Ọkùnrin tí wọ́n dájọ́ ikú fún lórí pé ó jí adìẹ gbé sọ̀rọ̀

Segun Olowookere

Oríṣun àwòrán, Remi Tunde

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Lati bi ọjọ meloo kan sẹyin lọrọ gendekunrin ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn kan, Segun Olowookere ti wọn dajọ iku fun lori ẹsun jiji adiẹ gbe lọdun mẹwaa sẹyin ti n ja rainrain lorileede Naijiria.

Ko si nnkan meji to jẹ ki ọrọ Olowookere di ohun ti awọn eeyan n jiroro le lori, to kọja bi Gomina Ademola Adeleke ṣe loun yoo fi oju aanu wo ọmọkunrin naa.

Gomina Adeleke ni ki adajọ agba ipinlẹ Osun ṣe atungbeyẹwo ẹjọ naa, lati le jẹ ki orukọ Olowookere wa lara awọn ẹlẹwọn ti yoo ri aanu ijọba gba ki ọdun 2024 too pari.

Nigba to n ba ileeṣẹ iroyin PUNCH sọrọ laipẹ yii, Olowookere sọ pe ẹgbẹrun lọna ọgbọn ti awọn obi oun ko ri ko silẹ fun ọga ọlọpaa igba naa lo jẹ ki oun dero ọgba ẹwọn.

O ni ọdun mẹtadinlogun loun wa nigba ti awọn ọlọpaa wa gbe oun ninu ṣọọbu ti baba oun ti n ta kasẹẹti lọdun naa, to si jẹ iyalẹnu wi pe wọn fi ẹsun jiji adiẹ gbe kan oun.

Awuyewuye yii lo jade lẹyin ti awọn obi Olowookere sọrọ nibi ifọrọwerọ kan ti oṣerebinrin nni, Biola Bayo ṣe fun wọn lori ayelujara.

Nigba to n sọrọ, Olowookere sọ pe "Inu ṣọọbu baba mi ni mo wa ni Oyan lẹyin ti mo de lati ile-ẹkọ. Emi pẹlu baba n sọrọ lnipa bi maa ṣe wọ fasiti lọwọ ni a deedee gbọ iro ibọn, ti awọn eeyan si n sa asala fun ẹmi ara wọn, yatọ si baba mi ati awọn kan."

Ọmọkunrin naa ni awọn ọlọpaa mu baba oun lọ sinu ọkọ ti wọn gbe wa lati beere oun, to si ni lati inu ọkọ naa ni baba oun ti n pariwo pe koun maa salọ.

"Awọn ọlọpaa beere lọwọ baba mi wi pe nibo ni mo wa, ti wọn si n beere lọwọ wọn pe ki ni ẹṣẹ mi. Nigba ti awọn ọlọpaa naa ko le sọ pato ohun ti wọn ni mo ṣe, baba mi pariwo wi pe ki n maa salọ nitori emi ni wọn wa mu.

"Ṣugbọn iyalẹnu lo jẹ fun mi wi pe iru ẹṣẹ wo ni mo le ṣẹ, ki ni mo ṣe, mo ni lati jade lọ ba wọn. Wọn mu mi si teṣan Oyan, ko to di pe wọn gbe mi lọ si teṣan Okuku to jẹ olori wọn lọjọ keji. Ibẹ ni mo ti pade awọn ọmọ ti wọn ko, nibi ti wọn ti n jẹ irẹsi nilẹẹlẹ."

Ẹsun ti wọn fi kan an

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Nigba to n sọrọ nipa ẹsun ti wọn fi kan an, Olowookere sọ pe ọga ọlọpaa naa beere pe ṣe oun ni Segun Olowookere, toun si sọ pe bẹẹni.

O ni DPO naa sọ foun pe awọn ọmọ ti wọn ko ni wọn darukọ oun wi pe "emi ni olori wọn."

"DPO sọ pe awọn ọmọ naa jẹwọ wi pe awọn ji adiẹ ati ẹyin adiẹ gbe. Mo ba awọn adiẹ ati kireeti ẹyin naa ti wọn jigbe ni teṣan. Mẹjọ ni awọn ọmọ naa. O sọ fun mi pe awọn ọmọ naa lo sọ pe emi ni olori wọn.

"Awọn ọmọ ti wọn n sọ yii, ọjọ ori wọn ko ju ọdun mejila si mẹtala lọ, nigba ti emi wa lọdun mẹtadinlogun nigba naa. Mo sọ pe lotitọ ni mo mọ awọn ọmọ naa ladugbo, ṣubọn ko si ohunkohun to pa wa pọ ju kiki lọ."

Olowookere ṣalaye wi pe wọn lu oun lalubami nigba toun sọ pe oun ko mọ ohunkohun nipa ẹsun ti wọn fi kan oun, ati pe iya ti wọn fi jẹ oun naa ni wọn fi jẹ Morankinyo

"Mo ṣalabapade Morakinyo ni teṣan, o si sọ fawọn ọlọpaa wi pe ounm ko mọ mi, tabi ni ohunkohun lati ṣe pẹlu mi. Nko ti ẹ mọ ibi ti wọn ti mu. Gbogbo awọn ọmọ naa ni wọn fi silẹ yatọ si emi pẹlu Morakinyo.

"Ọjọ ti mo ti de teṣan Okuku ni wọn ti n lu mi labẹ akoso DPO naa. Awọn ko lu awọn ọmọ ti wọn jale. Gbogbo igba ni DPO n sọ fun mi pe ki n sọ pe emi ni jale ti nko mọ nnkankan nipa rẹ.

"Lẹyin ọjọ diẹ, wọn fun wa ni ada lati roko teṣan pẹlu ọgbẹ to wa lara mi latari iya ti wọn fi jẹ mi."

Bawo ni ti ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira ṣe jẹ?

Olowookere sọ pe awọn ọlọpaa fẹẹ fi oun silẹ, ṣugbọn wọn loun yoo san ẹgbẹrun lọna ọgbọn, owo beeli, eyi ti awọn obi oun ko ni.

"Ẹgbẹrun lọna ogun naira ni baba mi ri ko silẹ ninu ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira ti wọn n beere. Awọn ọlọpaa sọ pe awọn ko le gba a, ayafi ti owo naa ba pe.

"Baba mi kuro ni teṣan lati wa owo naa lọ. Ṣugbọn ki wọn too pada de lọjọ keji, wọn ti ko wa lọ si ọgba SARS niluu Osogbo. Ada ti wọn fun emi pẹlu Morakinyo lati fi roko ni wọn ko fawọn SARS gẹgẹ bi ẹri, wọn sọ pe adigunjale ni wa.

"Lẹyin ọjọ mẹtadinlogun lọgba ẹwọn SARS, wọn ko wa lọ si ile ẹjọ Majisireeti pẹlu ẹsun idigunjale, latibẹ si ni wọn ti ko wa lọ sile ẹjọ giga, nibi ti wọn ti da ẹjọ iku fun wa," Segun Olowookere ṣalaye.

Siwaju sii, Segun jẹ ko di mimọ pe ẹgbọn oun kan lo ni ọgba adiẹ ti wọn ti ji awọn adiẹ ati ẹyin adiẹ ko.

"Inu agboole kan naa ni Ajirotutu niluu Oyan la ti jọ wa. Wọn pe ẹgbọn mi yii sinu ipade mọlẹbi, nibi to ti sọ pe nko si lara awọn to ji adiẹ gbe, ṣugbọn awọn ọmọ to jale lo darukọ mi.

"O sọ fawọn mọlẹbi wi pe oun yoo jawọ ninu ẹjọ naa. Ṣugbọn nigba to tun ya, niṣe lo wa jẹrii tako mi nile ẹjọ," Olowookere sọrọ.

Njẹ Segun jẹwọ?

Segun Olowookere sọ pe oun ko kọ ohunkohun silẹ ni agọ ọlọpaa lori ẹsun ti wọn fi kan oun ni agọ ọlọpaa.

Bẹẹ lo sọ pe ko si otitọ kankan ninu wi pe oun n gbe ninu ile aladagbe oni yara mẹfa nigba ti wọn jale naa, ati pe oun n gbe pẹlu awọn obi oun nigba naa ni.

"Nko kọ ọrọ kankan silẹ fawọn ọlọpaa. Awọn obi mi ko gbe ninu fulaati oni yara mẹfa. Mo n gbe pẹlu awọn obi mi nigba ti wọn mu mi ni," o ṣalaye.

Bakan naa, nigba to n sọrọ nipa idi ti agbẹjọro rẹ ko fi tako ẹsun ti wọn fi kan an, Olowookere sọ pe "Nko mọ ohunkohun, ṣugbọn ohun to da mi loju ni pe nko kọ nnkankan silẹ."