Nǹkan mẹ́wàá tí o kò mọ̀ nípa Ademola Lookman tó gba àmì ẹ̀yẹ agbábọ́ọ̀lù tó dára jù lọ ní Africa

Ademola Lookman

Oríṣun àwòrán, Caf/X

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Titi di akoko yii, ni awọn ololufẹ gbajugbaja agbabọọlu ọmọ orileede Naijiria, Ademola Lookman ṣi n kii, lori bo ṣe gba ife ẹyẹ agbabọọlu to dara julọ nilẹ Afrika. Yatọ si pe Ademola Lookman n gba bọọlu fun ikọ Super Eagles, o tun n gba bọọlu ọwọ iwaju fun ẹgbẹ agbabọọlu Atalanta. Ilu Marrakech to wa lorileede Morocco ni wọn ti gbe ife ẹyẹ ọhun fun un niwaju gbogbo awọn akẹgbẹ rẹ, to fi mọ iya ati baba rẹ. Lara awọn nnkan manigbagbe nipa Lookman, eyi to jẹ ki gbogbo agbaye rii daadaa ni bo ṣe gba goolu mẹta sinu àwọ̀n nibi ifẹsẹwọnsẹ aṣekagba ti idije UEFA Europa League, ati ipa to jọju to ko fun Naijiria ninu idije AFCON tọdun 2023. Diẹ ree lara awọn ohun iwuri nipa bi Ademola Lookman ṣe gun oke debi to fi n gba ife ẹyẹ agbabọọlu ọkunrin to peregede julọ nilẹ Afrika lọdun 2024. Ilu London ni wọn bi ọmọ Naijiria ọhun si, ni ogunjọ, oṣu Kẹwaa, ọdun 1997. Baba rẹ fi iwa ọmọluabi ati aṣa ati iṣe ilẹ Yoruba tọ ọ lati kekere titi to fi dagba, eyii lo si n lo ninu irinajo rẹ nile ẹkọ ati nidi ere bọọlu.

Ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn ọhun fi ẹyin awọn alatako rẹ lati Cote d'Ivoire ati Brighton & Hove Albion, Simon Adingra, Serhou Guirassy lati Guinea ati Borussia Dortmund, janlẹ̀. Awọn mii tun ni ọmọ orile-ede Morocco to tun n gba bọọlu fun Paris Saint-German, Achraf Hakimi, to fi mọ goli fun Mamelodi Sundowns, Ronwen Williams lati South Africa.

Gbigba ti Lookman gba ami ẹyẹ naa mu ko di igba keji ti agbabọọlu Naijiria gba a laarin ọdún meji. Victor Osimhen lo gba a lọdun to kọja

Taa ni Ademola Lookman?

Ademola Lookman

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ijafafa rẹ ninu eto ẹkọ ni Peckham

Ko to di pe o di ilu mọ-ọn-ka nidi ere bọọlu, Lookman jafafa nile-ẹkọ, to si tayọ kọja sisọ ni St. Thomas the Apostle College to wa ni Peckham.

Titayọ rẹ kọja afẹnuroyin pẹlu bo ṣe gbegba oroke ninu idanwo aṣekagba ti GCSE to ṣe nile ẹkọ, to si tun gbiyanju lati ma ṣe jẹ ki eto ẹkọ di ere bọọlu lọwọ, ti ere bọọlu naa ko si di eto ẹkọ rẹ lọwọ.

Lati ori papa adugbo titi to fi de Waterloo FC

Kekere ni Lookman wa nigba to bẹrẹ sii gba bọọlu lori papa iṣere ladugbo kan ni Peckham. Nigba ti yoo fi pe ọmọ ọdun mọkanla, Lookman ti wọ ikọ ẹgbẹ agbabọọlu Waterloo FC ni ti awọn ọdọ, nibi to ti gba ẹkọ gidi fun ọdun marun.

Ifarajin ati oniruuru akitiyan rẹ lo fun un ni anfaani lati wọ ile-ẹkọ Charlton Athletic Academy lọdun 2013.

Bi ogo rẹ ṣe buyọ ni Charlton Athletic

Ninu oṣu Kọkanla, ọdun 2015, Lookman peregede si ipo agba ninu ẹgbẹ agbabọọlu ti Charlton Athletic. Oṣu kan gbako lẹyin naa lo gba bọọlu akọkọ sinu awọn nibi ifẹsẹwọnsẹ pẹlu ẹgbẹ agbọọlu Brighton & Hove Albion.

Akitiyan ati ifarajin rẹ lo jẹ ko tete di apewaawo, to si fẹsẹ rẹ mulẹ daadaa gẹgẹ bi irawọ ninu ere bọọlu ilẹ Gẹẹsi.

Irinajo Premier League pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu Everton

Ẹbun Lookman lo pe ọkan awọn eeyan si ẹgbẹ agbabọọlu Everton, ti wọn ra a ni miliọnu mọkanla Pọun (£11m) ninu oṣu kinni, ọdun 2017.

O tun fi itan manigbagbe balẹ nigba to gba goolu sinu awọn ẹgbẹ agbabọọlu Manchester City, eyi ti wọn fi bori lọdun naa. Sibẹsibẹ, awọn anfaani atigbadegba to n ri lati bẹrẹ ifẹsẹwọnsẹ lasiko to fi wa ni Goodison Park tun jẹ ko maa ṣe daadaa.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Igba ọtun pẹlu RB Leipzig

Lẹyin ti eto ifiranṣẹ pari lakọtun, Lookman darapọ mọ ẹgbẹ agbọọlu RB Leipzig patapata lọdun 2019. Bo tilẹ jẹ awọn asiko rẹ nilẹ Germany fẹẹ ṣe segesege, sibẹ, o tun ṣi fi awọn itan manigbagbe balẹ pẹlu goolu rẹ to gba sawọn lasiko ifẹsẹwọnsẹ pẹlu Borussia Mönchengladbach. Lẹyin naa ni wọn tun fi ranṣẹ si Fulham ati Leicester City, nibi to ti kopa to jọju.

Aṣeyọri pẹlu Atalanta ati irawọ nla ni Serie A

Iṣẹ ori ran Lookman gbọna ara yọ lọdun 2022 nigba to darapọ mọ ẹgbẹ agbabọọlu Atalanta ninu adehun ọlọdun mẹrin to tọwọ bọ. Ifarahan akọkọ rẹ tayọ gidi, to fi mọ awọn ifẹsẹwọnsẹ pẹlu Salernitana, Spezia, ati Juventus. Lookman pari saa ọdun 2022/23 pẹlu goolu mẹẹdogun, eyi to jẹ ko gba ami ẹyẹ agbabọọlu to dara julọ fun Atalanta.

Goolu mẹta lẹẹkan ṣoṣo ni aṣekagba Europa League

Lọjọ kejilelogun, oṣu Karun-un, ọdun 2024, Lookman tun tayọ yatọ ninu ifẹsẹwọnsẹ pẹlu ikọ ẹgbẹ agbabọọlu Bayer Leverkusen, nibi ti wọn ti bori pẹlu ami ayo mẹta si odo.

Ifẹsẹwọnsẹ aṣekagba ni eyi jẹ ninu idije UEFA Europa League, to si jẹ eyi to fi itan ẹgbẹ agbabọọlu balẹ fun igba akọkọ lati gbe ife ẹyẹ idije naa, ati ife ẹyẹ kẹji lati ọdun mọkanlelọgọta sẹyin.

Aṣeyọri agbaye: Lati England si Naijiria

Lookman bẹrẹ aṣeyọri agbaye rẹ pẹlu ẹgbẹ ọdọ England, to fi mọ idije ife ẹyẹ agbaye ti FIFA U-20 ti wọn fi gbegba oroke lọdun 2017. Lọdun 2020, o lọ si Naijiria lati sọ asọyepọ, to si ṣe ifarahan akọkọ lọdun 2022 fun Super Eagles. Ipa to jọju lo ko ninu idije ife ẹyẹ ilẹ adulawọ, iyẹn Africa Cup of Nations tọdun 2023.

Aṣeyọri to tayọ ni L'Équipe

Maaki mẹwaa/mẹwaa ni Lookman gba nibi aṣekagba idije Europa League. Aṣeyọri ati ipa to ko, lo jẹ ko wa ni ifẹgbẹkẹgbẹ pẹlu awọn agba agbabọọlu bii Lionel Messi, Neymar, ati Erling Haaland, bi wọn ṣe n tọka si awọn ẹbun nla ati ipa rere to ti ko.

Ademola Lookman wa lara ikọ to ṣojú Naijiria ni Africa Cup of Nations lọdun 2023 Africa Cup of Nations, amọ ti Ivory Coast fi ẹyin wọn janlẹ ni ipele aṣekagba.

Igba mẹtadinlọgbọn lo ti ṣojú Naijiria, o si gba bọọlu sinu àwọ̀n ni igba mẹjọ, o si ti gba ami ẹyẹ MON.

Ẹgbẹ agbabọọlu rẹ, Atalanta jawe olubori ni 2023-2024 Europa League, nigba to gba 'hat-trick' wọ inu awọn Bayer Leverkusen ni aṣekagba, eyi to mu wọn bori.

Chiamaka Nnadozie gba ami ẹyẹ Goli obinrin to dara julọ

Goli fun ẹgbẹ agbabọọlu Super Falcons ti Naijiria, Chiamaka Nnadozie naa gba ami ẹyẹ, eyi to tun fi di ipo naa mu gẹgẹ bi goli obinrin to pegede julọ ni Africa.

O gba ami ẹyẹ naa mọ Khadija Er-Rmichi lati Morocco ati AS Far, to fi mọ Andile Dlamini ti South Africa ati Mamelodi Sundowns.

Nnadozie lo gba ami ẹyẹ naa lọdun to kọja.

Super Falcons ti Naijiria lo tun gba ami ẹyẹ fun ẹgbẹ agbabọọlu orile-ede to dara ju.

Awọn agbabọọlu bii Osinachi Ohale, Asisat Oshoala ati Rasheedat Ajibade wa ninu agbabọọlu obinrin mọkanla ti CAF sọ pe o tayọ julọ.