CBN kéde pé aráàlú kò ní lè gbà ju N100,000 lọ lójúmọ́ lórí POS

Oniṣowo POS to n ka owo

Oríṣun àwòrán, Other

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ile ifowopamọ apapọ Naijiria (CBN), ti gbe gbedeke owo ti onibara le gba lori ẹrọ POS lojumọ si ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un kan naira (100,000).

Ọjọ Iṣegun, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kejila ọdun 2024, ni CBN fi atẹjade kan sita, ninu eyi ti wọn ti kede igbesẹ yii.

Atẹjade naa ti Oladimeji Yisa Taiwo, buwọ lu lorukọ Adari CBN, kede pe ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta naira (500,000) ni gbedeke owo ti araalu le gba lọsẹ bayii.

Fun awọn alakooso okoowo POS ti a mọ si ejẹnti, to n fun awọn oni-POS keekeekee lowo, CBN ti gbe gbedeke wọn si miliọnu kan ati ẹgbẹrun lọna igba naira (1.2m) lojumọ.

Gẹgẹ bi awijare CBN, wọn ni igbesẹ yii ṣe pataki lati din bi awọn eeyan ṣe n gbe owo rin ku.

CBN ṣalaye pe ohun ti oyinbo n pe ni 'cashless policy', eyi ti kara-kata ati okoowo gbogbo ko nilo owo beba, ṣugbọn ti a o maa fowo ranṣẹ si akanti awọn ti a n ba dowopọ lo dara ju.

Ẹ o ranti pe CBN gbe igbesẹ yii kan naa lọdun 2023, lasiko ti ijọba mu ayipada ba awọ owo 200, 500 ati 1,000 naira.

Inira ti 'cashless policy' naa mu ba araalu pọ nigba naa, debii pe ẹmi awọn eeyan kan bọ si i nibi ti wọn ti n daamu latari ohun ti ijọba aarẹ Buhari to wa nipo nigba naa gbe kalẹ.

Bẹẹ ni ohun ti Godwin Emefiele ti i ṣe gomina CBN nigba naa ko awọn eeyan si, nitori cashless policy yii ko ṣee gbagbe nin

Ìbẹ̀rùbojo, ìdààmú gba ọkàn aráàlú, nítorí ìgbésẹ̀ CBN

Ṣaaju gbedeke iye owo ti araalu le gba yii ni ai si owo naira ti n ṣẹlẹ.

O ti to ọsẹ meloo kan bayii ti awọn eeyan Naijiria ti n koju ai ri owo gba ni banki ati lọdọ awọn oniṣowo POS gan-an.

Lọdọ awọn oniṣowo POS, ọpọ wọn ni wọn ti fi owo kun iye ti wọn n gba tẹlẹ lọwọ onibaara.

Awijare wọn si ni pe awọn ko ri owo gba ni banki, bẹẹ ni awọn n fi owo ra owo ti awọn n san fun araalu ni.

Eyi lo ti n ṣẹlẹ to si n ko wahala ba awọn eeyan, paapaa bi ọdun ṣe n bọ lọna yii.

Ṣugbọn pẹlu ofin adinku owo ti CBN tun ṣe yii, ohun ti awọn ọmọ Naijiria n sọ ni pe ṣe ohun ti yoo tun mu alekun inira ba awọn kọ ni ijọba tun gun le yii?

Kí ló ń fa ìṣòro yìí gan-an?

Aworan ọwọ to n ko owo naira jade.

Oríṣun àwòrán, Getty image

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Yatọ si banki to pọ lọ jàrá ni Naijiria, ibudo POS to fi orukọ silẹ lorilẹde yii loṣu keje ọdun 2024, jẹ miliọnu mẹrin ati ẹgbẹrun mẹfa.( 4.06 million registered PoS terminals).

Ajọ Nigeria Interbank Settlement System Plc, lo sọ eyi di mimọ.

Ṣugbọn pẹlu akọsilẹ yii, ati awọn onka mi-in to tun wa, iyalẹnu lo jẹ pe ọwọngogo owo naira ṣi tun n gbode.

B'awọn kan ṣe n sọ pe ijọba fẹẹ ko owo atijọ kuro nilẹ ni, bẹẹ lawọn mi-in n sọ pe awọn ọlọja to n ta owo fun awọn oni-POS lo n da wahala silẹ.

Bakan naa ni awuyewuye gbode, pe ọwọ awọn oṣiṣẹ banki paapaa ko mọ ninu ọrọ yii.

Eeyan yoo fẹẹ gba ẹgbẹrun lọna ọgun naira, wọn yoo fun un ni marun-un pere.

O si le jẹ igba naira ati ọndrẹdi naira ni wọn yoo tun fi sanwo naa.

Nibo ni owo yooku wa?

Owo tuntun ti fẹrẹ di eewọ ni banki, awọn araalu ki i ri i gba mọ.

Nibo ni owo tuntun lọ?

Sibẹ, awọn kan n ri owo tuntun yii gba lọpọ yaanturu, wọn n na an lode ariya.

Loṣu Kẹwaa ọdun 2024 yii, owo ti CBN sọ pe o wa lode jẹ ₦4.5 trillion, eyi to tun le si iye to wa lode ni oṣu kẹsan-an.

Bi iru owo bẹẹ ba wa laaarin ilu, ko yẹ ki iṣoro wa fun araalu lati ri owo gba, gẹgẹ bi alaye awọn amoye lori ọrọ aje.

Bi CBN ṣe n sọ pe ki araalu fi ẹjọ banki to ba kuna sun, ti wọn n fi owo itanran nla lelẹ fun banki to ba jẹbi ẹsun ai ri owo gba yii, bẹẹ ni iṣoro naa n pọ si i.

Yatọ si inira ati idaamu ti iṣoro yii n da silẹ, idojuti ati ai kunju oṣunwọn banki apapọ ati awọn banki kereje ni ọpọ araalu ka a si.

Eyi ri bẹẹ, nigba ti ko sẹni to fẹẹ gba ẹbi ohun to n ṣẹlẹ gan-an.