Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́sàn-án lákàtà àwọn ajínigbé, òyìnbó China gbòmìnira ní Kwara

Aworan Kọmiṣọna ọlọpaa Kwara

Oríṣun àwòrán, Kwara State Police command

Oyinbo China kan, ti orukọ n jẹ PengChao Zang ti awọn agbebọn jigbe ni ipinlẹ Kwara ti gba ominira lẹyin ọjọ mesan-an ti ti wa ni akata awọn ajinigbe.

Wọn ni ẹni ti yoo royin ogun ko ni ku sogun, ọrọ yii gan-an lo ṣẹ mọ Zang ti wọn jigbe ni ile itura kan lagbegbe Ẹyẹnkọrin lara.

Zang yii naa ni awọn alabasisẹ rẹ n pe ni Williams Kaka.

Lọjọ kẹwaa, oṣu kẹta, ọdun 2024 yii ni a gbọ wipe wọn ji oyinbo naa gbe lọ, to si wa lakata awọn ajinigbe fun ọjọ mẹsan-an gbako.

Laaarọ kutu ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹta yii ni ọkunrin naa gbominira lọwọ awọn ti wọn ji i gbe.

Alukoro Ileeṣẹ Ọlọpaa ni Kwara, DSP Ejirẹ Adetoun Adeyẹmi, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, lonii Ọjọruu, ogunjọ, oṣu Kẹta yii.

O ni pẹlu akitiyan awọn ẹsọ alaabo ọlọpaa ati Fijilante, awọn ti doola ẹmi Zang, to si ti darapọ mọ ẹbi rẹ layọ ati alaafia.

O tẹsiwaju pe lọjọ kẹwaa, oṣu Kẹta yii, ni awọn agbebọn mẹfa kan ya wọ otẹẹli kan ti wọn n pe ni "Cherish Guest House", lagbegbe Ẹyẹnkọrin, nibi ti oyinbo China yii wa ti wọn si ji i gbe lọ.

O salaye pe, nigba ti awọn ọlọpaa ati Fijilante n wa wọn kiri ni wọn kan wọn ninu igbo, ti wọn si doola ọkunrin ọhun lai farapa.

O fi kun un pe aseyọri naa waye latari isẹ ọpọlọ, iwadii to yanranti ati ifaraẹniji ti awọn ikọ alaabo naa se.

Kọmiṣọna Ọlọpaa ni Kwara, CP Victor Ọlaiya, ti wa ni gbogbo awọn to huwa ibajẹ naa ko ni lọ lai jiya.

Bakan naa lo rọ gbogbo olugbe ipinlẹ Kwara, ki wọn maa wa ni oju ni alakan fi n ṣọri, pe ti wọn ba sakiyesi iwa aitọ lagbegbe wọn ki wọn fi to awọn ẹsọ alaabo leti.