Ohun mẹ́wàá tó yẹ kí o mọ̀ nípa òfin owóyàá akẹ́kọ̀ọ́ tíjọba ṣẹ̀ṣẹ̀ buwọ́lù

Awọn Akẹkọọ

Oríṣun àwòrán, UI

Ọjọru, ọjọ kẹta oṣu kẹrin ọdun 2024 ti ijọba Aarẹ Bọla Tinubu, buwọ lu ofin ẹyawo awọn akẹkọọ kaakiri ileewe giga lorilẹ-ede yii.

Ninu oṣu kẹfa ọdun 2023 ni Aarẹ se ibuwọlu naa, ṣugbọn nitori awọn kudiẹ-kudiẹ kan, ofin naa ko ṣee lo.

Wọn da a pada fawọn aṣofin.

Ni bayii ti Aarẹ Bọla Tinubu ti waa buwọ lu u, o tọ lati mọ awọn nnkan to rọ mọ anfaani ẹyawo naa.

Aare Bọla Tinubu

Oríṣun àwòrán, Presidency

Àwọn kókó mẹ́wàá náà rèé

  • Agbekalẹ owo kan ti a Akẹ́kọ̀ọ́ tó bá gba ‘student loan’ láì sán padà lè fi ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́ta jura – Ìjọba apapọ̀ ya sọto lati maa ya awọn akẹkọọ to tọ si yoo wa.
  • Awọn akẹkọọ le yawo yii lati sanwo ileewe eyikeyi, wọn si le fi gbọ bukaata mi-in to ba jẹ mọ ẹkọ wọn. Wọn le fi sanwo ẹkọṣẹ iṣẹ ọwọ to ba wu wọn.
  • Iye owo ti akẹkọọ le ya ko pin sibi iye tawọn obi rẹ n gba, gẹgẹ bo ṣe wa ninu ofin ti tẹlẹ fun 2023 pe awọn akuṣẹẹ ọmọ nikan lo wa fun.
  • Ko nilo ki akẹkọọ lọọ mu oniduuro to jẹ akẹkọọ bii tiẹ wa ninu ofin yii ko too le yawo.
  • Tẹlẹ lo jẹ wọn gbọdọ mu eeyan meji wa, eyi ti oṣiṣẹ ijọba to wa ni akasọ kejila tabi ju bẹẹ lọ gbọdọ wa ninu wọn.
  • Wọn yoo si tun mu lọọya to ti ṣiṣẹ amofin fọdun mẹwaa wa, labẹ ofin ti tẹlẹ. Eyi ko ri bẹẹ mọ bayii.
  • Owo ti wọn jẹ obi akẹkọọ ko ni nnkan kan lati ṣe pẹlu owo tijọba yoo ya a lati kawe.
  • Lẹyin ọdun meji ti akẹkọọ ti pari agunbanirọ ni yoo too da owo to ba ya pada.
  • Akẹkọọ to fẹẹ yawo lanfaani lati ṣalaye pe oun ko lowo toun yoo fi san gbese naa pada, nitori oun ko ti i maa ṣiṣẹ.
  • Iwe ibura kootu ni yoo mu wa lati fidi eyi mulẹ.
  • Ofin yii faaye silẹ, pe ẹni to ba purọ, fi alumọkọrọyi gbowo yii yoo ṣẹwọn ọdun mẹta.
  • Bi a ba ri akẹkọọ to doloogbe ki asiko ati sanwo to ya pada too pe, a ko ni i gba gbese naa lọwọ awọn eeyan rẹ.
  • Abi ti a ba ri awọn mi-in ti ẹri foju han pe alaini paraku ni wọn, wọn ko le dawo naa pada. Ofin yii yọnda ẹ fun iru wọn lati ma ṣe sanwo naa pada mọ.

Kí ló ti ṣẹlẹ̀ ṣíwájú

Akẹ́kọ̀ọ́ tó bá gba ‘student loan’ láì sán padà lè fi ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́ta jura – Ìjọba apapọ̀

Nigerian Senate

Oríṣun àwòrán, Nigerian Senate

Ijọba apapọ ti buwọlu ofin ti yoo fun awọn akẹkọọ lanfani lati ya owo kawe ni Naijiria.

Ọsẹ to kọja lo ki eto naa gberasọ amọ ijọba sun siwaju lati le ṣe awọn atunṣẹ kan si eto ẹyawo ọhun.

Niju abadofin eto ẹyawo naa ni oniruru awọn ilana bi awọn akẹkọọ ti ko rọwọ họri ṣe le ya owo ọhun wa, ati ijiya to wa fun ẹni to ba tapa si ofin to rọ mọ owo naa.

Lara awọ ilana to wa ninu ẹyawo naa ni bi awọn akẹkọọ yoo ṣe san owo ọhun pada fun ijọba.

Ofin naa sọ pe awọn akẹkọọ gbọdọ maa san owo naa pada ni kete ti wọn ba ti bẹrẹ iṣe lẹyin ẹkọ wọn.

Yatọ si iṣẹ, ijọba ko ni bẹrẹ si gba owo naa pada ayafi lẹyin ọdun meji ti akẹkọọ to ya owo ọhun ba pari agunbainrọ rẹ tan.

Akẹkọọ to ba ṣoro fun lati san owo ọhun to si nilo akoko diẹ si ni lati lọ bura nile ẹjọ pe oun ko tii ri iṣẹ kankan, oun ko si lagbara lati maa san owo naa pada, nitori naa ki ijọba fun oun laaye diẹ si.

O fi kun pe ẹnikẹni to ba pa irọ labẹ ibura naa yoo jẹbi iditẹ, yoo si fi ẹwọn ọdun mẹta jura.

Ki ni yoo ṣẹlẹ ti ẹni to ya owo lọwọ ijọba lati kawe ba jade laye?

Ofin naa ni ijọba yoo fi ori owo naa jin oku ọrun.

Ilé aṣòfin l'Abuja fọ̀ntẹ̀ lu àbádòfin ẹ̀yáwó fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ ọmọ Nàìjíríà nílé ẹ̀kọ́ gíga

Aworan Godswill Akpabio

Oríṣun àwòrán, The Senate President/X

Ile aṣofin agba l’Abuja ti buwọlu abadofin fawọn akẹkọọ ile ẹkọ giga ti ko ri ọwọ họri.

Abadofin yii yoo fawọn akẹkọọ ọmọbibi Naijiria lanfani lati kẹkọọ gboye nile ẹkọ giga ni Naijiria.

Ti e o ba gbagbe, ninu oṣu kẹfa ọdun 2023 ni Aarẹ Bola Tinubu ṣe ifilọlẹ ẹyawo fawọn akẹkọọ ile ẹkọ girama lai ni san ele kankan.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Lọsẹ to kọja ni Aarẹ Tinubu fi aba naa ranṣẹ si ile aṣofin fun ayẹwo ati atunṣe ati lati buwọlu u.

Bayii ni awọn aṣofin ṣe agbeyẹwo aba yii ti wọn fi buwọlu u lonii Ọjọru ogunjọ oṣu Kẹta ọdun 2024 yii.

Abadofin yii tun ṣe agbekalẹ bi awọn akẹkọọ to ba gba owo yii yoo ṣe da a pada lẹyin ti wọn kẹkọọ gboye tan.

Awọn aṣofin wo abadofin naa finifini, wọn si ṣe agbeyẹwo gbogbo imọran tawọn sẹnẹtọ atawọn aṣoju-ṣofin mu wa lori aba naa.

Igbimọ ile aṣofin agba ati aṣoju-ṣofin jọ jiroro papọ lori aba naa, wọn si fẹnu ko lori rẹ.

Iroyin kan tiẹ fidi rẹ mulẹ pe ijọba apapọ ti ya owo to to igba biliọnu naira sọtọ fun eto yii.

Ara awọn atunṣe tawọn ṣe lori eto naa ni yiyọ ohun to wa nibẹ tẹlẹ ni pe obi awọn akẹkọọ to ba fẹ gba owo naa gbọdọ ni to iye kan ninu akaunti wọn.

Awọn aṣofin fẹnu ko wi pe eyi maa di yiyọ kuro nibẹ.

Awọn aṣofin tun yọ ohun to wa nibẹ tẹlẹ pe akẹkọọ to ba fẹ gba owo yii gbọdọ ni oniduro.

Bakan naa, akẹkọọ to ba fẹ gba owo yii le ri gba lai nan ni bo ya obi rẹ ti jẹ owo ri tẹlẹ.