Àwọn tó ṣètò àpèjẹ ọdún tí àwọn ọmọde ti kú n'Ibadan ti wà ní àhámọ́ - Makinde

Seyi Makinde ati Naomi Ogunwusi

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Gomina Seyi Makinde tipinlẹ Oyo ti ba mọlẹbi awọn to fara kaaṣa nibi ijamba to waye lasiko apejẹ ọdun fawọn ọmọde niluu Ibadan, eyi ti Olori Ọọni tẹlẹ, Olori Silekunola Naomi Ogunwusi gbe kalẹ niluu Ibadan.

Ile-ẹkọ Islamic High School to wa ni agbegbe Bashorun niluu Ibadan ni apẹje awọn ọmọde naa ti waye.

Ninu atẹjade ti Kọmiṣanna feto iroyin ati ilanilọyẹ nipinlẹ Oyo, Ọmọọba Dotun Oyelade fi sita l'Ọjọru, ọj kejidinlogun, oṣu Kejila, o ni iṣẹlẹ naa kọ wọn lominu pupọ, to si tun ba wọn lọkan jẹ gidi.

Ile-ẹkọ girama ti Basorun Islamic to wa niluu Ibadan ni apẹje awọn ọmọde naa ti waye, to si jẹ ọmọde lo pọ ju ninu awọn to ku, gẹgẹ bi Oyelade ṣe sọ.

Oyelade sọ ninu atẹjade ọhun pe ijọba ran ikọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri, Rapid Response Team dide lati ṣe iranwọ to yẹ nibi ijamba naa.

O tẹsiwaju pe ọpọ awọn to farapa ni wọn ti sare ko lọ sawọn ile iwosan kaakiri niluu Ibadan fun itọju.

Gomina Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde/X

Oyelade jẹ ko di mimọ pe ijọba ipinlẹ Oyo yoo sa gbogbo ipa ati agbara rẹ lati rii pe wọn ṣe iranwọ to yẹ fun gbogbo awọn to farapa.

"Ijọba ko mọ ohunkohun nipa agbekalẹ eto ọhun, bẹẹ si ni wọn ko fi to ileeṣẹ eto ilera leti lati pese iranwọ fawọn ọmọde nibi apejẹ opin ọdun naa.

"O ṣe pataki lati maa ni eto to dara nigba ti a ba n ṣagbekalẹ eto to ba ti nii ṣe pẹlu ero rẹpẹtẹ, paapaa fun awọn ọmọde ati awọn arugbo."

Siwaju sii ni Oyelade sọ pe awọn ṣi n reti esi lati ọdọ ọga ọlọpaa lati fidi iye awọn to fara kaaṣa mulẹ nibi ijamba ọhun.

Bẹẹ lo rọ awọn obi ati alagbatọ ti wọn n kọminu lori ibi ti awọn ọmọ wọn wa lati ṣabẹwo si awọn ileewosan ti wọn ko awọn ọmọ naa lọ - Patnas Hospital, Basorun; Western Hospital, Basorun; Ringroad State Hospital; Molly Specialist Hospital, ati University College Hospital (UCH).

Bakan naa ni Gomina Seyi Makinde sọ loju opo ayelujara ti 'X' rẹ l'Ọjọru, pe iṣẹlẹ ọhun kọ oun lominu pupọ, ti ko si dun mọ oun ninu.

Ọmọde lo pọ ju ninu awọn to kagbako ninu iṣẹlẹ naa
Àkọlé àwòrán, Ọmọde lo pọ ju ninu awọn to kagbako ninu iṣẹlẹ naa

O ni o ṣeni laanu pe ọpọ ẹmi lo sun, ti ọpọ si tun farapa yannayanna.

"Ibanujẹ ni ọjọ yii jẹ fun wa nibi nipinlẹ Oyo. A ba awọn obi ti ayọ wọn deedee yipada si ibanujẹ kẹdun nitori iku to ṣẹlẹ yii."

Siwaju sii ni gomina tun ṣalaye pe bo tilẹ jẹ pe iwadii ṣi n lọ lọwọ, sibẹ awọn to ṣagbekalẹ eto naa ni wọn ti wa lahamọ.

"Mo fẹẹ fọkan awọn eeyan wa balẹ pe ẹnikẹni to ba lọwọ si agbekalẹ eto naa lo maa dahun fun un. Ẹ dakun, ẹ ṣe suuru nitori pe awọn eleto aabo ti bẹrẹ iwadii iṣẹlẹ yii," Makinde ṣalaye.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post