Ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá Nàìjíríà ṣàbẹ̀wò sí ẹbí Olatunji 'táwọn ọlọ́pàá' ló pokùn so látìmọ́lé n'Ilorin

Oríṣun àwòrán, Olumuyiwa Adejobi/X
Ọgba ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria, IGP Kayode Adeolu Egbetokun, ti ṣabẹwo ibanikẹdun si awọn obi Jimoh Abdulkadir Olatunji to ku si ahamọ ọlọpaa niluu Ilorin.
Lọjọ Aiku ọjọ kejilelogun oṣu Kejila ni ọga ọlọpaa ṣabẹwo si ẹbi oloogbe naa.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria, ACP Olumuyiwa Adejobi lo fi ọrọ naa lede loju opo X rẹ.
Adejobi sọ pe ileeṣe ọlọpaa ko ni gba ki awọn oṣiṣẹ rẹ maa ṣi agbara wọn lo.
Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe iwadii to peye ti bẹle lori iṣẹlẹ naa.
Ti ẹ ko ba gbagbe, nnkan bii oṣu meji ṣeyin ni awọn ọlọpaa lu ọdọkunrin kan pa nipinlẹ Kawara yii kan naa, ti awọn mọlẹbi rẹ ko si tii ri idajọ ododo gba titi di asiko yii.
Ọga agba ọlọpaa sọ lasiko abẹwo ibanikẹdun to ṣe si ẹbi oloogbe naa pe ''mo wa lati sọ fun yin pe idajọ ododo yoo waye lori iṣẹlẹ yii.

Oríṣun àwòrán, Olumuyiwa Adejobi/X

Oríṣun àwòrán, OlumuyiwaOlumuyiwa Adejobi/X Adejobi/X
A o si ni figba kan bọ ọkan ninu lati wadii ohun to ṣokunfa iku Olatunji ni ahamọ ọlọpaa to wa.
A o ni gba ki awọn kọlọnbiti ẹda kan ba ibaṣepọ to wa laarin ileeṣẹ ọlọpaa ati araalu jẹ.
Mo wọ gbogbo eeyan lati farabalẹ, ki wọn si jẹ ki ọlọpaa ṣiṣẹ wọn.''
Ninu ọrọ tiẹ, Balogun Fulani Ilorin, Alhaji Sadiq Fulani, to ṣorọ lorukiọ ẹbi oloogbe sọ pe ''ẹbi oloogbe mọ riri abẹwo ọga agba ọlọpaa.
Ireti wa ni pe ohun to jẹ otititọ yoo farahan, ati pe awọn a fẹ ki awọn to ṣiṣẹ laabi yii foju wina ofin.''
Bi iṣẹlẹ naa ṣe waye
Lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ, iya oloogbe naa, Morike Olatunji ṣalaye pe inu ile ni ọmọ oun wa lasiko ti ọkan lara awọn ti wọn jọ n ṣiṣẹ papọ ti orukọ rẹ n jẹ Jelili pe e lati pade oun ni opopona Balogun Fulani niluu Ilorin.
O ni bo ṣe de ibẹ lo ba awọn ọlọpaa meji ti wọn si gbe Olatunji sori ọkada lọ si olu ileeṣẹ wọn niluu Ilorin.
Iya Olatunji salaye pe oun lọ si agọ ọlọpaa lati gba ọmọkunrin oun silẹ ṣugbọn awọn ọlọpaa kọ jalẹ, wọn ni ọga rẹ to n ba ṣiṣẹ ti orukọ rẹ n jẹ Gabriel lo jẹ lowo tawọn fi mu un.
Ẹgbọn oloogbe to ba BBC Yoruba sọrọ, Ismail Olarewaju, ni nnkan bii aagọ mẹwaa alẹ lawọn ọlọpaa pe awọn lati wa gba beeli rẹ tawọn si sọ fun wọn pe ki wọn jẹ ki ilẹ mọ.
Ṣugbọn ni gba tawọn de agọ ọlọpaa lọjọ keji lawọn ọlọpaa ni Ọlatunji ti ku.
Ismail ni awọn bi ọlọpaa leere ohun to pa ọmọ wọn, wọn ni ṣe ni o pokunso.
O fi kun ọrọ pe awọn ri ẹjẹ nilẹ nigba ti wọn yoo fi gbe Olatunji de ile igbokupamọ si.
Bakan naa lo sọ pe awọn tun ri ẹjẹ ni imu oloogbe ọhun.















