Ìjàmbá ọkọ̀ pa ọlọ́pàá mẹta àti obìnrin kan l'Ondo

Oríṣun àwòrán, Afolabi Idowu
Ijamba ọkọ kan to waye ti gbẹ̀mí ọlọpaa mẹta ni ilu Ore, lagbegbe Kajola, ipinlẹ Ondo, lasiko ti wọn n ṣisẹ wọn, bẹẹ ni obinrin kan ti ki i ṣe ọlọpaa naa di oloogbe pẹlu.
Alukoro Ileeṣẹ ọlọpaa Ondo, Funmilayo Odunlami-Omisanya, lọ sọ iṣẹlẹ yii di mimọ ninu atejade to fi lede.
Omisanya sọ pe ọgbẹ ọkan ni ijamba to waye lọjọ kejìdínlógún, oṣù Kejila ọdun 2024 yii jẹ fun ileeṣẹ ọlọpaa.
Lasiko to n salaye bi iṣẹlẹ naa se waye, Alukoro sọ pe ọkọ Àjàgbé DAF tó ń lọ si ilu Eko lo kuro loju ọna tìrẹ, to si gun ori pepele ti wọn fi pin opopona marosẹ Ore si meji, to si kọlu ọkọ ọlọọpa to n lọ si ilu Ore naa.
Omisanya sọ pe o jẹ ohun to ba ni ninu jẹ, pe ọlọpaa mẹta padanu ẹ̀mí wọn ninu ijamba ọkọ ọhun, ti ọkan ninu wọn to farapa si wa nile iwosan bayii.
Nipa obinrin to di oloogbe pẹlu awọn agbofinro naa, Alukoro sọ pe obinrin naa n wa ọna atijẹ rẹ lọ ni.
O ni ki i ṣe afurasi ọdaran bawọn ẹka iroyin kan ṣe n gbe e kiri.
O rọ awọn akọroyin lati maa gbe iroyin to jẹ ojulowo, pàápàá pẹlu irufẹ iṣẹlẹ yii, ki wọn si bọwọ fun oku ọrun ati awọn ẹbi wọn ti wọn wa ninu ibanuje lasiko yii.














