Ìpínlẹ̀ Eko, Ondo, Anambra kéde àlàkalẹ̀ lóri pínpín oúnjẹ ọ̀fẹ́ lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ ìtẹra-ẹni-pa tó wáyé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lojuna ati dena irufẹ awọn iṣẹlẹ itẹra-ẹni-pa to waye nibi tawọn eeyan ti fẹ gba ounjẹ ọfẹ niluu Ibadan, Abuja ati Okija nipinlẹ Anambra lọjọ iwaju, awọn alakoso ijọba ipinlẹ ti bẹrẹ si ni oriṣiriṣi igbesẹ, pẹlu alakalẹ ilana fawọn eeyan to ba fẹẹ ṣe iranwọ faraalu.
Awọn ọmọde marundinlogoji lo ba iṣẹlẹ Ibadan lọ, mẹwaa lawọn to ku ni ti Abuja.
Iroyin tun fidi rẹ mulẹ pe eeyanmejilelogun ni wọn padanu ẹmi wọn nibi ti wọn ti fẹ gba ounjẹ ọfẹ niluu Okija nipinlẹ Anambra.
Wonyi ni awọn igbesẹ tawọn ipinlẹ Eko, Ondo ati Anambra ti kede lori alakalẹ fawọn to ba fẹ fi ounjẹ ṣe iranwọ fun araalu.
Ijọba ipinlẹ Eko
Lara awọn alakalẹ ilana tijọba ipinlẹ Eko gbe kalẹ ni pe ẹnikẹni tabi ajọ yoowu to ba fẹẹ gbe eto ti awọn eeyan ti yoo kopa nibẹ yoo le ni 250 gbọdọ lọ fi to awọn ileeṣẹ eleto aabo leti, yala lasiko pọnpọnṣinṣin ọdun yii tabi lẹyin ọdun.
Ijọba sọ pe awọn to ba kọ lati ṣe eyi yoo ri pipọn oju ijọba nipa ijiya ti wọn la kalẹ.
Kọmiṣanna feto akanṣe iṣẹ ati oniduro laarin ijọba si araalu, Gbenga Oyerinde, pẹlu akẹgbẹ rẹ lati ileeṣẹ eto iroyin, Gbenga Omotosho, lo sọ eyi di mimọ fawọn akọroyin lọjọ Aiku to kọja.
"Iṣẹlẹ titẹ-ara-ẹni-pa to ṣẹlẹ nipinlẹ Oyo, Anambra, ati Abuja kọ ijọba ipinlẹ Eko lominu.
Ẹnikẹni, ẹgbẹkẹgbẹ tabi ajọ yoowu to ba n gbero lati pin awọn nnkan fun apẹjọpọ eeyan ni lati gba iwe aṣẹ ijọba, ki wọn si forukọsilẹ lọdọ awọn ileeṣẹ alaabo, "Omotosho ṣalaye.
Ijọba Ipinlẹ Ondo
Adajọ nipinlẹ Ondo, Ọmọwe Olukayode Ajulo, ẹni to tun jẹ Kọmiṣanna feto idajọ nigba to n sọrọ lọjọ Aiku to kọja jẹ ko di mimọ pe ofin tuntun ti wa fun ipejọpọ awọn eeyan rẹpẹtẹ bayii ni ibamu pẹlu ofin, to si wa fawọn to n ṣagbatẹru eto.
Amofin Ajulọ sọ pe awọn gbe ofin naa kalẹ nibamu pẹlu iwe ofin Naijiria ti ọdun 1999 ati iwe ofin ipinlẹ Ondo lọdun 2025, to fi mọ ti iwe ofin ọlọpaa tọdun 2020.
Nigba to n sọrọ, o ni "awọn agbofinro gbọdọ ṣayẹwo ewu fawọn ipẹjọpọ rẹpẹtẹ bii wiwo iye awọn eeyan ti yoo wa nibẹ, ibi ti wọn fẹẹ lọ ati ipenija eto aabo.
"Bakan naa, o pọn dandan fawọn alagbekalẹ eto lati fi to awọn alakoso aabo agbegbe naa leti, lati le ṣe iwadii nipa bi eto naa yoo ṣe lọ, ati asiko ti wọn yoo lo."
Siwaju sii ni adajọ agba naa jẹ ko di mimọ pe ayẹyẹ to ba ti ni akopa to to ọọdunrun gbọdọ ni awọn oṣiṣẹ eleto ilera nitosi, ati pe awọn akopa gbọdọ ni anfaani si omi mimu ati ṣalanga.
O fi kun ọrọ rẹ pe ibi agbekalẹ eto tabi ayẹyuẹ gbọdọ ni ẹnu ọna abawọle to pọ, fun awọn eeyan lati maa rin lai ni idiwọ.
Ipinlẹ Anambra
Gomina Chukwuma Soludo tipinlẹ Anambra, ọkan lara awọn ipinlẹ tiṣẹlẹ ajalu naa ti waye naa sọ tiẹ, o ni lotitọ lo jẹ pe pẹlu ifẹ ọkan lawọn to ṣagbatẹru pinpin ounjẹ fawọn araalu lasiko ọdun fi ṣe e.
Sibẹ, o ni ki awọn to n ṣagbatẹru iru eto bayii rii daju pe wọn n ṣagbekalẹ ilana to pe ye lati fi pin awọn ẹbun naa, lati le dena ajalu titẹ-ara-ẹni pa lọjọ iwaju.
Ninu atẹjade ti akọwe iroyin gomina, Christian Aburime gbe jade lọjọ Aiku to kọja, Soludo ni ibanilọkanjẹ ni iṣẹlẹ naa jẹ fun ipinlẹ Anambra, ati orileede Naijiria lapapọ.
"Eto naa ni wọn ṣe pẹlu ifẹ ọkan lati pin ounjẹ fawọn alaini lasiko pọnpọnṣinṣin ọdun yii. Ṣugbọn ṣa, ijamba to tẹyin rẹ yọ ti wa pe fun agbekalẹ ati ilana pajawiri lati dena irufẹ ijamba naa," Soludo sọ ninu atẹjade ọhun.
"Mo rọ awọn eeyan ati ẹgbẹ ti wọn n ṣagbekalẹ iru eto bayii lati maa mu ọrọ ẹmi awọn eeyan lọkukudun nipa pipe awọn eleto aabo sibi apejọ wọn."
O ni ko pọn dandan ko jẹ pe oju kan ṣoṣo ni wọn yoo ti maa pin ounjẹ naa, ki wọn pese aaye to pọ ti wọn yoo ti maa pin ẹbun naa fawọn eeyan, lati mu adinku ba ero rẹpẹtẹ soju kan.
"Ẹ ṣagbekalẹ ilana ati eto fun awọn to ku diẹ kaato fun, awọn alaabọ ara, awọn arugbo, awọn alaboyun, ati awọn ọmọde; ati paapaa gbigba awọn akọṣẹmọṣẹ ti yoo dari awọn ero.
"Ẹ rii daju pe awọn eeyan to sori ila, ki ẹ si ṣe iranwọ fawọn to nilo rẹ, ẹ ṣe idanilẹkọọ ita gbangba lati ṣabojuto eto aabo lasiko ," Soludo ṣalaye.
Lara awọn ipinlẹ to tun ṣagbekalẹ ilana tuntun fawọn araalu ni ipinlẹ Abia, Akwa Ibom, Kogi, Rivers, Delta, ati awọn miran.
Kii ṣe igba akọkọ ree ti iru ajalu bayii yoo maa waye ni Naijiria - Ijọba apapọ
Ijọba apapọ orileede Naijiria ti sọ pe awọn iṣẹlẹ titẹ ara ẹni pa to ṣẹlẹ lawọn ipinlẹ mẹta lorileede naa ko ni ohunkohun lati ṣe pẹlu atunto ti iṣakoso Aarẹ Bola Tinubu dawọ le.
Mohammed Idris to jẹ minisita feto iroyin ati ilanilọyẹ ni Naijiria lo sọ eyi di mimọ ninu atẹjade ibanikẹdun sawọn mọlẹbi to padanu awọn eeyan wọn, eyi to fi sita lọjọ Aiku to kọja.
Idris ni o jẹ nnkan iyalẹnu lati maa ri bi awọn kan ṣe n so awọn ijamba naa papọ mọ awọn ilana ati agbekalẹ Aarẹ Tinubu lati mu atunto ba Naijiria.
O ni kii ṣe igba akọkọ ree ti iru ajalu bayii yoo maa waye ni Naijiria, to si niru iṣẹlẹ bẹẹ ti ṣẹlẹ kọja ki iṣakoso yii too gbajọba.
"O yẹ ka mọ pe iru iṣẹlẹ to ba ni lọkan jẹ bayii ti ṣẹlẹ sẹyin, ko to di asiko iṣakoso yii, fun idi eyi, lati maa so ajalu naa papọ mọ atunto Aarẹ jẹ eyi ti ko bojumu," Idris sọ ninu atẹjade naa to fi soju opo 'X'.
Bakan naa lo ba awọn mọlẹbi gbogbo awọn to padanu ẹmi wọn ati awọn to farapa kẹdun, to si tun gbadura fun wọn.
Bi ẹ ko ba gbagbe, ilu Ibadan ni itẹra-ẹni-pa naa ti kọkọ waye, nibi ti Olori tẹlẹ fun Ọọni Ile-Ifẹ, Olori Naomi Ogunseyi ti pin ounjẹ ọdun fawọn ọmọde.
Iṣẹlẹ keji ni eyi to waye ninu ijọ Katoliiki kan to wa lagbegbe Maitama niluu Abuja tii ṣe olu ilu Naijiria, ti iṣẹlẹ kẹta si waye lagbegbe Okija to wa nipinlẹ Anambra.
Ọpọ awọn eeyan ni eto pinpin ounjẹ ọfẹ fawọn araalu ti ran lọ sọrun aremabọ, eyi to n kọ gbogbo eeyan lominu pẹlu ibanujẹ ọkan.
Iroyin sọ pe awọn mẹtadinlaadọrin, eyi ti marundinlogoji ninu wọn jẹ ọmọde lo ba iku ojiji pade nibẹ.
"Ero ati adura wa lọ sọdọ awọn tọrọ kan, awọn mọlẹbi wọn, ati gbogbo awọn to fara kaaṣa ninu ijamba naa," Idris tẹsiwaju.
Idris sọ pe ajalu naa ti jẹ ko di mimọ pe awọn eeyan ni lati maa tẹle ilana lati ṣe oore faraalu, paapaa lawọn asiko ayẹyẹ ọdun bi eyi to wa nita bayii.
O fi kun ọrọ rẹ pe ajọṣepọ ati ifọwọsowọpọ ti wa pẹlu ajọ NEMA ati ileeṣẹ ọlọpaa lati rii daju pe dena iru awọn iṣẹlẹ bayii lọjọ iwaju.















