Àwọn agbéṣùmọ̀mí tó lé ní igba rí ìdájọ́ ikú, ẹ̀wọ̀n gbére he

Oríṣun àwòrán, TheCable
Ilé ẹjọ́ gíga ìjọba àpapọ̀ ti ṣèdájọ́ àwọn afurasí agbéṣùmọ̀mí tí iye wọn lé ní igba lórí ẹ̀sùn ìgbéṣùmọ̀mí ní Nàìjíríà.
Ilé ẹjọ́ gíga ní àwọn afurasí náà jẹ̀bi àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wọ́n, tí wọ́n sì fún èèyàn kọ̀ọ̀kan ní ìdájọ́ tó tọ́ sí wọn.
Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ka tó ń gbógunti ìwà ìgbéṣùmọ̀mí ìyẹn National Counter-Terrorism Centre ní ọ́fíìsì olùbádámọ̀ràn ààrẹ lórí ètò ààbò, National Security Adviser (NSA) ṣe sọ, àwọn kan gba ìdájọ́ ikú, àwọn mìíràn gba ẹ̀wọ̀n gbére, tí wọ́n sì ju àwọn mìíràn sí ẹ̀wọ̀n ogún ọdún sí àádọ́rin ọdún.
Àtẹ̀jáde náà ní ìdájọ́ tí ẹni kọ̀ọ̀kan gbà dá lórí bí ẹ̀ṣẹ̀ wọn ṣe le tó.
Ìròyìn ní ẹ̀ka olùpejọ́ ní ọ́fíìsì agbẹjọ́rò àgbà ní Nàìjíríà ló rí sí bí ètò ìgbẹ́jọ́ náà ṣe lọ.
Ọ̀pọ̀ àwọn afurasí náà ni wọ́n ń jẹ́jọ́ lábẹ́ àwọn adájọ́ ilé ẹjọ́ gíga márùn-ún ní àhámọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n Kainji tí wọ́n wà lórí àwọn ẹ̀sùn tó lágbára.
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ibi tí ìgbẹ́jọ́ dé dúró, adarí ẹ̀ka ìbáraẹnisọ̀rọ̀ ṣàlàyé pé ìgbẹ́jọ́ àwọn afurasí 237 ni wọ́n gbọ́ lásìkò ìgbẹ́jọ́ náà.
Wọ́n ní lára àwọn tí wọ́n dájọ́ ikú fún jẹ́ àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ tó lágbára tó fi mọ́ ṣíṣe ìkọlù sáwọn obìnrin àtàwọn ọmọdé àti bíba àwọn ilé ìjọsìn jẹ́.
Bákan náà ni àwọn afurasí tí wọ́n dú àwọn èèyà lọ́rùn, àwọn tó jí àwọn obìnrin àti ọmọdé gbé níbi ìkọlù tí wọ́n ṣe sí ìlú Gina Kara Kai ní ìpínlẹ̀ Borno ni wọ́n gba ìdájọ́ ikú.
Iléeṣẹ́ olùbádámọ̀ràn ààrẹ ní ìgbésẹ̀ ńlá ni ìdájọ́ náà jẹ́ nídìí gbígbógunti ìwà ìgbéṣùmọ̀mí tó fi mọ́ ikọ̀ Boko Haram, IPOB àti àwọn agbébọn.
Wọ́n ní gbogbo ìlànà ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà àgbáyé ni wọ́n tẹ̀lé nídìí ìgbẹ́jọ́ náà láti ri dájú pé ìdájọ́ òdodo wáyé àti láti ri àláfíà jọba láwọn ẹkùn tí wàhálà ti ń ṣẹlẹ̀ káàkiri orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.
Àtẹ̀jáde náà tún ṣàlàyé pé àwọn tí wọ́n ń ṣe agbátẹrù fún àwọn agbéṣùmọ̀mí ni wọ́n rí ẹ̀wọ̀n gbére he.
Ó rọ àwọn ọmọ Nàìjíríà láti wá ní ìṣọ̀kan, wà ní ojú lalákàn fi ń ṣọ́rí ní gbogbo ìgbà, kí wọ́n sì máa fi àwọn ìwà tó bá mú ìfura lọ́wọ́ ní agbègbè wọn tó àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò létí.















