Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́
Ẹgbẹrun marun-un owo ọdun ti Olori Naomi fẹẹ pin lawọn ọmọ mi lọ gba ti wọn fi tẹ wọn mọlẹ
Ọkan lara awọn iyalọmọ ti ọmọ wọn fara kaasa nibi apejẹ to mu ẹmi lọ niluu Ibadan lo sọ bẹẹ fun BBC
Meji lara awọn ileewosan ti BBC de sọ pe apapọ ọmọ meje lo ku lọdọ wọn
Lori iroyin yii bakan naa,
Awọn to ṣeto ayẹyẹ apejẹ ọdun tawọn ọmọde ti ku n'Ibadan ti wa lahamọ
Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde lo kede bẹẹ ninu ọrọ ibanikẹdun rẹ
Ṣugbọn ṣe lootọ ni pe Oriyomi Hamzat, alaṣẹ ileeṣẹ redio kan nibadan naa mọ nipa ajalu yii.
Hmmm, iroyin Lọ wo bi gbogbo ẹ ṣe jẹ loju opo BBC Yoruba
Ireti pọ ninu aba iṣuna 2025 yii
Ewo lẹ ri o
Aarẹ Tinubu ṣalaye fawọn aṣofin l'Ọjọru to gbe e lọ sile igbimọ
Pe dọla yoo walẹ, koda,ounjẹ yoo pọ yanturu ni 2025
Hmmm,iyẹn naa daa.
Bọjẹẹti ipadabọsipo ni wọn pe e
Ko buru, bawo ni ti ọrọ aje, ilera atawọn yooku, ṣe wọn ko si nibẹ ni?


