'N5,000 tí wọ́n ṣèlérí ni mo fẹ́ lọ gbà níbi àpèjẹ tí wọ́n ti tẹ ọmọ mi mọ́lẹ̀'

Oríṣun àwòrán, Oyo State Government
Ọkan lara obi awọn ọmọ ti ori ko yọ lọwọ iku ojiji nibi apejẹ ti Olori Ooni Ile-Ife tẹlẹ, Naomi Ogunwusi ṣe niluu Ibadan, ti ṣe alaye bi ọgọọrọ ero ṣe tẹ awọn ọmọ rẹ meji mọlẹ lasiko ijijadu fun ẹbun ọdun.
Ninu ọrọ ti o ba awọn oniroyin sọ, Arabinrin naa ṣe alaye wi pe ori redio ni awọn ti gbọ ikede wi pe Olori Ooni Ile-Ife tẹlẹri, Naomi fẹ pin ẹgbẹrun Naira fun awọn eeyan lati ṣe ami ayẹyẹ opin ọdun.
Ilepa ati gba ẹbun ọdun lo si mu ki o ko awọn ọmọ tiẹ naa lọ si ibi eto naa.
Ọkan ninu awọn ọmọ mejeeji naa ti pada sile lẹyin ti o gba itọju nile iwosan, ṣugbọn ikeji ṣi wa ni ibi ti wọn ti n tọju rẹ ni ọkan lara awọn ile iwosan ijọba ipinlẹ Ọyọ.
Ẹlomii ti o ko awọn ọmọ rẹ mẹtẹẹta lọ si ibi eto naa ni lati Olodo lẹ Baṣọrun sọ ohun ti oju rẹ ri lasiko ti igbakeji Gomina ipinlẹ Ọyọ, Adebayo Lawal ṣe abẹwo si ọkan lara awọn ile iwosan ti wọn ko awọn eeyan to fi ara pa nibi iṣẹlẹ naa lọ.
O ni ori redio naa ni ohun ti gbọ wi pe ounjẹ ọfẹ ati ẹbun ọdun wa fun awọn ọmọ kekeeke, eyii lo mu ki oun naa tara ṣaṣa lọ si ibi eto naa.
Awọn ọmọ mẹtẹẹta ti o ko lọ naa ni wọn tẹ mọlẹ lasiko ti awọn eeyan n kọlu ara wọn ni ibi ti wọn ti fẹ gba ẹbun ọdun, ṣugbọn a ko le sọ boya awọn mẹtẹẹta naa ni o ṣi wa laye, nitori pe ọmọ kan ṣoṣo ni a ri pẹlu Arabinrin naa lasiko ti o ba igbakeji Gomina ipinlẹ Ọyọ sọrọ.
Alaye ti iya awọn ọmọ naa ṣe ni pe "wọn ni ẹni kan ti san ẹgbẹrun marun marun Naira fun awọn ọmọ pe ki wọn fi ṣe owo ọdun ni a ṣe lọ".
Ọrọ ti igbakeji Gomina ipinlẹ Ọyọ sọ lasiko to ṣe abẹwo si awọn ile iwosan naa ni pe, lati igba ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹ ni ijọba ti n ṣe awọn iwadii kan, lori ohun ti o ṣokunfa iṣẹlẹ naa ati awọn to ṣe agbatẹru ẹ.
Lawal ni awọn to ṣe agbatẹru eto naa ko sọ nnkan kan fun Ọlọpaa, ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ, Amọtẹkun, ajọ to n ṣe akoso igbokegbodo ọkọ n'ipinlẹ Ọyọ ati awọn ẹṣọ aabo to ku, ki wọn to gbe igbesẹ lati ko awọn eeyan jọ.
O ni awọn to ṣe eto naa n reti ẹgbẹrun mẹwaa ọmọ kekeeke nibi eto wọn, ṣugbọn wọn ko pese aabo, wọn ko si ba ijọba sọ ọ.
''Iwadii n lọ lọwọ lori ohun to ṣokunfa iku awọn ọmọ nibi apejẹ to waye n'Ibadan''

Oríṣun àwòrán, Oyo State Government
Igbakeji Gomina ipinlẹ Ọyọ ni awọn to ṣe eto naa gbudọ lọ jọwọ ara wọn fun awọn Ọlọpaa tabi ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ, ki wọn si lọ wi tẹnu wọn pẹlu akọsilẹ ọrọ.
O ni ijọba ipinlẹ Ọyọ ti n gbe igbesẹ lati rii pe ohun ogbo pada bọ sipo.
Lawal parọwa si awọn obi lati ṣọra fun awọn eto ti wọn n pe awọn ọmọde si lati wa gba nnkan ọdun, paapaa julọ awọn eleyii ti ijọba ko ba fi ọwọ si.
O fi kun ọrọ rẹ wi pe ti ijọba ba fẹ ṣe iru eto bẹẹ lati pin nnkan ọdun, eto aabo a wa, ọkọ to n ṣe amojuto iṣẹlẹ pajawiri yoo wa. Kii ṣe pe ki a kan ko awọn ọmọde jọ lai ṣe awọn eto ti o tọ.
Inu ọgba ile-ẹkọ Islamic High School, to wa ni agbegbe Bashorun, ni iṣẹlẹ laabi naa ti ṣẹ ki akoko ti wọn da fun eto naa lati bẹrẹ to pe l'Ọjọru.
Ọpọlọpọ ero to yabo oriko eto naa lo pọ ju nnkan ti ẹni to fẹ fun awọn eeyan ni ẹbun gba lero, eyii lo si ṣe okunfa wọlukọlu to da ẹmi awọn ọmọde kan legbodo.
A kan si mẹta ọtọọtọ lara awọn ile iwosan ti wọn ko awọn to fi ara pa nibi iṣẹlẹ naa lọ.
Awọn ile iwọsan naa ni 'Patnas Hospital', 'Best Western Hospital' ati 'Molly Hospital' to n bẹ ni opopona Idi-Apẹ di Baṣọrun.
Awọn aṣoju ọkan ninu awọn ile iwosan naa ṣe alaye fun akọroyin wa wi pe ọmọ mẹfa ni wọn gbe digbadigba wa si ọdọ awọn lati ibi iṣẹlẹ naa, ṣugbọn mẹrin jẹ ipe Ọlọrun ninu wọn. Awọn meji ti o ku ti gba itọju, wọn si ti pada si ile wọn.
Alaye ti a tun gbọ lati ẹnu awọn aṣoju ile iwosan mii ni pe o kere tan, ọmọ mẹta ọtọọtọ ni ẹmi ti bọ lọrun wọn ki wọn to ri wọn gbe de ile iwosan naa.
A kan si ileeṣẹ Ọlọpa ipinlẹ Ọyọ fun ariwisi lori iṣẹlẹ naa, alaye ti alukoro ileeṣẹ Ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, Adewale Osifeso ṣe fun akọroyin wa ni pe iṣẹ iwadii ṣi n tẹsiwaju lori iṣẹlẹ naa.















