Iná tó ṣẹ́yọ nílé ijó gbẹ̀mí èèyàn 29, ẹnìkan farapa

Istanbul nightclub fire

Oríṣun àwòrán, getty images

O kere tan, eeyan mọkandinlọgbọn lo ti jade laye, ti ẹnikan si farapa lẹyin ina to ṣẹyọ nile ijo kan ni Turkey.

Ile ijo naa, ti wọn n pe ni ‘Masquerade club’ lo wa labẹ ile alaja pupọ kan ti n ṣatunṣẹ rẹ lọwọ ṣaaju iṣẹlẹ ọhun.

Gomina ilu Istanbul, Davut Gül sọ pe awọn tii ko mọ ohun to fa ṣababi ina naa lẹyin to dede ṣẹyọ lẹyin aago mejila ọsan.

Gül sọ pe awọn ti iṣẹlẹ naa kan lo jẹ awọn oṣiṣẹ to n ṣiṣẹ atunṣe ile naa.

Wayi o, ijọba ilẹ naa ti fi ṣikun ofin mu ọpọ awọn ti wọn fura si pe aibikita wọn lo ṣokunfa iṣẹlẹ ina ọhun.

Lara awọn to ti wa lahamọ ọlọpaa ni oludari ile ijo naa ati adari awọn to n ṣatunsẹ ile ọhun.

Ṣaaju ni awọn oṣiṣẹ panpana ti kọkọ ya bo ile alaja mẹrindinlogun naa nigba ti ina ọhun ṣẹyọ.

Adari ilu Istanbul, Ekrem Imamoglu sọ pe awọn alaṣẹ ile ijo naa ko gba aṣẹ ijọba lati ṣe atunsẹ si i.

Lẹyin naa lo sọ loju pop X rẹ pe pe oun ba mọlẹbi awọn ti iṣẹlẹ naa mu ẹmi wọn lọ, to fi mọ awọn to farapa kẹdun.

O fi kun pe Aarẹ Recep Tayyip Erdogan ti gbọ nipa iṣẹlẹ ọhun o si n bojutọ bi iwadii ṣe n lọ lọwọ lori rẹ.