Orílẹ̀èdè Australia ń wá àwọn èèyàn tí yóò jápa wá sọ́dọ̀ wọn

Oríṣun àwòrán, Getty image
Nibi ti atiwọ awọn orilẹede kan ti di afi-agbara-wọ, orilẹede kan ree ti wọn ni awọn n wa awọn eeyan ti yoo japa waa ṣiṣẹ lọdọ awọn.
Australia ti kede pe oun n wa awọn ọlọpọlọ pipe eeyan ti wọn ni ẹbun kan tabi omiran, lati waa maa gbe niluu awọn.
Wọn yoo maa ṣiṣẹ nibẹ pẹlu.
Nibi eto ifilọlẹ fisa tuntun ti Australia ṣe, ti wọn pe ni 'National Innovation Visa', ni wọn ti sọ eyi di mimọ.
Fisa naa fi aaye gba mọlẹbi lati gbe ni Australia.
Ki i ṣe pe awọn to ba japa wa naa yoo gbebẹ fungba diẹ o, wọn ni wọn yoo maa bawọn gbe lọ gbere ni pẹlu fisa tuntun ti wọn tun n pe ni 'Subclass 858' naa.
Fisa tuntun yii ni orilẹede naa fi rọpo eyi ti wọn n pe ni Global Talent, ti saa rẹ pari lọjọ kẹfa, oṣu Kejila.
Kí ló dé tí Australia ń wá àwọn ọlọ́pọlọ kúnra?
Gẹgẹ bi ijọba Australia ṣe wi, wọn ni ọna kan lati fa oju awọn eeyan to ni ọpọlọ pipe ati ẹbun mọra leyi.
Orilẹede naa sọ pe awọn eeyan to le fi tiwọn gbe ẹka gbogbo de ipo agba lawọn n pe.
Wọn ni awọn eeyan naa yoo ran ọrọ aje Australia lọwọ nipa ipese iṣẹ ati agbedide ọrọ aje.
"NIV n wa awọn ti wọn ti di olori ninu iṣẹ ọwọ wọn, ati awọn to han pe aṣiwaju ni wọn ninu ohun ti wọn n ṣe.
''Awọn ti wọn le fi ẹbun wọn ran ọjọ ọla Australia lọwọ la n wa".
Ileeṣẹ to n ri si ọrọ ile niluu naa lo ṣalaye bẹẹ.
Wọn fi kun un pe awọn oniwadii agbaye, awọn oniṣowo ti wọn mọ ìdí ọlà, olokoowo to mọ ibi ti eeyan le ti fowo ṣiṣẹ, awọn elere idaraya ati gbogbo ẹni to ba le sọ ookan di eeji lawọn n wa .
Báwo lo ṣe lè kúnjú òṣùwọ̀n fún gbígba físà náà?
Ileeṣẹ to n ri si eto yii yoo kọkọ fiwe pe ọ lati waa gba fisa.
Lẹyin eyi ni o le ṣẹṣẹ lọọ gba fisa ọhun.
Ẹni to fẹẹ gba fisa yii tun gbọdọ jẹ gbajugbaja ti wọn mọ orukọ rẹ nilẹ okeere, fun ipa to n ko ninu iṣẹ to n ṣe.
Bakan naa lo gbọdọ jẹ pe gbajugbaja nilẹ okeere ni ẹni to fi orukọ rẹ ranṣẹ si Australia.
Ọ gbọdọ jẹ gbajumọ loke okun, yala lẹka ere idaraya, iṣẹ-ọnà (arts), olukọni tabi oluwadii.
Eyi tumọ si pe o gbọdọ ni amuyẹ to ju ti awọn eeyan yooku lọ.
O gbọdọ ni akọsilẹ aṣeyọri ti yoo ṣoro fawọn ẹlomiran lati gba.
Awọn eeyan gbọdọ mọ pe ara ọtọ ni tiẹ labala ohun ti o n ṣe.
Nipa ọjọ ori, wọn ni ko ni nnkan lati ṣe.
Awọn ti ko ti i pe ọdun mejidinlogun paapaa le kopa.
Awọn to ti le lọdun marundinlọgọta (55) naa le kopa pẹlu, ko ṣaa ti jẹ ẹni to le ṣafikun oriire Australia.
Pẹlu fisa yii, ijọba Australia sọ pe awọn to ba bọ si i fun yoo le maa gbe nibẹ laelae.
Wọn le maa kawe ni Australia
Wọn le gba itọju nileewosan ijọba
Wọn si le bẹrẹ eto nipa bi wọn yoo ṣe di ọmọ Australia gangan.














