Àwọn òṣìṣẹ́fẹ̀yìntì fẹ̀hónúhàn l'Osun, wọ́n ní ₦9,000 péré ni ìjọba ń fún àwọn

Awọ oṣiṣẹ to fẹyinti lọdun 2011 ati 2012 nipinlẹ Osun ti ke si gomina Ademola Adeleke ko fikun owo oṣu wọn.
Yemi Lawal to jẹ adari fun awọn osisẹfẹyinti ọdun 2011 ati 2012 ọhun to ba akọroyin BBC Yoruba sọrọ ni o ti pẹ ti ijọba ipinlẹ ọsun n ti fi iya jẹ awọn lori bi ko ṣe san owo ifẹyinti awọn lati aye ìjọba Rauf Aregbesola.
Ọgbẹni Lawal tun tesiwaju pe owo oṣisẹ to kere ju nigba naa ti n se ẹgbẹ̀rún mẹsan an naira ti ijọba n san lo ṣi n san titi di oni yii.
O ni awọn gbe ọrọ naa lọ sile ẹjọ, ile ẹjọ si da awọn lare wi pe ki ijọba ko dẹkun fifi owo osisẹ to kere ju lakoko naa san owo fun awọn.
Sugbọn kaka ki ewe agbọn ko dẹ, wọn ni ṣe lo tun le koko si fun gbogbo osisẹfẹyinti ọdun 2011 ati 2012 nipinlẹ Ọsun.
Wale Akinwale to ṣoju oṣisẹfẹyinti ijọba Ìbílẹ̀ Ariwa Ife nipinlẹ Osun naa ṣalaye idi ti wọn fi jade.
Akinwale ni awọn bẹ ijọba Gomina Ademola Adeleke ko tun ipinnu rẹ ṣe lori awọn oṣisẹ fẹyinti ọdun naa lati fi ẹgbẹrun mejidinlogun 18,000 san owo ifẹyinti awọn.

Akinwale tun fi kun ọrọ rẹ pe, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ninu wọn lo ti di alaisan latari owo ifẹyinti ti ko lọ deede, bẹẹ ni ọpọ ti ku nipasẹ pe ko si owo ti wọn yoo fi tọju ara wọn.
O wa rọ Gomina Ademola Adeleke ko tete wa nnkan ṣe si ọrọ naa ni kiakia.
John Olusegun to jẹ ọkan lara awọn osisẹfẹyinti naa tun sọrọ lori bi ijọba ṣe n fi iya jẹ awọn.
O ni "Awa ko lagbara lati le ba ijọba ja sugbọn ki Ọlóọrun ṣe idajọ laarin ijọba ati oṣisẹfẹyinti ipinlẹ Osun paapaa julọ awa oṣisẹ fẹyinti ọdun 2011 ati 2012.
John Olusegun tun tesiwaju ninu ọrọ rẹ pe, ọdun marun-un ni oun fi wa lori aisan latari pe ìjọba kọ lati san owo ifẹyinti to jẹ awọn.
Gbogbo akitiyan wa lati gbọ ọrọ lati ẹnu ìjọba ipinlẹ Osun lasiko ti a n ko iroyin yii jọ lo ja si pabo.















