Ilé ìgbìmọ aṣòfin bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ láti f'òfin de ríra ọjà pẹ̀lú owó ilẹ̀ òkèèrè ní Nàíjíríà

Oríṣun àwòrán, Nigerian Senate/Facebook
Lọjọ Iṣẹgun ọsẹ yii ni ile igbimọ aṣofin agba ni Naijiria bẹrẹ igbesẹ lati fofin de rira awọn ọja pẹlu owo ilẹ okeere laarin orileede ọhun.
Igbesẹ naa lo ti kọja kika ni ipele akọkọ.
Wọn ni ko lẹtọọ fawọn ọmọ Naijiria lati maa gba owo oṣu, ra ọja tabi san eyikeyi owo pẹlu owo ilẹ okeere laarin ilu, eyi ti wọn ni ko bojumu.
Nibi ijoko awọn aṣofin ni wọn ti daba naa nigba ti Sẹnetọ Ned Nwoko to jẹ alaga igbimọ to n ri si atunṣe lewaju aba ọhun.
Wọn ni igbesẹ naa yoo tubọ fun owo naira lagbara sii, ti awọn eeyan yoo si tun nigbagbọ ninu rẹ.
Bakan naa ni wọn jẹ ko di mimọ pe, igbesẹ naa yoo jẹ ki awọn to n gbe ọja jade lọ si awọn orileede miran maa gba owo pẹlu naira.
Aba naa ni wọn pe ni "A Bill for an Act to Alter the Central Bank of Nigeria Act, 2007, No. 7, to Prohibit the Use of Foreign Currencies for Remuneration and for Other Related Matters."
Gẹgẹ bi Sẹnetọ Ned Nwoko ṣe ṣalaye, o jẹ ko di mimọ pe agbelarugẹ owo ilẹ okeere n tabuku ba owo naira, to si n bu adojukọ ati iṣoro ba eto ọrọ aje Naijiria.
O tẹsiwaju pe lilo owo dọla, Pọun ati awọn owo ilẹ okeere miran lati maa fi ra ọja tabi san awọn owo kan n ṣe idiwọ fun ominira eto ọrọ aje Naijiria pupọ.
Nwoko ni aba naa yoo dẹkun "sisan owo oṣu, sisan owo ati rira ọja pẹlu owo ilẹ okeere, lati rii daju pe gbogbo oṣiṣẹ, to fi mọ awọn atipo lati maa gba owo oṣu pẹlu naira."
O tun daba pe "owo epo rọbii ati awọn ohun miran ti wọn n gbe jade lo n jẹ owo naira, lati le jẹ ki awọn onibara agbaye lẹ maa lo owo naira daadaa."















