Dúkìá tó lé ní ₦360m ṣòfò bí ọjà Owódé ní ìlú Offa ṣe jóná

Oríṣun àwòrán, Kwara State Fire Service
Ariwo ge ni ọja Owode ilu Offa ni ọjọ Iṣẹgun, ọjọ Keji, oṣu Kẹrin ọdun 2024 bi ijamba ina ṣe bẹ silẹ ninu ọjọ naa.
Dukia to le ni ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu Naira lo ṣegbe sinu ijamba ina naa ti awọn ọlọja si n poruru ọkan lori adanu nla yii.
Igba akọkọ kọ niyi ti ijamba ina yoo waye ninu ọja yii to si tun waye ni afọmọju ọjọ Iṣẹgun.
Nigba ti awọn ọlọja n dẹ ṣọọbu ni aarọ ọjọ Iṣẹgun ni wọn n ba ọja wọn to ti n jona, eyi ti awọn kan n sọ pe lati bii aago meji abọ oru ni ijamba ina ọhun bẹrẹ.
Ọkan ninu awọn ọlọja to padanu dukia rẹ nibi ijamba ina naa sọ pe o ṣeeṣe ko jẹ pe ina ẹlẹtiriiki lo ṣokunfa ijamba ina to fi ọpọlọpọ dukia ṣofo yii.

Oríṣun àwòrán, Kwara State Fire Service
"Dukia to to biliọnu mejila ni ileeṣẹ panapana doola lọwọ ina"
Nigba to n fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, Alukoro ileeṣẹ panapana ipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Hassan Hakeem Adekunle, sọ pe bi awọn oṣiṣẹ awọn ṣe tete de sibi iṣẹlẹ naa, ni ko jẹ ki ijamba ina ọhun pọ kọja ibi to de duro ti awọn fi pa a.
O ni ṣọọbu to le ni aadọta (50) lo jona nigba ti dukia to to bii irinwo miliọnu ṣegbe sinu ijamba ina naa.
O tẹsiwaju pe dukia to to biliọnu mejila ni ileeṣẹ panapana doola lọwọ ina.
Ọga agba ileeṣẹ panapana Kwara, Ọmọọba Falade John, wa gba gbogbo olugbe ipinlẹ Kwara niyanju lati maa pa gbogbo ina ile ati ti ibi iṣẹ daadaa ni kete ti wọn ba lo awọn ina ọhun tan.
O ni eyi ṣe pataki lati maa dena iṣẹlẹ ijamba ina, paapaa lasiko ẹẹrun ta a wa yii, ti iṣẹlẹ ina saba maa n waye julọ.















