Ó ti lé ní ọgọ́ta ọdún tí tọkọtaya yìí ti wàpọ̀ - Ẹ wo àṣírí ìgbeyàwó wọn

Àkọlé fídíò, Lóòtọ́ ni ìgbeyàwó n túká , ẹ wo tọkọtaya tó ti wà pọ̀ fún ọdún 65 tí ìfẹ́ wọn ṣì n gbóná
Ó ti lé ní ọgọ́ta ọdún tí tọkọtaya yìí ti wàpọ̀ - Ẹ wo àṣírí ìgbeyàwó wọn

Lati ọjọ pipẹ ni igbeyawo ti n tuka, amọ lode oni, ituka tọkọtaya ti tubọ di tọọrọ fọnkale. Oriṣiriṣi nnkan si lo n fa a , bẹrẹ lati ori iwa ipa, aijẹ olotitọ sira ẹni, ọr aje, airọmọbi, ati bẹẹbẹẹ lọ.

Ọpọ eeyan lo si n wadii aṣiri to gbe awọn igbeyawo aye atijọ ro ti wọn fi n wa papọ fun ọdun gbọọr.

Ninu ifrọwanilẹnuwo yii, BBC Yoruba ba tọkọtaya kan to ti wa pọ fun bii ọdun marunlelọgọta, sọrọ.

Ọpọlọpọ alaye ni wọn sẹ lori aṣiri igbeyawo wọn, ati awọn nnkan to n fa ipinya laarin tọkọtaya lode oni.

Baba to jẹ ọkọ, Alagba Akanbi Mulero Akintunde, ẹni aadọrun ọdun sọ pe ọga to kọ oun niṣẹ kafinta, lo fẹ iyawo oun, Arabinrin Sinatu Mulero, fun oun lẹyin ti oun sọ fun un pe o wu oun.

"Lẹyin ti mo kọṣẹ tan lọdọ ọga mi, mo lọ ọ fẹ lọdọ awọn obi rẹ.

"Ohun ti mo ri lara rẹ nigba naa ni pe o tutu, o si jẹ ọmọ ọdọ agbalagba."

Alagba Akintunde sọ pe iyawo oun ko bu oun ri, bẹẹ ni oun naa ko sọ ọrọkọrọ si i ri.

"Eewọ niru nnkan bẹẹ jẹ fun wa."

O ni aṣiri to wa nidi bi igbeyawo wọn ṣe tọjọ ni pe awọn ko ṣe ju agbara rẹ lọ.

Baba agba naa sọ pe asọyepọ ati ijiroro lori bi awọn ṣe fẹ ẹ ṣe eto ile ati igbeaye wọn tun ni aṣiri keji ti awọn ni.

Awọn nnkan to n fa ituka lode oni

Tọkọtaya Mulero

Ninu ọrọ tiẹ, Arabinrin Sinatu Mulero sọ pe ti ija ba tiẹ waye laarin awọn, ẹnikẹni kii gbọ tabi mọ nipa rẹ.

"Eeyan o le ṣe ko ma ri ija pẹẹpẹẹpẹ, ibinu a waye, a si tun pari ẹ."

Alagba Akintunde sọ pe laye ode oni ni pe takọtabo to n fẹ ara wọn ko gbọ ẹkọ iya ati baba wọn.

Nnkan miran to tun tọka si ni aini ifaramọ ati ifarada.

"Ti ọkunrin ko ba ni ẹkọ, iyawo ko ni le gbe ile rẹ. Bakan naa ni ti obinrin ko ba ni ẹkọ, oun ati ọkọ ko ni le gbaduna ra wọn."

"Ati ọmọkunrin ati ọmọbinrin ni ẹkọ ile ṣe pataki fun lati ni."

Lara awọn nnkan miran to tun tọka si pe o n fa ituka igbeyawo lasiko yii ni pe pupọ eeyan lo n pari ọrọ igbeyawo laarin ara wọn ṣaaju ki wọn o to sọ fun ẹbi wn lai si iwadii agbalagba.