Wo ìgbésẹ̀ tuntun tí Finland gbé lórí Simon Ekpa olórí ẹgbẹ́ IPOB tí wọ́n jù sẹ́wọ̀n

Aworan Simon Ekpa

Oríṣun àwòrán, Simon Ekpa/Facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Awọn alaṣẹ ijọba orilẹede Finland tun ti gbe igbesẹ tuntun lori ọrọ Simon Ekpa to jẹ olori ẹgbẹ ajijagbara fun idasilẹ orilẹede Biafra, IPOB, eyi to wa lẹwọn lorilẹede naa lori ẹsun igbesunmọmi atawọn ẹsun mii.

Gẹgẹ bi iroyin ti a gbọ lati Finland, ijọba orilẹede naa ti gbẹsẹ le dukia Ekpa atawọn eeyan kan to n ṣiṣẹ pọ pẹlu rẹ.

Ti ẹ o ba gbegbe, ijọba Finland kede pe awọn ti fọwọ ofin mu Ekpa ati eeyan mẹrin mii lori ẹsun igbesunmọmi ati riru awọn eeyan soke lati wu iwa ipa.

Oloṣelu ẹsẹ kuuku ni wọn mọ Ekpa si ni Finland ti o si jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu NCP nibẹ.

Koda iroyin tun fidi rẹ mulẹ pe Ekpa ti jẹ igbakeji kansilọ ri labẹ asia ẹgbẹ oṣelu NCP ti o si ṣoju ẹgbẹ oṣelu naa lẹkun Lahti lorilẹede Finland.

Ọjọ kọkanlelogun oṣu Kẹta ọdun 1985 ni wọn bi Ekpa, ẹni to jẹ ọmọbibi ilu kekere kan ti orukọ rẹ n jẹ Ohaukwu nipinlẹ Ebonyi.

Ohun ti ile ẹjọ ni Finland sọ ni pe Ekpa n sọ nipa iyapa lọna aitọ lori ayelujara.

Gẹgẹ bii ohun ti ile ẹjọ sọ, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹjọ, ọdun 2021 ni ọkunrin naa hu iwa ọdaran ọhun ni Lahti.

Ọgba ẹwọn Kylmäkoski ni Ekpa wa ni Finland pẹlu awọn mẹrin mii ti wọn mu wọn papọ.

Kinni tuntun lori ọrọ Simon?

Titi di asiko ti a kọ iroyin yii, Ekpa si wa lọgba ẹwọn lorilẹede Finland, koda, awọn alaṣẹ orilẹede naa tun ti fikun iye ọjọ to yẹ ki o lo lọgba ẹwọn.

Ileeṣẹ iroyin kan ni Finland, yle sọ pe Ekpa si wa lori ẹsẹ rẹ pe oun ko jẹbi ọkankan ninu awọn ẹsun ti wọn kan oun.

Ọgbẹni IIkka Kopra to jẹ agbẹjọro Ekpa ṣalaye pe ileeṣẹ ọlọpaa fi Ekpa silẹ lẹwọn tori wọn mọ pe ti o ba jade, o le ṣe idena fun iṣẹ iwadii ti wọn n ṣe.

Agbẹjọro Ekpa ni awọn ọlọpaa sọ foun pe tawọn fi Ekpa silẹ lọgba ẹwọn, o le lẹdi apo pọ pẹlu awọn olujẹri.

Igba akọkọ ree ti Ekpa yoo ko sọwọ ijọba orilẹede Finland.

Wọn fọwọ ofin mu Ekpa loṣu Keji, anọ, wọn pada fi i silẹ lẹyin ti akọroyin kan sọ fun BBC pe awọn ọlọpaa ṣe ifọrọwanilẹnuwo pẹlu rẹ tan.

Ṣaaju eto idibo gbogbogbo to waye ni Naijiria lọdun 2023 ni ijọba apapọ sọ fun orilẹede Finland lati ṣe iwadii awọn nnkan ti Ekpa n ṣe lẹyin to kawọn eeyan maa kopa ninu eto idibo naa.

Kinni yoo ṣẹlẹ si dukia Simon Ekpa?

Ni ọdun 2007 ni Simon Ekpa lọ si orilẹede Finland lati maa gbe ibẹ.

O si kopa ninu era idaraya to waye ni Finland lọdun 2009, bakan naa lo tun kopa ninu idije ere ọdan ti wọn pe ni Helsinki 4 Athletics GP loṣu Kẹjọ ọdun 2009 kan naa gẹgẹ bi ọmọ orilẹede Finland.

Amọ, Ekpa ti di ilumọọka lori ayelujara lati igba naa.

Ọmọbinrin orilẹede Finland ni Ekpa ṣe igbeyawo pẹlu rẹ, Eledua si fi ọmọ kan tawọn lọrẹ.

Ni gbogbo igba lo maa n fi ọmọ naa yangan lori ayelujara, o tun maa n sọ pe oun le sọ ede Finland daadaa.

Gẹgẹ bi iroyin ṣe fidi rẹ mulẹ, dukia Ekpa wa lara awọn dukia ti ijọba gbẹsẹ le lori ẹsun pe o n ṣagbatẹru igbesunmọmi.

Eyi yoo ṣakoba nla fun Ekpa ati gbogbo ileeṣẹ to ba ni ṣe rẹ to fi mọ gbogbo awọn alabaṣiṣẹpọ rẹ.

Ibẹrẹ Simon Ekpa

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Lẹyin to pari ile girama, o gbera lọ fasiti Aberystwyth nibi to ti kẹkọọ gboye keji ni fasiti ninu ofin.

O tẹsiwaju lọ ABMS Education ni Switzerland nibi to gba oye PhD ofin okowo.

Nigba to wa ni ewe, Simon Ekpa jẹ elere idaraya fifo, to si ni okiki laarin awọn akẹgbẹ rẹ.

O figba kan soju orilẹede Naijiria nibi idije ilẹ Africa. Lọdun 2003 ni idije awọn ọjọwẹwẹ elere idaraya ni ilẹ Afrika, Simon gba ami ẹyẹ fadaka ni ere fifo.

Gbogbo nnkan lọ daada fun Simon, sugbọn o farapa, to si fi orukun ṣeṣe, eyi ti ko gba laaye layi tẹsiwaju ninu ere idaraya.

O gbera lọ si orilẹede Finland ni ọdun 2007 fun itọju ati iṣẹ abẹ fun orunkun rẹ.

Nibẹ ni Simon ni ri igbesi ayeye tuntun, bẹrẹ iṣẹ agbẹjọro, to si bẹrẹ mọlẹbi.

Lẹyin to pinnu to duro si ilu Lahti, Simon kọ ede Finland, ti wọn si tun fun ni iwe igbelyu, to si tun kopa ninu iṣẹ ologun.

O darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu NCP ni orilẹede Finland, to si kopa ninu eto iidbo lọdun 2022.

Lati ọdun 2012 ni Simon Ekpa ti n se oṣelu loorekore.

O da ileeṣẹ Ekpa & Co to n ri si ileeṣẹ to n risi ofin irinajo silẹ.