Ààfin Ooni sọ̀rọ̀ lórí àpèjẹ Olori Naomi níbi tí ọ̀pọ̀ ọmọdé ti kú n'Ibadan

Oríṣun àwòrán, queen_silekunolanaomi_ogunwusi/Instagram
Aafin Ooni Ile Ife ti kẹdun pẹlu ijọba ipinlẹ Oyo, ileeṣẹ Redio Agidigbo ati ajọ WINGS to jẹ ti Olori Ooni tẹlẹ ri, Arabinrin Naomi Silekunola Ogunseyi, lori awọn ọmọde to padanu ẹmi wọn nibi apejẹ ti Arabinrin Naomi ṣagbatẹru rẹ niluu Ibadan l'Ọjọru.
Ninu atẹjade kan ti adari eto iroyin fun aafin Ooni, Otunba Moses Olafare, fi sita ni aafin Ooni Ile Ife, Enitan Ogunwusi, Ojaja Kẹta ti sọ pe ọgbẹ ọkan ni iṣẹlẹ yii jẹ fawọn naa.
Kabiyesi wa gbadura wi pe ki Eleduwa tu awọn obi awọn ọmo to doloogbe nibi iṣẹlẹ naa ninu.
''A tun fi asiko kẹdun pẹlu ijọba ipinlẹ Oyo lori iṣẹlẹ to bani lọkan yii papaa julọ Gomina Seyi Makinde lori awọn igbesẹ to gbe nigba ti iṣẹlẹ naa waye.
Iru iṣẹlẹ bayii pe fun ifọwọsowọpọ gbogbo eeyan lati daabo bawọn ọmọde kaakiri orilẹede Naijiria.
Lasiko ti Arabinrin Naomi fi jẹ Olori ni Ile Oodua, o fi ifẹ han sawọn ọmọde ni Ile Ife nipa ṣiṣe agbekalẹ oniruuru eto lati ṣe iranwọ fawọn eeyan ti ko rọwọ họri lawujọ papaa julọ lasiko ọdun bayii.
Ile Oduduwa wa ṣeleri lati ṣe iranwọ lori akitiyan lati tu awọn obi to padanu ọmọ wọn ninu iṣẹlẹ naa ninu.''
Aafin Ooni tun pe fun ọna lati fopin si iru iṣẹlẹ yii lọjọ iwaju nipa titẹle awọn alakalẹ lori eto aabo fawọn ọmọde lawọn ile ẹkọ.
Bakan naa ni aafin Ooni tun bu ẹnu ẹtẹ lu awọn akọroyin kan ti wọn n gbe oriṣiiriṣii iroyin eyi ti ko ṣẹlẹ nipa apejẹ naa jade.
''Awọn iroyin ofege ti ko fẹsẹ mulẹ tawọn kan n gbe kiri nipa iṣẹlẹ naa tun n dakun ibanujẹ awọn obi ti wọn padanu ọmọ wọn ni nibi iṣẹlẹ naa.
A rọ gbogbo awọn akọroyin lati ṣe pẹlẹ ki wọn si sọ bi ọrọ sẹ ri gan an nigba kugba ti iru iṣẹlẹ yii ba waye.
Ile Oduduwa rọ gbogbo eeyan tọrọ kan lati ori ijọba to fi dori awọn ileeṣẹ iroyin ati araalu lati lo asiko yii fun ikẹdun awọn to ba iṣẹlẹ naa lọ.
Bakan naa, a rọ Arabinrin Naomi Silekunola, Ọgbẹni Oriyomi Hamzat atawọn ti wọn jọ ṣagbekalẹ eto yii pe ki wọn ma kaarẹ lati tun ṣe iru eto yii lọjọ iwaju tori ohun to ṣẹlẹ.
Wọn kan nilo lati tẹlẹ awọn alakalẹ lori ṣiṣe eto to ni ṣe pẹlu ọpọ eeyan ni, ati pe wọn tun ni lati lo gbogbo ẹkọ ti wọn ti kọ ninu iṣẹlẹ yii lo,'' Aafin Ooni lo sọ bẹẹ















