Ìjì líle Cyclone Chido kọlu Mozambique, èèyàn 94 pàdánù ẹ̀mí wọn

Oríṣun àwòrán, Reuters
Iji lile Cyclone Chido ti ṣekupa ọrinlelaadọrun eeyan lorilẹede Mozambique.
Ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajwiri nilẹ naa, National Institute of Risk and Disaster Management (INGD) sọ pe eeyan 768 lo farapa nigba ti 622,000 di alairilegbe.
Ọjọ karundinlogun, oṣu Kejila ti a wa yii ni iji lile naa kọlu orilẹede naa to si n sare ni iwọn kilomita 260 laarin wakati kan fun wakati mẹrinlelogun akọkọ.
Irufẹ iji lile ọhun ti kọkọ ṣọṣẹ nilẹ Mayote, ko to lọ kulu awọn eeyan Mozambique, Malawi ati Zimbabwe.
Ni Mozambique, iji lile ọhun kọlu iha ila oorun nibi ti irufẹ iṣẹlẹ bẹẹ ti maa n waye tẹlẹ.
Agbegbe Cabo Delgado ni iji naa kọkọ kọlu, ko to lọ ṣoṣẹ ni Niassa ati Nampula.
Ajọ INGD sọ pe iṣẹlẹ naa ti ṣakoba fun eto ẹkọ ati eto ilera orilẹede ọhun.
O le ni ẹgbẹrun lọna ọgọrun un ọmọ ile ẹkọ ti iṣẹlẹ naa ṣakoba fun latari bi ọpọ ile ẹkọ ṣe dawo.
Adari ẹgbẹ oṣelu to n ṣe ijọba lọwọ nibẹ, Daniel Chapo sọ fun awọn akọroyin pe awọn ti bẹrẹ si n ṣe iranwọ to yẹ fun awọn ti ọrọ naa kan.
Chapo ni ijọba ti n ṣiṣẹ pẹlu ajọ INGD lati tun awọn agbegbe bii Mecúfi, Nampula, Memba ati Niassa kọ.
Lagbege Chido nikan, eeyan marundinlogoji lo jade laye.
Wayi o, nnkan bii ọlọpaa 1,300 ni ijọba ti da si igboro lati ṣiṣẹ pẹlu awọn adoola ẹmi.















