Wo ìgbà márùn-ún táwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò pàdé ikú lọ́wọ́ aráàlú ní Naijiria

Oríṣun àwòrán, Getty image
Ta a ba yọwọ iku latọdọ awọn ikọ onijagidijagan bii Boko Haram, awọn ti wọn n beere orilẹ-ede Baifra atawọn adigunjale, iku miran to tun maa n ba awọn ẹṣọ alaabo ninu jẹ ju ni Naijiria ni eyi to ba tọwọ awọn araalu ilu wa.
Awọn asiko kan maa n wa ti awọn ẹṣọ yoo lọ lati pẹtu saawọ, ṣugbọn awọn eeyan ibẹ yoo pa wọn.
Nigba mi-in paapaa, eyi maa n di wahala gidi bawọn ẹṣọ naa, yala ọlọpaa tabi ologun ba fẹẹ gbẹsan.
B’awọn ẹṣọ ba binu bayii, wọn yoo maa ja lai mọ ààlà ni, gbogbo ilu ni yoo jiya ipaniyan naa.
Ni bayii, awọn ṣọja Naijiria n ṣọfọ ologun mẹtadinlogun tawọn kan pa ni Delta lọjọ kẹrinla oṣu kẹta 2024. Ṣugbọn ipaniyan yii kọ lakọọkọ.
Ẹlẹẹkarun rẹ leyi lati 1999 ta a ti n ṣẹjọba awarawa.
Eyi ni igba marun-un ti araalu ti pa ẹṣọ alaabo ni Naijiria ati awọn agbegbe naa
Odi, nipinlẹ Bayelsa
Loṣu kọkanla ọdun 1999, awọn ọdọ kan nitosi ilu Odi, nijọba ibilẹ Kolokuma/ Opokuma, nipinlẹ Bayelsa, pa ṣọja ati ọlọpaa mejila to lọọ pẹtu saawọ wọn.
Nigba tawọn ẹṣọ naa yoo gbẹsan, wọn jo gbogbo abule kanlẹ lai ku nnkan kan.
Akọsilẹ sọ pe eeyan to to ẹẹdẹgbẹrun (900) ni wọn pa.
Alakyo, nipinlẹ Nassarawa
Ni 2013, ko din ni ọlọpaa marundinlọgọta (55) ati awọn ẹṣọ alaabo mẹwaa mi-in ti wọn ku l’Abule Alakyo, nipinlẹ Nasarawa.
Baba kan tawọn eeyan fura si pe oṣó ni, (Baba Alaky ni wọn n pe e), ni awọn ọmọ ẹyin rẹ kọlu awọn agbofinro to fẹẹ da wọn lọwọ kọ lori iṣẹ ti wọn n fi oṣo naa ṣe.
Wọn ni iṣẹ ibi to n ba aye araalu jẹ ni wọn n fi agbara okunkun wọn ṣe.
Awọn ọmọ ẹyin Baba Alaky dena de awọn awọn ẹṣọ tijọba ran wa lati Abuja.
Wọn gba awọn nnkan ija wọn, wọn pa wọn, wọn si tun dana sun oku wọn.
Dura-Du, nipinlẹ Plateau
Mọkanla ninu awọn ọdọ abule Dura Du, nijọba ibilẹ Guusu Jos, ipinlẹ Plateau, padanu ẹmi wọn lasiko ti awọn pẹlu ṣọja ni gbolohun asọ ni 2018.
Lẹyin iṣẹlẹ naa ni Ọgagun Idris Alkali n rin irin ajo lati Abuja si Bauchi.
Ori irin ajo naa lo ti di awati, wọn ko ri i mọ pẹlu mọto rẹ to n gbe lọ si Bauchi.
Inu odò kan ni wọn ti pada ri oku ọga ṣọja yii, awọn ologun si sọ pe awọn ọdọ Dura Du lo pa a.
Zaki-Biam, nipinlẹ Benue
Ẹṣọ ologun mọkandinlogun (19) ni awọn ọdọ ilu Zaki-Biam, nipinlẹ Benue, pa loṣu kẹwaa ọdun 2021.
Awọn Tiv ati Jukun ni wọn n ja, ijọba si ran awọn ṣọja lọ sibẹ lati pẹtu si i.
Ṣugbọn iku awọn ṣọja yii lo pade ṣẹlẹ.
Awọn ṣọja ya bo wọn lẹyin ikọlu naa. A gbọ pe wọn pa ju ọgọrun-un kan eeyan lọ, wọn si tun dana sun ilu naa.
Ṣugbọn awọn ologun sọ pe irọ ni.
Okuama, nipinlẹ Delta
Iku awọn ṣọja ni Okuama leyi to gbode lọwọ yii lorilẹ-ede Naijiria.
Ipinlẹ Delta lo ti waye, ṣọja mẹtadinlogun lo ba a lọ lọjọ kẹrinla, oṣu kẹta 2024.
Iroyin sọ pe iku ẹlẹya lawọn ọdọ yii fi pa awọn ologun naa, wọn ni wọn yọ ọkan wọn lẹyin ti wọn pa wọn tan.
Awọn eeyan Okuama ti sa kuro ni gbogbo agbegbe naa, nitori ibẹru ohun tawọn ologun yoo fi wọn ṣe bi wọn ba mu wọn.

Oríṣun àwòrán, Nigerian Army
Ki lohun to n fa ikọlu yii?
*Bi ko ba si ajọṣepọ to dan-mọ-ọn-ran laarin awọn alaabo atawọn ti wọn n ṣọ, o ṣẹe ṣe ki ikọlu waye.
*Bi apa kan ninu awọn ti wọn n da aabo bo ba lero pe ṣọja n gbe sẹyin igun keji, wahala le ṣẹlẹ.
*Nigba mi-in, bawọn ologun ba kọ lati fun igun kan ni atilẹyin, wọn le maa ri wọn bii ọta ti wọn gbọdọ kọlu.
* Bi araalu ba kọlu ẹṣọ alaabo, o tumọ si pe awọn naa ni nnkan ija lọwọ niyẹn.
Bi araalu ba ni nnkan ija lọwọ, o maa n jẹ ki wọn rira wọn bi ologun ni.

Oríṣun àwòrán, Getty image
Ọna abayọ
*Malam Kabiru Adamu ṣalaye pe pipa awọn ẹṣọ to n ṣọ orilẹ-ede wa gbọdọ dopin.
*Ẹnikẹni tọwọ ba tẹ pe o pa ẹṣọ alaabo gbọdọ gba idajọ, ko le jẹ ẹkọ fawọn eeyan yooku.
*Ọpọlọpọ ẹṣọ alaabo ni Naijiria ti padanu laarin ogun ọdun si asiko yii, latari awọn ija s ni.
*Ijọba gbọdọ pese irinṣẹ ati nnkan ija gidi fawọn ẹṣọ alaabo.
*Eto aabo lorilẹ-ede yii gbọdọ rinlẹ si i.
*Awọn ẹṣọ ti gbọdọ maa loye ibi ti wọn ti fẹẹ lọọ pẹtu saawọ ki wọn too debẹ.
*Araalu gbọdọ fẹran awọn ẹṣọ alaabo ilu, ki wọn le mọ bi wọn ṣe pataki to .
Iroyin sọ pe o ti le ni ẹgbẹrun meji (2,000) ologun ti Naijiria ti padanu laarin ọdun mẹwaa si asiko yii.
Bakan naa ni iwadii kan ni 2021 sọ pe ẹṣọ alaabo to wa ni Naijiria ko ju ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta (500,000) lọ.
Wọn ni eyi kere pupọ forilẹ-ede to jẹ awọn eeyan ibẹ le ni miliọnu meji.














