Mi ò kú o, irọ́ ńlá ni! Alága INEC Yakubu sọ̀rọ̀ lórí ìròyìn tó ní ó jáde láyé

Oríṣun àwòrán, INEC/X
Alaga ajọ eleto idibo INEC, Ọjọgbọn Mahmoud Yakubu, ti sọrọ lori iroyin kan to lu ori ayelujara pa lana ọjọ Abamẹta pe o jade laye.
Ọjọgbọn Yakubu ti sọ pe irọ to jina si ootọ ni iroyin naa nitori koko lara oun le.
Alága INEC fidi ọrọ yii múlẹ ninu atẹjade kan to fi sita lati ọwọ akọwe iroyin rẹ, Rotimi Oyekanmi.
Ileesẹ iroyin ori ayelujara kan lo gbe iroyin naa jade lọjọ Abamẹta wi pe Ọjọgbọn Yakubu ti jade laye lẹyin to ṣàisan nile iwosan kan niluu London.
Amọ, alaga INEC sọ ninu atẹjade to fi sita pe "wọn ti pe akiyesi mi si iroyin ofege kan to ni mo ti ku.
Mi o n fi asiko ri rọ gbogbo eeyan lati kọ eti ikun si iroyin ofege naa."
Ọjọgbọn Yakubu sọ ninu atẹjade to fi sita pe oun ko ti rinrin ajo lọ si ilu London gan an fun bi ọdun meji bayii nibi ti iroyin naa sọ pe o ku si.
Lọdun 2021 ni iru iroyin yii jade pe Ọjọgbọn Yakubu jade laye
Yakubu sọ pe oun si wa nibi ipade kan pẹlu ile aṣoju-ṣofin l'Abuja lori ọrọ eto idibo lọjọ kọkanla oṣu Kejila yii.
Bakan naa ni Ọjọgbọn Yakubu tun dari ipade pẹlu awọn ọga agba ajọ INEC l'awọn ipinlẹ ni Ọjọbọ ọsẹ to kọja.
Alaga INEC ni ipade mejeeji toun ṣe yii l'awọn ileeṣẹ iroyin tẹlifísàn gbe, koda, awọn oniwe iroyin naa ko gbẹyin.
O ni awọn kan ti gbe iru iroyin yii jade nipa oun ni nnkan bíi ọdun mẹta sẹyìn, ki wọn to wa tun ṣe bẹẹ bayii.
"O yẹ k'awọn to n gbe iru iroyin bayii kiri mọ ipa ti ko dara ti iru iroyin ofege bayii maa n ni lori ẹni ti wọn sọ nípa rẹ ati lori awujọ lapapọ," Ọjọgbọn Yakubu lo sọ bẹẹ.
O ni ajọ INEC yoo tẹsiwaju lati maa ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn akọṣẹ-mọṣẹ akọroyin lati gbogun ti iroyin ofege lawujọ.















