Wo ìlèrí tí ìjọba ṣe fún ẹbí àwọn tí wọ́n tẹ̀ pa nibí tí wọ́n ti fẹ́ gba oúnjẹ ọ̀fẹ́ n'Ibadan, Abuja àti Anambra

Oríṣun àwòrán, FCT Police Com
Igbakeji aarẹ orilẹede Naijiria, Kashim Shettima ti fọkan awọn araalu balẹ wi pe gbogbo awọn to padanu ẹmi wọn nibi eto pinpin ounjẹ to waye lọsẹ to kọja lawọn yoo ṣe iranwọ fun mọlẹbi wọn, lati fi pa ironu rẹ.
Shettima lo sọrọ yii ninu atẹjade ibanikẹdun to fi sita lanaa lọjọ Aiku, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kejila, ọdun 2024 niluu Abuja.
Igbakeji aarẹ kọminu gidi lori iṣẹlẹ ajalu naa, to si lo ba oun pẹlu ọpọ eeyan, paapaa ijọba Naijiria lọkan jẹ.
Nibẹ lo ti gbadura fun gbogbo mọlẹbi ti wọn padanu awọn eeyan wọn, wi pe ki Ọlọrun tu wọn ninu.
Shettima, nigba to n ṣapejuwe iṣẹlẹ ọhun gẹgẹ bi ajalu apapọ lorileede, jẹ ko di mimọ pe ijọba apapọ ti paṣẹ fun gbogbo awọn ileeṣẹ ijọba tọrọ kan lati dide iranlọwọ fun awọn mọlẹbi to padanu awọn eeyan wọn.
Ninu ọrọ rẹ to kọ sinu atẹjade ibanikẹdun naa, Shettima sọ pe Iṣẹlẹ to mu ẹmi awọn alimọkan lọ yii "ba mi lọkan jẹ gidi"
"Adura mi ati ero ọkan mi lọ si gbogbo awọn mọlẹbi ti ọkan wọn gbọgbẹ, to fi mọ awọn to farapa, ti wọn si n gba itọju lọwọ."
Shettimma tẹsiwaju pe iṣẹlẹ ọhun ko iporuru ọkan ba oun lati rii pe ọpọ ọmọ Naijiria, paapaa awọn ọmọde ti sọnu sibi iṣẹlẹ titẹ ara ẹni pa, eyi to yẹ ki wọn ti dena rẹ, ka ni eto ati ilana daadaa wa nilẹ ni.
O ni pipadanu awọn ẹmi kii ṣe fun ipinlẹ nikan, bi ko ṣe fun gbogbo orileede.
"A ti duro digbi lati dide iranwọ fun gbogbo mọlẹbi lasiko iṣoro yii, a ti pe ko si igbiyanju ti a maa gbe sẹgbẹ kan lati fi pese iranwọ ti wọn ba n ilo.
"Fun awọn ti wọn ṣi n gba itọju lọwọ lawọn ile iwosan kakairi, ipadabọsipo wọn jẹ wa logun, ti a si maa duro ti wọn lasiko ipenija yii," Shettima sọ bẹẹ.














