Lẹ́yìn tí BBC pariwo iléẹ̀kọ́ tí wọ́n ti ń kọ́ akẹ́kọ̀ọ́ lábẹ́ igi, ìjọba Kwara ṣe àtúnṣe

Àkọlé fídíò, Lẹ́yìn tí BBC pariwo iléẹ̀kọ́ tí wọ́n ti ń kọ́ akẹ́kọ̀ọ́ lábẹ́ igi, ìjọba Kwara ṣe àtúnṣe
Lẹ́yìn tí BBC pariwo iléẹ̀kọ́ tí wọ́n ti ń kọ́ akẹ́kọ̀ọ́ lábẹ́ igi, ìjọba Kwara ṣe àtúnṣe

Ni asiko diẹ sẹyin ni ileeṣẹ BBC gbe iroyin kan jade nipa ile ẹkọ kan ti awọn akẹkọọ ti n kọ ẹkọ wọn labẹ igi nitori aisi kilaasi.

ile ẹkọ alakọbẹrẹ LGEA Kankan ni ijọba ibilẹ Asa ni ile ẹkọ ti a n sọrọ rẹ yii.

Aworan aga tuntun fun ile ẹkọ naa

Laipẹ si asiko naa ni ijọba ipinlẹ Kwara gbe igbesẹ lati ṣe atunṣe gbogbo to yẹ fun ile ẹkọ naa.

Kilaasi tuntun ni wọn gbe kalẹ ni ile ẹkọ naa eyi to mu ki awọn obi ati olukọ ni ile ẹkọ naa kan sara siwọn.

O ṣi ku o!

Kilaasi tuntun ti ijọba kọ

Pẹlu bi ijọba ti ṣe ṣe ohun atunṣe wọn yii, awọn araalu naa ko ṣai tun ke si ijọba ki o ba wọn ṣe atunṣe opopona fun awọn akẹkọọ ati olugbe agbegbe naa lati lee maa ko ere oko wọn ati lati maa lọ si awọn ilu to ku.

aworan opopona naa

Bakan naa ni wọn tun rọ ijọba lati kọ ile ẹkọ giga girama fun awọn awọn akẹkọọ to n kẹkọjade ni ile ẹkọ alakọbẹrẹ naa.

Ijọba ẹ jọwọ ẹ ma gbagbe awa naa o!

Aworan awoku kilaasi kan ni ile ẹkọ Sadaadi ni ipinlẹ Kwara

Bi awọn olukọ ile ẹkọ alakọbẹrẹ LGEA Kankan ni ijọba ibilẹ Asa ṣe n dunnu ti wọn si n dupẹ lọwọ ijọba lawọn ti ile ẹkọ Idi Apa Sadaadi pẹlu n ke si ijọba ipinlẹ Kwara pe ki wọn ṣi oju wo awọn naa ki wọn si tun awọn ile ẹkọ wọn ṣe.