Kókó márùn ún nínú ètò ìṣúná N47.96tn tí Tinubu gbé lọ síwájú ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin l'Abuja

Aworan Aarẹ Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, Presidency/X

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Aarẹ Bola Tinubu ti gbe eto iṣuna ọdun 2025 lọ siwaju ile aṣofin l'Abuja ni Ọjọru,

ọjọ kejidinlogun oṣu Kejila ọdun 2024.

Lasiko ijokoo ile l'Ọjọru ni Tinubu gbe eto iṣuna to pe ni eto iṣuna ipadabọsipo, alaafia ati ọrọ lọ siwaju awọn aṣofin.

N47.96tn ni gbogbo iye owo ti ijọba apapọ Naijiria fẹ na lọdun 2025 gẹgẹ bi Tinubu ṣe gbe e kalẹ niwaju ile aṣofin.

Aarẹ Tinubu sọ fawọn aṣofin pe eto iṣuna naa yoo jẹ ki ọwọngogo nnkan lọlẹ lati ida 34% to wa lọ si ida 15% lọdun 2025.

Bakan naa ni Tinubu tun sọ pe owo dọla si naira yoo tun walẹ sii lati N1,700 to wa bayii lọ si N1,500.

Aarẹ Naijiria fikun ọrọ rẹ pe agba epo rọbi ti Naijiria n pese lojumọ fun tita yoo di 2.06m lọdun 2025.

N34.82tn ni owo ti Tinubu sọ pe ijọba n reti lati pa wọle lọdun 2025.

N47.90tn ni owo ti Aarẹ Tinubu sọ pe ijọba oun yoo na lọdun 2025 nigba ti N15.81tn yoo ba sisan ele owo gbese ti Naijiria jẹ lọ.

Koko to wa ninu eto iṣuna 2025 ti Tinubu gbe lọ siwaju ile aṣofin

Ẹka eto abo - N4.91tn

N4.91tn ni ijọba apapọ yoo na lori eto abo lọdun 2025 gẹgẹ bi o ṣe wa eto iṣuna ti Tinubu gbe lọ siwaju ile igbimọ aṣofin agba l'Abuja l'Ọjọru.

Tinubu ni awọn ileeṣẹ ọmogun, atawọn ẹṣẹ eleto aabo mii ni yoo gba owo to pọ julọ ki wọn le daabo bo awọn ibode orilẹede Naijiria daadaa.

Tinubu ṣeleri lati maa mu ọrọ eto aabo orilẹede Naijiria ni ọkunkundun.

Aarẹ Naijirina ni ijọba oun yoo tẹsiwaju lati maa ṣe koriya fawọn oṣiṣẹ eleto abo ki wọn le maa tẹsiwaju lati maa daabo bawọn araalu.

Bakan naa ni aarẹ sọ pe ijọba oun ko ni kaarẹ nipa gbigbaruku ti awọn ileeṣẹ ọmogun pẹlu bi wọn ṣe gbogun ti igbesunmọmi.

Ohun amayedẹrun – N4.06tn

Nnkan keji ti ijọba yoo tun nawo to pọju ṣikeji lọdun 2025 ni nnkan amayedẹrun.

Aarẹ Tinubu sọ fawọn aṣofin pe ijọba oun ti bẹrẹ awọn akanṣẹ iṣẹ kan bii ọna mọrosẹ lati ilu Eko si Calabar ati Sokoto si Badagry eyi ti yoo ṣe awọn araalu lanfaani.

Bakan naa ni aarẹ sọ pe awọn akanṣẹ iṣẹ yii yoo ni ipa rere lori eto ọrọ aje Naijiria.

Tinubu fikun ọrọ rẹ pe akanṣẹ iṣẹ lẹka ina mọnamọna, igbokegbodo ọkọ ati iṣẹ ilu yoo pese iṣẹ yanturu fun araalu.

Bakan naa ni aarẹ sọ pe awọn akanṣẹ iṣẹ yoo mu idagbasoke ba orilẹede Naijiria.

Ẹka eto ilera – N2.48tn

Aarẹ Tinubu sọ fawọn aṣofin wi pe ijọba oun ti ya N402bn sọtọ fun awọn akanṣe iṣẹ lẹka eto ilera lọdun 2025.

Aarẹ tun sọ pe ijọba oun tun ti ya N282.65bn sọtọ fun ipese eto ilera alabọde.

O ni ijọba oun yoo ṣe itaniji fawọn ile iwosan ijọba lọdun 2025 pẹlu oogun to dara atawọn nnkan mii.

Tinubu ni ijọba oun ti pese fun ipese ogun fawọn ileewosan ijọba kaakiri Naijiria lọdun 2025, eyi ti yoo mu adinku ba lilọ gba itọju nilẹ okeere.

Ẹka eto ẹkọ - N3.52tn

N3.52tn ni ijọba apapọ yoo na lori ẹka eto ẹkọ ni Naijiria lọdun 2025 gẹgẹ o ti wa lakọsilẹ ninu eto iṣuna ti Tinubu gbe lọ siwaju ile igbimọ aṣofin l'Abuja.

Tinubu ni ijọba oun ti ya N826.90 sọtọ ninu eto iṣuna ọdun 2025 lati na lori akanṣe awọn eto kan lẹka eto ẹkọ.

Tinubu ni lara owo yii yoo lọ si awọn ile ẹkọ giga mẹsan ti ijọba ṣẹṣẹ da silẹ ati eto ẹkọ kari-aye UBEC.

Ẹka eto ọgbin

Aarẹ Tinubu ni ijọba oun yoo ṣe iranwọ fawọn agbẹ pẹlu owo ki wọn le da oko to pọ ki ounjẹ le sun araalu bọ.

Aarẹ ni ijọba oun yoo gbiyanju lati ri pe ounjẹ wa fun araalu lati jẹ ti ko si ni jẹ ọwọngogo.

Tinubu sọ pe ebi ko ni pa ọmọ Naijiria labẹ iṣẹjọba oun lọdun 2025.