Wọ́n fòfin de ààrẹ South Korea lẹ́yìn tí ilé aṣòfin yọ ọ́ nípò

Yoon Suk-yeol

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin orílẹ̀ èdè South Korea ti dìbò láti yọ ààrẹ orílẹ̀ èdè náà, Yoon Suk-yeol nípò.

Ní báyìí, olóòtú ìjọba ní South Korea, Han Duck-Soo ni yóò máa ṣe àkóso ìjọba gẹ́gẹ́ bí adelé ààrẹ lẹ́yìn tí wọ́n ti fòfin de ààrẹ Yoon lórí ojúṣe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ààrẹ.

Nínú àwọn aṣòfin ọ̀ọ́dúnrún (300) tó wà nílé aṣòfin náà, mẹ́rìnlénígba (204) ló dìbò pé kí wọ́n yọ ààrẹ náà kúrò nípò táwọn márùndínláàádọ́rùn-ún (85) dìbò tako ìgbésẹ̀ náà.

Abẹnugan ilé aṣòfin ọ̀hún, Woo Won-shik ni àwọn ti fẹnukò lórí ìyọnípò náà, tí gbogbo ètò sì ti parí láti yọ ààrẹ náà.

Woo ní òun lérò pé ìgbésẹ̀ náà yóò mú inú àwọn èèyàn orílẹ̀ èdè náà dùn àti pé gbogbo àwọn tí wọ́n ti gbégi dínà aríyá ọdún tí wọ́n fẹ́ ṣe yóò yí ọkàn wọn padà báyìí.

Bí wọ́n ṣe kéde èsì ìbò àwọn aṣòfin tó dìbò láti yọ ààrẹ náà nípò ni àwọn èèyàn tí wọ́n ti ń ṣe ìfẹ̀hónúhàn níwájú ilé aṣòfin bẹ̀rẹ̀ sí ní dáwọ́ ìdùnnú.

Àwọn ará ìlú tó ń dunnú lẹ́yìn tí wọ́n kéde ìyọnípò Yoon Suk-yeol

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Àwọn ará ìlú tó ń dunnú lẹ́yìn tí wọ́n kéde ìyọnípò Yoon Suk-yeol

Ní ìlú Seoul, tó jẹ́ olú ìlú orílẹ̀ èdè South Korea, níṣe ni àwọn èèyàn ń fò fáyọ̀ lórí bí wọ́n ṣe yọ ààrẹ náà nípò.

Ẹ̀wẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn aṣòfin ti dìbò láti yọ ààrẹ nípò, ilé ẹjọ́ ni yóò fìdí ìyọnípò náà múlẹ̀.

Mẹ́fà nínú àwọn adájọ́ mẹ́sàn-án ilé ẹjọ́ náà ni òfin ní ó gbọ́dọ̀ fẹnukò pé kí wọ́n yọ ààrẹ náà nípò, kí ìyọnípò ọ̀hún tó lè fẹsẹ̀ múlẹ̀.

Gẹ́gẹ́ bí àwọn iléeṣẹ́ ìròyìn abẹ́lé ṣe sọ, ọjọ́ Ajé ni ilé ẹjọ́ yóò bẹ̀rẹ̀ ìjókòó láti jíròrò lórí ìyọnípò ààrẹ Yoon.

Tí àwọn adájọ́ náà bá fẹnukò lọrí ìyọnípò náà, wọ́n máa ṣètò ìdìbò láàárín oṣù méjì láti fi yan ààrẹ mìíràn.

Olóòtú ìjọba ni yóò máa ṣàkóso ètò orílẹ̀ èdè títí tí wọ́n fi máa ṣètò ìdìbò láti yan ààrẹ tuntun.

Kí ló fa táwọn aṣòfin fi yọ Yoon nípò?

Àwọn ará ìlú tó ń dunnú lẹ́yìn tí wọ́n kéde ìyọnípò Yoon Suk-yeol

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Àwọn ará ìlú tó ń dunnú lẹ́yìn tí wọ́n kéde ìyọnípò Yoon Suk-yeol

Ní ọ̀sẹ̀ tó kọjá ni ààrẹ Yoon kéde lílo òfin àwọn ológun tí wọ́n ń pè ní "martial law" dípò ti ìjọba alágbádá.

Èyí ló ti ń fa awuyewuye lágbo òṣèlú láti ìgbà tó ti kéde ìgbésẹ̀ náà ní ọjọ́ mọ́kànlá sẹ́yìn.

Láti ìgbà náà ni àwọn kan ti ń ní pé kí Yoon fi ipò rẹ̀ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ààrẹ àmọ́ tí Yoon kọ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀, tí èyí sì fa ìgbésẹ̀ táwọn aṣòfin fi pinnu láti yọ ọ́ nípò.

Yoon nínú àtẹ̀jáde kan tó fi léde ní òun gbà pé ìrìnàjò òun gẹ́gẹ́ bí ààrẹ yóò rí ìdádúró fún ìgbà díẹ̀ ná àmọ́ òun kò ní kó àárẹ̀ ọkàn lórí àwọn nǹkan tí òun ti ń ṣe fún South Korea láti ọdún méjì àbọ̀ tí òun ti di ààrẹ.

Òun àtàwọn èèyàn rẹ̀ ló wà lábẹ́ ìwádìí báyìí, tí wọn kò ní àǹfàní láti kúrò ní orílẹ̀ èdè náà lásìkò yìí.