọn jẹ ti to ẹgbẹrun mẹrinlelọgbọn miliọnu naira.
Awọn oloṣelu miran tọrọ naa tun kan ni Sẹnetọ Dino Melaye to du ipo gomina ipinlẹ Kogi nigba kan; Shehu Sani toun naa du ipo gomina ipinlẹ Kaduna; Rochas Okorocha toun ti figba kan ṣe gomina ipinlẹ Imo; Abdul Ningi, sẹnetọ to wa lori ipo; adajọ agba Naijiria tẹlẹri, Walter Onnoghen; ati Enyinnaya Abaribe, gbajumọ sẹnetọ nipinlẹ Abia.
Owo to le ni miliọnu mọkanlelọgọta naira ni wọn jẹ lori awọn owo ilẹ ti wọn ya sọtọ fun wọn lagbegbe Maitama to gbajumọ daadaa niluu Abuja.
Yatọ si awọn wọnyi, awọn ile ijọsin bii Methodist Church of Nigeria ko gbẹyin ninu awọn to jẹ owo yii, miliọnu kan le ni idaji (1.75m) naira ni wọn jẹ.
Awọn ilẹ ati dukia ti apapọ wọn jẹ 762 ni ijọba FCT lawọn ti gba iwe aṣẹ wọn, ati pe awọn wọnyi ko laṣẹ lori awọn ilẹ atiu dukia naa mọ.
Bakan naa ni ijọba FCT tun fi orukọ awọn miran ti wọn ti san lara owo wọn sita, to si n fun wọn ni gbedeke ọsẹ meji pere lati fi san awọn owo yooku.
Bo tilẹ jẹ pe a ko le sọ pato iye ọdun ti awọn eeyan yii ti jẹ gbese naa, bẹẹ si ni a ko le fidi iye to yẹ ki wọn maa san lọdọọdun lelẹ.
Ohun kan ti ko tun foju han ni pe boya awọn dukia ti ijọba FCT gbẹsẹ le yii ti lọ patapata niyẹn, tabi pe o ṣee ṣe ki awọn ti ọrọ naa kan pe ẹjọ kotẹmilọrun.
BBC ti kan si ẹka ileeṣẹ iroyin FCTA fun alaye lẹkunrẹrẹ, ṣugbọn ti a ṣi n duro de esi wọn.
Kii ṣe igba akọkọ ree ti Nyesom Wike yoo maa gbẹsẹ le ilẹ ati dukia awọn eeyan nla-nla niluu Abuja, latigba to ti di minisita fun FCT.
Ninu oṣu Kẹsan, ọdun to kọja, Wike gbẹsẹ dukia awọn oloṣelu, adajọ, ileeṣẹ ati awọn eeyan, to fi mọ ti oludije sipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu Labour, Peter Obi.
Emi kọ ni mo ni ilẹ ti wọn n sọ - Aarẹ Buhari ti sọrọ
Aarẹ Muhammadu Buhari funra rẹ ti sọrọ, to si ni ọrọ ko ri bi awọn kan ṣe n gbe e kaakiri wi pe oun jẹ owo iwe ẹri emi ni mo ni ilẹ, iyẹn CofO ti ijọba ilu FCT gbẹsẹ lẹ.
Ninu atẹjade ti Garba Shehu to jẹ agbẹnusọ Buhari gbe jade soju opo 'X', o ṣalaye pe awọn kan lo n lo orukọ oun lati fi da ajọ naa silẹ.
Buhari sọ pe wọn fi orukọ naa ṣagbatẹru oun fun ipo oṣelu ni.
"Aarẹ ana kii ṣe ojulowo ẹni to ni ilẹ ti wọn ya sọtọ lorukọ ajọ "Muhammadu Buhari Foundation."
"Awọn kan to sunmọ aarẹ ni wọn da ajọ ọhun silẹ, ati pe ọna to ba ilana ofin mu ni wọn fi da ọhun silẹ, to si jẹ pe ọpọ awọn alẹnulọrọ lo wa ninu ẹ.
"Ṣugbọn niṣe ni wọn ba ijakulẹ pade nigba ti ẹka to n mojuto ọrọ ilẹ, FCDA gbe iwe owo gọbọi wa fun wọn labẹ eto ti wọn pe ni CofO, ti owo naa si pọ gidi, eyi to kọja owo ti wọn le fun ajọ kan lati san," Shehu sọ bẹẹ.
Bakan naa lo tun sọ pe bi wọn ṣe gbẹsẹ le ilẹ ọhun ko jẹ tuntun rara fẹnikẹni nitori pe owo ti wọn n beere fun ti pọ ju ohun ti ajọ naa le san lọ.
"Gẹgẹ bi eniyan, Aarẹ ana ni ọpọlọpọ ilẹ lorukọ rẹ niluu Abuja. Nigba ti wọn pe oun pẹlu awọn igbimọ iṣakoso rẹ lati wa tọwọ bọwe lasiko ijọba rẹ, aarẹ da iwe naa pada lai tọwọ bọ ọ, nitori to sọ pe oun ti ni ilẹ kan niluu FCT tẹlẹ, ati pe ki wọn fun awọn ti ko ni ilẹ tẹlẹ. Ko si gba ilẹ ọhun."
O wa fi kun ọrọ rẹ pe ki awọn eeyan yee sọ ohun ti wọn ko ba mọ lori ọrọ to ba nii ṣe pẹlu Aarẹ Buhari wi pe wọn ti gbẹsẹ le ilẹ rẹ niluu Abuja, nitori pe bẹẹ kọ ni ọrọ ri.


























