Awakọ̀ wa ọkọ̀ wọ inú ọjà ọdún Kérésìmesì, èèyàn 200 farapa

Aworan ibi isele naa

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Nṣe lọrọ di bi o ko le lọ, ki o yago lọna laarọ ọjọ Abamẹta nigba ti wọn sọ pe awakọ kan wa ọkọ rẹ niwakuwa wọ aarin awọn eeyan ninu ọja Keresimesi kan ni orilẹede Germany, to si ṣe ọpọ awọn eeyan lese.

Awọn eeyan ti ko din ni igba la gbọ pe wọn fara kaaṣa ikọlu naa, nigba ti awọn mọkanlelogoji farapa yannayanna.

Obinrin kan to wa pẹlu ọrẹkunrin rẹ ti wọn wa ninu ọja Keresimesi ọhun to wa ni Magdeburg sọ fawọn akọroyin pe oun di ololufẹ oun lọwọ mu lasiko ti ọkọ naa n sare bọ niwaju awọn.

"Niṣe ni ọkọ naa gba a danu kuro lẹgbẹ mi. I buru jai," Nadine, ẹni ọdun mejilelọgbọn naa sọ fun iwe iroyin Bild.

Fọnran kan to wa loju opo iroyin ilẹ Gẹẹsi kan ṣafihan ọkọ dudu kan to sare wọ aarin ero pẹlu ere asapajude, to si n lọ siwaju pẹlu ere ọhun.

Ọrẹkunrin Nadine lo fi ẹsẹ ati ori ṣeṣe kọja sisọ.

Ọkan lara awọn ti iṣẹlẹ ọhun ṣoju rẹ, Gianni Warzecha, sọ fun BBC pe oun n gbọ orin Keresimesi loun n gbọ lọwọ pẹlu mọlẹbi ọrẹbinrin oun ninu ọja naa nigba ti "a gbọ ariwo ati rukerudo lojiji pẹlu ariwo gilaasi to n fọ silẹ".

"Iporuru ọkan bẹrẹ sii mu awọn eeyan, mo ri ọkọ naa pẹlu awọn eeyan nilẹ, ara awọn eeyan ti kun fun ẹjẹ. Awọn ọmọde naa wa nibẹ pẹlu.

"Bi maa ṣe doola ẹmi awọn eeyan ni gbajumọ. O gba awọn olujọ ni iṣẹju diẹ ko to di pe wọn de, bo tilẹ jẹ pe wọn ko pọ to nitori pe igba eeyan lo farapa.

"Itọju akọkọ ti wọn ṣe lo jẹ pe awọn to wa nibẹ lo ṣe e."

Lars Frohmüller, akọroyin MDR kan to debi iṣẹlẹ ọhun lẹyin ijamba naa sọ fun BBC nipa ohun ti oju rẹ ri.

Heike Janke

Oríṣun àwòrán, Reuters

"Awọn ọkọ iṣẹlẹ pajawiri wa kaakiri, awọn ọlọpaa naa ti de, awọn panapana naa ko gbẹyin fun aabo.

"Ajalu nla ni iṣẹlẹ yii. A ri ẹjẹ awọn eeyan nilẹ, a ri awọn eeyan ti wọn jokoo lẹgbẹ ara wọn, ti wọn si ni awọn ohun to yi wọn ka. A si ri awọn dokita ti wọn n gbiyanju lati tọju awọn to farapa.

"Iṣẹlẹ ojiji nla ni. O mu iporuru ọkan ba awọn eeyan nibi ni Magdeburg ati gbogbo awọn eeyan ni ."

Tobias Rausch, toun naa wa ni ọja Keresimesi, ẹni to tun jẹ akọwe agba fun ayẹyẹ AfD ni Saxony-Anhalt, sọ fun Reuters pe iṣẹlẹ ọhun banilẹru.

Rausch ṣalaye pe oun ko tii debi ayẹyẹ naa ti awọn fi di pe "lojiji, a bẹrẹ sii gbọ ariwo, ati ẹnijiini ọkọ to n dun pẹlu ariwo nla.

"Awọn eeyan n pariwo. Aarin iṣẹju aaya ni iṣẹlẹ ọhun fi waye."

Ọkunrin naa ni boun ṣe yẹra nibi ijamba ọhun, oun bẹrẹ sii ka fọnran ọkunrin to da ikọlu naa silẹ.