Wo àwọn nǹkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa CAF Awards tí yóò wáyé lónìí

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ní ọjọ́ Ajé, ọjọ́ kẹrìndínlógún, oṣù Kejìlá ni ayẹyẹ fífúnni lámì ẹ̀yẹ àjọ eré bọ́ọ̀lù ilẹ̀ Áfíríkà, Confederation of Africa Football (CAF) yóò wáyé.
Ní ìlú Marrakech, orílẹ̀-èdè Morocco ni wọ́n yóò ti fún àwọn agbábọ́ọ̀lù ilẹ̀ Áfíríkà ní àmì ẹ̀yẹ ní ìpele mẹ́ẹ̀dógún.
Kókó àmì ẹ̀yẹ náà ni láti ṣe àfihàn àti ṣíṣe kóríyá fáwọn agbábọ́ọ̀lù, akọnimọ̀ọ́gbá àtàwọn ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù nílẹ̀ Áfíríkà ní ìpele ọkùnrin àti obìnrin.
Àwọn olólùfẹ́ eré bọ́ọ̀lù káàkiri àgbáyé ló máa ń fojú sọ́nà fún ayẹyẹ yìí láti mọ agbábọ́ọ̀lù tó gba àmì ẹ̀yẹ fún ipò agbábọ́ọ̀lù tó dára jùlọ lọ́dún kan.
Láti ọdún 1992 ni àjọ CAF ti máa ń ṣe ayẹyẹ yìí.
Ìbéèrè tó gbẹnu àwọn èèyàn ni pé agbábọ́ọ̀lù wo ló máa gba ipò agbábọ́ọ̀lù tó dára jùlọ lọ́wọ́ àwọn ọmọ Nàìjíríà - Victor Osimhen àti Asisat Oshoala tí wọ́n gbà á lọ́dún 2023?
Àbí ọwọ́ àwọn ọmọ Nàìjíríà – Ademola Lookman àti Chiamaka Nnadozie ni àmì ẹ̀yẹ náà yóò já mọ́ lọ́wọ́?
Aago mélòó ni àmì ẹ̀yẹ náà yóò wáyé?
Aago méje ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ Ajé, ọjọ́ Kẹrìndínlógún ni ìṣàfihàn àmì ẹ̀yẹ náà yóò wáyé.
Èèyàn le rí bí ayẹyẹ náà ṣe ń lọ ní Marrakech wò lórí ìkànnì àmóhùnmáwòrán tí wọ́n ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú àjọ CAF tàbí lórí ìtàkùn ayélujára àjọ CAF gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe máa ń ṣe ní ọdọọddún.
Àwọn wo ló ń forí gbárí láti gba àmì ẹ̀yẹ agbábọ́ọ̀lù tó dára júlọ̀ nílẹ̀ Áfíríkà lọ́dún yìí?
Àwọn agbábọ́ọ̀lù márùn-ún ni wọ́n ń figagbága lórí ta ni yóò gba àmì ẹ̀yẹ agbábọ́ọ̀lù tó dára jùlọ ní ìpele àwọn ọkùnrin.
Simon Adingra tó jẹ́ agbábọ́ọ̀lù fún orílẹ̀ èdè Cote d'Ivoire àti Brighton, Serhou Guirassy ti orílẹ̀ èdè Guinea àti Achraf Hakimi ti orílẹ̀ èdè Morocco wà lára àwọn tó ń díje fún ipò náà.
Àwọn mìíràn ni ọmọ Nàìjíríà tó tún ń gbà fún Atalanta, Ademola Lookman, tí aṣọlé fún orílẹ̀ èdè South Africa, Ronwen Williams ń wòye pé ipa rẹ̀ ní ìdíje ife ẹ̀yẹ ilẹ̀ Áfíríkà tó kọjá yóò mú òun gba àmì ẹ̀yẹ náà.
Simon Adingra

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Simon Adingra jẹ agbábọ́ọ̀lù tó pàtàkì fún Cote d'Ivoire lásìkò ìdíje ife ẹ̀yẹ ilẹ̀ Áfíríkà ọdún 2023 tó wáyé nínú oṣù Kejì ọdún yìí.
Lásìkò ìdíje náà, ó ṣe àtìlẹyìn fún bí orílẹ̀ èdè rẹ̀ ṣe gbá ife ẹ̀yẹ rẹ̀ mọ́ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà lọ́wọ́.
Bákan náà ló gba àmì ẹ̀yẹ agbábọ́ọ̀lù tó ṣe dada jùlọ lásìkò ìdíje ọ̀hún.
Simon Adingra, ẹni ọdún méjìlélógún wà lára àwọn agbábọ́ọ̀lù tó ṣe kókó fún ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Brighton àti Hove Albion tó gbá fún ní ọdún yìí.
Serhou Guirassy (Guinea)

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Òkíkí Guirassy tàn gidi bó ṣe jẹ góòlù ọgbọ̀n nínú àwọn ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ tó gbá fùn ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Stuttgart ní ìdíje German Bundesliga fún sáà ọdún 2023/2024.
Èyí náà ló sì gbé wọ Borussia Dortmund ní sáà tuntun tí wọ́n wà yìí.
Guirassy, ẹni ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n jẹ góòlù mẹ́tàlélógún fún ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù tó ń gbá fún àti orílẹ̀ èdè rẹ̀ láàárín oṣù Kìíní sí oṣù Kẹwàá ọdún 2024.
Achraf Hakimi (Morocco)

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Agbábọ́ọ̀lù kan gbòógì ni Hakimi jẹ́ fún ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù orílẹ̀ èdè Morocco pàápàá bó ṣe ti kópa nínú ìdíje mẹ́rìnlá káàkiri àgbáyé fún orílẹ̀ èdè náà lọ́dún 2024.
Ó ṣokùnfà ìrànlọ́wọ́ bí Morocco ṣe gba ipò Kẹta níbi ìdíje Paris Olympic Games.
Bákan náà ló ṣe gudugudu méje yàyà mẹ́fà ní ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Saint-Germain bí ó ṣe jẹ́ kí ẹgbẹ́ náà máa jáwé olúborí níbi àwọn ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ tí wọ́n gba láti fi gba ife ẹ̀yẹ Ligue 1.
Ademola Lookman (Nigeria)

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lookman ni ìràwọ̀ rẹ̀ ń búyọ gidi lásìkò yìí pàápàá lọ́dún 2024 yìí.
Ó ṣe ìrànwọ́ bí ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù rẹ̀, Atalanta gbé ife ẹ̀yẹ UEFA Europa League.
Ìdíje náà ni èyí tó jẹ́ àmì ẹ̀yẹ tí orílẹ̀ èdè náà máa gbà láti ọdún mọ́kànlélọ́gọ́ta sẹ́yìn.
Bákan náà ló ṣe ìrànwọ́ fún bí Nàìjíríà ṣe de ìpele àṣekágbá ní ìdíje ife ẹ̀yẹ ilẹ̀ Áfíríkà.
Wọ́n fui orúkọ Lookman sílẹ̀ fún àmì ẹ̀yẹ Ballon d'Or ọdún 2024.
Ronwen Williams (South Africa)

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Aṣọle fún orílẹ̀ èdè South Africa, Williams di gbajúmọ̀ fún ipa rẹ̀ níbi ìdíje ife ẹ̀yẹ ilẹ̀ Áfíríkà tó kọjá.
Ọ̀pọ̀ góòlù ni Williams ṣe ìrànwọ́ fún orílẹ̀ èdè rẹ̀ láti tì síta pàápàá lásìkò tí wọ́n gbá pẹnáritì.
Bákan náà ni àwọn ìrànwọ́ rẹ̀ yìí mu kí South Africa gba ipò kẹta ní ìdíje náà.
Àwọn ipa rẹ̀ yìí mú kí wọ́n fi orúkọ rẹ̀ sílẹ̀ láti díje fún ọ̀kan lára àwọn aṣọ́lé tó dára jùlọ ní àjọ FIFA.
Àwọn agbábọ́ọ̀lù tó ti gba àmì ẹ̀yẹ agbábọ́ọ̀lù tó dára jùlọ ní ìpele ọkùnrin láti ọdún márùn-ún sẹ́yìn ni:
2023: Victor Osimhen, Nigeria - Napoli (ITA)
2022: Sadio Mané, Senegal - Liverpool (ENG)
2021: Kò sí àmì ẹ̀yẹ
2020: Kò sí àmì ẹ̀yẹ
2019: Sadio Mané, Senegal - Liverpool (ENG)
2018: Mohamed Salah, Egypt - Liverpool (ENG)
2017: Mohamed Salah, Egypt - Liverpool (ENG)











