Ní ìlú yìí, àwọn òǹtàjà gbàgbọ́ pé kámẹ́rà CCTV inú ṣọ́ọ̀bù wọn le ṣekú pa wọ́n

Aworan kamẹra ninu ile itaja kan.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 8

Nnkan ko rọgbọ bayii fun awọn ontaja ti wọn ni ṣọọbu ni Mogadishu, ti i ṣe olu-ilu orilẹede Somalia, pẹlu bi ijọba ṣe paṣẹ fun wọn lati fi kamẹra ti yoo maa ya aworan si ita ṣoọbu wọn, lati le maa ri awọn alakatakiti ẹsin Islam to n da ilu naa laamu.

Awọn olokowo naa sọ pe bawọn ba fi kamẹra sibi ti ijọba n fẹ, iku ti yoo pa awọn lawọn dan wo yẹn.

Wọn ni awọn awọn ọmọ ikọ Al-Shabab to n yinbọn kiri yoo yinbọn pa awọn danu ni, ti wọn ba tun kọ lati fi kamẹra naa sibẹ, ọlọpaa yoo mu awọn.

Wọnyi ni awọn oniṣowo naa to ba BBC sọrọ, ṣugbọn ti a yi orukọ wọn pada fun aabo wọn.

" Kamẹra ti wọn ni ka fi si ṣọọbu wa lo jẹ kẹ ẹ ri mi nile bayii'' Hamza Nuur, ẹni ọdun mejidinlaaadọta ti ko le lọ sile itaja rẹ mọ lo ṣalaye bẹẹ lori aga to jokoo si.

O ṣalaye fun BBC pe ko dun mọ oun lati ṣe ipinnu pe oun yoo ta ile itaja oun fun ẹlomii. O ni ṣugbọn oun gbọdọ ṣe bẹẹ ki oun ma baa ri ibinu ijọba ati tawọn Al-Shabab.

"Awọn kan ni ka fi kamẹra sita, awọn kan ni ka yọ ọ kuro. O ku sọwọ oniṣọọbu lati mu ọkan ninu lilọ si ẹwọn tabi gbigba ọta ibọn s'ara." Ọgbẹni Nuur lo ṣafikun bẹẹ.

Ọdun to kọja ni ijọba Somalia paṣẹ fun awọn oniṣọọbu lati fi kamẹra kọlọfin naa si sọọbu wọn, owo ara wọn ni wọn ni ki wọn fi ṣe e pẹlu, wọn ni eyi ni yoo ka awọn Al-Shabab lọwọ ko.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ninu ọrọ ti Igbakeji olori Mogadishu, Mohamed Ahmed Diriye, ba BBC sọ lo ti ṣalaye pe ijọba ti ri anfaani to pọ lara kamẹra to paṣẹ naa.

"Tẹlẹtẹlẹ, wọn le ju ado oloro nigba mẹrin abi marun-un laaarin oṣu kan ni Mogadishu, ṣugbọn ko ri bẹẹmọ bayii," Diriye lo ṣalaye bẹẹ.

Ni bayii, ijọba ti paṣẹ pe awọn araalu gbọdọ fi kamẹra siwaju ile wọn naa, ki i ṣe ṣọọbu nikan mọ. Wọn ni ki wọn fi si gbogbo ibi to ba yẹ niluu lati koju iṣoro awọn agbebọn ọhun.

Ṣugbọn ofin yii ti mu ipaya ba awọn araalu, wọn n bẹru pe awọn Al-Shabab le ko ogun waa ja awọn ninu ile, bawọn ba tẹle ohun tijọba n sọ.

Lati oṣu Kẹwaa si asiko yii, Al-Shabab ti pa awọn oniṣowo mẹrin ti wọn jẹ ọkunrin. Eyi waye ninu ikọlu mẹwaa, wọn pa wọn nitori wọn fi kamẹra si ile itaja wọn.

Ẹgbẹ kan to n mojuto iwa awọn agbebọn naa, Armed Conflict Location & Event Data (Acled), lo sọ eyi di mimọ.

Afojusun ijọba lori aṣẹ naa ni lati ri i pe awọn Al-Shabab dẹkun bi wọn ṣe maa n gba owo nla lọwọ awọn oniṣọobu. Ṣugbọn ipadabọ rẹ ko bimọ ire fun awọn ontaja yii, gẹgẹ bi Acled ṣe ṣalaye ẹ ninu àyọkà kan to wa loju opo ayelujara wọn.

Aworan awọn ọkunrin meji lori ọkada, wọn n kọja niwajuu ṣọọbu ti wọn tipa.

Oríṣun àwòrán, Mohamed Gabobe

Àkọlé àwòrán, Aworan ọkan ninu awọn ṣọọbu ti wọn ko le ṣi mọ, nitori aṣẹ ijọba ati ibẹru al-Shabab.

''Mo kọ́kọ́ takú pé mi ò ní í fi kámẹ́rà sí ṣọ̀ọ́bù mi, àwọn agbófinró ni kò gbà fún mi''

Ọgbẹni Nuur ṣalaye pe oun ti kọkọ kọ eti ikun si aṣẹ ijọba to ni kawọn lo kamẹra, ṣugbọn nigba ti awọn agbofinro de pẹlu ofin lo di pe ko si oun ti oun le ṣe.

"Mo gbiyanju lati ṣalaye fun wọn pe talaka ni mi, pe mi o fẹẹ ni nnkan kan lati ṣe pẹlu ijọba, ṣugbọn inu bi awọn agbofinro naa, wọn si bẹrẹ si i dunkooko mọ mi. Wọn lawọn maa ba aye mi jẹ."

Ọgbẹni Nuur sọ pe kete toun fi kamẹra naa si ṣọọbu bayii, niṣe loun bẹrẹ si i gba ipe ọlọkan-o-jọkan lati ọdọ awọn toun ko tiẹ mọ nọmba wọn.

"Niṣe ni gbogbo ara mi bẹrẹ si i gbọn, mo mọ awọn to le maa pe mi yẹn''

Awọn Al-Shabab ni Nuur n pa aṣamọ mọ. Ikọ naa ni awọn amí to maa n ṣiṣẹ ọtẹlẹmuyẹ fun wọn labẹnu, awọn ni wọn maa n tu aṣiri awọn eeyan bii Nuur to fi kamẹra si ṣoọbu.

Nuur sọ pe oun paaarọ nọmba ẹrọ ibanisọrọ oun, ṣugbọn niṣe lọmọkunrin kan tun waa ba oun ni ṣọọbu laaarọ ọjọ kan.

" O ka asọ to wọ soke, ibọn kan wa nibi ẹgbẹ rẹ, ọmọkunrin naa paṣẹ fun mi lati tan foonu mi."

O ni oun ṣe bo ṣe wi, foonu oun si dun lẹsẹkẹsẹ lai gbe orukọ ẹni to n pe naa jade.

O ni ẹni to n pe naa beere lọwọ oun pe ṣe aṣẹ ijọba lo ṣe pataki ju ni abi ti ẹni to n pe naa.

"Mi o mọ ohun ti mo le ṣe, ọmọkunrin ti ibọn wa lara rẹ yẹn duro naa ni ba a ṣe n sọrọ lọ. Emi ti ẹ ti n ro o pe o maa yinbọn pa mi ti mo ba ti pari ipe naa ni. Nitori naa, mo rọra ṣe adura idakẹjẹjẹ lọkan mi.''

Nuur lo sọ bẹẹ.

O ni ṣugbọn oun ri aanu gba, ọmọkunrin naa jade ninu ṣọọbu oun lai yinbọn nigba ti ipe naa pari."

Nuur loun pinnu lati ta ṣọọbu oun loṣu Kẹwaa, lẹyin ti awọn agbebọn naa pa awọn oniṣowo meji bii toun.

"Ẹ wo o, ko sohun to ṣe pataki ju ẹmi eeyan lọ.''

Bẹẹ ni Nuur wi .

Aworan ikọ Al-Shabab ti wọn bo oju, wọn si gbe asia dudu wọn dani.

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, O ti fẹrẹ to ogun ọdun bayii ti awọn Al-Shabab ti n da Somalia laamu.

'Àwọn tí ìjọba kò lè mú ni wọ́n ní kí aráàlú máa bá jà''

Kinni kan to mu aṣẹ ijọba yii nira pupọ fun araalu lati tẹle ni pe awọn ti ijọba funra wọn ko le mu ni wọn n de awọn araalu si.

Eyi jẹyọ ninu alaye Ọgbẹni Nuur, o ni, "awọn eeyan ti wọn n tiraka lori ọna ti wọn yoo fi maa ri ounjẹ jẹ ni ijọba n paṣẹ fun, pe ki wọn maa ba awọn tijọba funra wọn ko le mu ja. Ẹ o ri i pe a ṣe nnkan, awa araalu ni wahala ba."

Ṣugbọn ninu ọrọ Igbakeji olori, Diriye, o ni ko sohun to jọ pe awọn oniṣowo n ti ṣọọbu wọn pa, tabi pe ijọba n fipa mu wọn lati fi kamẹra si ṣọọbu wọn.

Ṣugbọn, o ni loootọ ni pe ẹru n ba awọn ọlọja kan.

O ni ṣugbọn ijọba n fi wọn lọkan balẹ, pe nnkan kan ko ni i ṣe wọn.

" Ilu fararọ, ọja n lọ lai si wahala" Diriye lo ṣafikun bẹẹ.

Ṣugbọn ẹlomi-in to tun ba BBC sọrọ, Asiyo Mohamed Warsame, ṣalaye pe awọn agbebọn to n bo oju ni wọn pa ẹgbọn oun, ẹni ogoji ọdun sinu ṣọọbu rẹ ni Mogadishu.

O ni Dahir Warsame Mohammed ni ẹgbọn oun naa n jẹ.

Lori idi ti wọn fi pa a, Asiyo sọ pe nigba to fi kamẹra si sọọbu rẹ loṣu kẹwaa ni. Awọn agbofinro to fi dandan le e pe ko fi ẹrọ naa si ṣọọbu ni wọn jẹ ko kagbako iku ojiji, gẹgẹ bi aburo rẹ sẹ sọ.

"Ọmọ mẹfa lo fi silẹ lọ, eyi to kere ju ninu wọn jẹ ọmọ oṣu mẹrin." Asiyo lo sọ bẹẹ.

Bakan naa ni Ismael Hashi, ẹni ọdun mẹtalelọgbọn, sọ pe oun ti ṣoọbu oun pa nigba ti awọn ipe ti ko ni nọmba n ti ọdọ wọn Al-Shabab wa.

"Wọn mọ orukọ mi ati ọpọlọpọ nnkan nipa mi, afi bii pe wọn ti mọ gbobgbo nnkan pata nipa mi ni.''

Hashi ni oun pada gba ipe kan lati ọdọ awọn ọlọpaa, ti wọn n sọ foun pe koun lọọ ṣi ṣoọbu. O ni nigba toun ko da wọn lohun, niṣe ni wọn waa gbe oun, ti wọn ti oun mọle fun ọjọ diẹ ki wọn too fi oun silẹ. O ni oun ti n ṣi ṣoọbu naa pada bayii.

" Kamẹra naa ṣi wa ni ṣoọbu mi, nitori aṣẹ ijọba ni, ṣugbọn mo mọ pe ijọba ko le da aabo bo mi bi ẹnikan ba pinnu lati gba ẹmi mi" Bẹẹ ni Hashi wi.

"Bi mo ba ri eeyan to wọle waa ba mi ni ṣọọbu, aya mi aa si ka soke, nitori mo maa n ro o pe ṣe ki i ṣe ẹni ti wọn ran pe ko waa pa mi ree. "

Sidow Abdullahi Mohamed, ẹni ọdun mọkandinlogoji, sọ fun BBC pe nitori oun kọ lati fi kamẹra si inu ile ni wọn ṣe fi ofin mu oun. Agbegbe Wajir lo ni ile naa wa.

O ni wọn tun mu awọn mẹrinla miran to kọ lati fi ẹrọ naa sinu ile wọn pẹlu.

Sidow sọ pe awọn ti fi kamẹra naa sile bayii o, ṣugbọn inu ibẹrubojo lawọn n gbe.

" Gẹgẹ bi araalu, wọn fipa mu wa lati ra kamẹra sile, a sanwo ti wọn fi ba wa ṣe e ni paapaa, bẹẹ la si wa lọwo ewu ikọlu Al-Shabab to ṣee ṣe ki wọn wọle wa.

Ṣe pẹlu iru iwa yii ni ijọba ro pe araalu yoo fẹran awọn?"