Ààrẹ Tinubu sọ̀rọ̀ lórí ikú àwọn ọmọdé tó wáyé níbi ayẹyẹ Naomi nìlùú Ibadan

Oríṣun àwòrán, Others
Aarẹ Bola Tinubu ti paṣẹ pe ki iwadii bẹrẹ ni kiakia lori awọn nnkan to ṣokunfa bi awọn eeyan ṣe tẹ ara wọn pa nibi apejẹ opin ọdun niluu Ibadan.
Olori Ooni Ile-Ife nigba kan, Naomi Silekunola, lo sẹ agbatẹru ayẹyẹ naa nibi ti ireti ti wa pe awọn ọmọ bii ẹgbẹrun marun-un yoo ri ẹbun owo ati ounjẹ ọfẹ gba.
Ṣugbọn iroyin sọ pe eero to pọju ninu ọgba ile-ẹkọ Islamic High School, Bashorun, nibi to yẹ ki eto ti waye, lo fa a ti wọn fi bẹrẹ si ni ṣubu lu ara wọn.
Ninu atẹjade kan ti oluranlọwọ pataki fun aarẹ lori eto iroyin, Bayo Onanuga, fi sita l'Ọjọru, ni Tinubu ti sọ pe o ṣe pataki lati fidirẹ mulẹ boya ailakasi tabi nnkan afinu-findọ ṣe, wa lara awọn nnkan to lọwọ si ajalu buruku naa.
Bakan naa ni aarẹ sọ pe iwadii ọhun yoo mu ki akoyawọ o wa lori rẹ.
Ẹwẹ, Aarẹ tinubu ni oun rọ ijọba ipinlẹ Oyo lati gbe gbogbo igbesẹ to yẹ lati dena iru ajalu bẹẹ lọjọ iwaju. Lara awọn igbesẹ ti aarẹ la kalẹ ni ṣiṣe agbeyẹwo gbogbo awọn ilana to rọ mọ ṣiṣe ayẹyẹ ni gbangba, ati ririi daju pe awọn to n sẹ ayẹyẹ tẹle awọn ilana eeto abo ati ipamọ to yẹ nibi ayẹyẹ wọn.
Bayo Onanuga sọ pe aarẹ ba aijọba ati awọn eniyan ipinlẹ Oyo kẹdun lori iṣẹlẹ naa, to fi mọ awọn ẹbi to n ṣe ọfọ awọn ọmọ wọn to ku.
O ni "aabo awọn ọmọ wa ṣe koko, ti ayẹyẹ kankan ko si gbọdọ ṣe nnkan to lodi si aabo ẹmi wọn".
Ki la wọn nnkan to ti ṣẹlẹ sẹyin?
O kere tan, ọmọde marunlelọgbọn lo ku, ti ọpọ si farapa, nibi apejẹ ti olori Ooni Ile-Ife tẹlẹ, Naomi Ogunwusi, ṣe niluu Ibadan.
Ọjọru, ọjọ kejidinlogun, oṣu Kejila, ọdun 2024, ni eto naa yẹ ko waye, amọ gbogbo rẹ foriṣanpọn nitori ohun to ṣẹlẹ
Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn sọ fun BBC Yoruba pe ko tii pẹ ti eto bẹrẹ, ti awọn eeyan fi bẹrẹ si ni tẹ ara wọn.
Igba akọkọ kọ ree ti Olori Naomi Silekunola Ogunwusi ṣe eto apejẹ naa.
Ọdọọdun lo maa n ṣe e labẹ ajọ ẹlẹyinju aanu rẹ to pe ni, Women in Need of Guidance and Support (WINGS).
Awọn ti ọmọ wọn farapa ba BBC sọrọ
Ọkan lara obi awọn ọmọ ti ori ko yọ lọwọ iku ojiji nibi apejẹ ti Olori Ooni Ile-Ife tẹlẹ, Naomi Ogunwusi ṣe niluu Ibadan, ti ṣe alaye bi ọgọọrọ ero ṣe tẹ awọn ọmọ rẹ meji mọlẹ lasiko ijijadu fun ẹbun ọdun.
Ninu ọrọ ti o ba awọn oniroyin sọ, Arabinrin naa ṣe alaye wi pe ori redio ni awọn ti gbọ ikede wi pe Olori Ooni Ile-Ife tẹlẹri, Naomi fẹ pin ẹgbẹrun Naira fun awọn eeyan lati ṣe ami ayẹyẹ opin ọdun.
Ilepa ati gba ẹbun ọdun lo si mu ki o ko awọn ọmọ tiẹ naa lọ si ibi eto naa.
Ọkan ninu awọn ọmọ mejeeji naa ti pada sile lẹyin ti o gba itọju nile iwosan, ṣugbọn ikeji ṣi wa ni ibi ti wọn ti n tọju rẹ ni ọkan lara awọn ile iwosan ijọba ipinlẹ Ọyọ.
Ẹlomii ti o ko awọn ọmọ rẹ mẹtẹẹta lọ si ibi eto naa ni lati Olodo lẹ Baṣọrun sọ ohun ti oju rẹ ri lasiko ti igbakeji Gomina ipinlẹ Ọyọ, Adebayo Lawal ṣe abẹwo si ọkan lara awọn ile iwosan ti wọn ko awọn eeyan to fi ara pa nibi iṣẹlẹ naa lọ.
O ni ori redio naa ni ohun ti gbọ wi pe ounjẹ ọfẹ ati ẹbun ọdun wa fun awọn ọmọ kekeeke, eyii lo mu ki oun naa tara ṣaṣa lọ si ibi eto naa.
Awọn ọmọ mẹtẹẹta ti o ko lọ naa ni wọn tẹ mọlẹ lasiko ti awọn eeyan n kọlu ara wọn ni ibi ti wọn ti fẹ gba ẹbun ọdun, ṣugbọn a ko le sọ boya awọn mẹtẹẹta naa ni o ṣi wa laye, nitori pe ọmọ kan ṣoṣo ni a ri pẹlu Arabinrin naa lasiko ti o ba igbakeji Gomina ipinlẹ Ọyọ sọrọ.
Ileeṣẹ ọlọpaa mu Naomi Silekunola ati awọn eeyan mi
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ti sọ pe ọmọde marunlelọgbọn lo ku nibi iṣẹlẹ ikọluraẹni to waye lasiko ti apejẹ opin ọdun ti olori Ooni Ile-Ife nigba kan, Naomi Ogunwusi, ṣe niluu Ibadan.
Bakan naa ni ọmọde mẹfa ṣi wa nileewosan nitori wọn farapa kọja aala.
Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa, Osifeso Adewale fi sita ni ọsan Ọjọbọ, o ni awọn tun ti mu ẹni to ṣonigbọwọ eto naa, Wooli Naomi Silekunola.
Lara awọn ti agbẹnusọ ọlọpaa sọ pe awọn ti mu ni Fasasi Abdulahi (Ọga agba ile-ẹkọ Islamic High School, Ibadan), Genesis Christopher, Tanimowo Moruf, Anisolaja Olabode, Idowu Ibrahim, ati Abiola Oluwatimilehin.
SP Osifeso sọ pe awọn ti gbe iwadii lori iṣẹlẹ naa le ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to n mojuto iwa ọdaran lọwọ fun iwadii to yẹ.












