Ìjọba Amẹ́ríkà yarí fáwọn akọ̀ròyìn tó ń jí nǹkan nínú bàálù ààrẹ

Baalu aarẹ Amẹrika

Wọn ti kilọ fawọn akọroyin lati jawo ninu jiji awọn nkan to wa ninu baalu Aarẹ America, Joe Biden.

Nigba ti wọn ka awọn nkan to yẹ ki o wa ninu baalu naa lẹyin abẹwo aarẹ si apa ila oorun ilẹ naa ni oṣu Keji ọdun yi, ni wọn ri pe pupọ awọn nkan to wa ni aaye awọn akọroyin lo ti poora.

Awọn nkan bi aṣọ ọrun irọri, ife imumi ati awo tanganran oni goolu leti, wa lara awọn nkan ti wọn fura si pe o di awati ninu baalu naa.

Ẹgbẹ awọn akọroyin to n tẹle aarẹ kaakiri ti kilọ pe eewọ ni lati maa mu awọn nkan wọnyii.

Loṣu to kọja, ẹgbẹ naa kọ iwe imeeli sawọn akọroyin pe iru iwa bayi a maa tabuku awọn akroyin to n tẹle aarẹ kaakiri ati pe iru iwa bayi gbọdọ wa sopin.

Loore koore, wọn a maa fun awọn akọroyin ni awọn nkan ẹbun amurele bi ṣokoleeti ti wọn fi ami idanimọ aarẹ si lara.

Amọ iwa ki awọn eeyan maa mu nkan ninu baalu aarẹ lalae gba iyọnda ko ṣeṣẹ maa waye gẹgẹ biiroyin kan ṣe wi.

Ko ṣẹṣẹ maa waye, n ko ṣe nkankan ti ko bojumu pẹlu bi mo ṣe ko awọn nkan pẹ pẹ pẹ yii jọ - Akọ̀ròyìn

Misha Komadovsky, to jẹ́ akọ̀royin fun ileeṣẹ iroyin Voice of America, ti ṣe akojọpọ awọn nkan pẹpẹpẹ lati inu baalu aarẹ lẹyin bi ọdun meloo kan to n ba aarẹ ṣiṣẹ.

"Mi o ṣe nkankan ti ko bojumu pẹlu bi mo ṣe ko awọn nkan pẹ pẹ pẹ yii jọ’’

Alaye ree to ṣe fun ileeṣẹ iroyin BBC, bo ti ṣe mu ikeemu kan lọwọ ti o ni ami idanimọ aarẹ lara.

O ni ‘’mo gbagbe lati sọ ikeemu yi nu lẹyin ti mo lo tan’’

Lara awọn nkan to tun wa ni ọwọ Ọgbẹni Komadovsky ni paali suuti sokoleeti M&Ms ti aarẹ buwọlu.

Aworan ṣọkọleeti ti wọn n pin fawọn akọroyin ninu baalu aarẹ

Bawo ni baalu naa se ri?

Baalu Air Force One yi ti ileeṣẹ aarẹ juwe gẹgẹ bi ọfisi aarẹ lori ofurufu tobi to iwọn ẹsẹ bata ẹgbẹrun mẹrin to si ni aaye onipele mẹta.

Lara awọn nkan aramọnda ti wọn ṣe leto sinu baalu naa ni aaye aarẹ, aaye itọju fawọn oṣiṣẹ ilera, aaye ipade ati aaye ijoko jẹun.

Wọn tun fi aaye ipeelo ounjẹ to le bọ eeyan ọgọrun kan lẹẹkan naa ati aaye ọtọ ti wọn la kalẹ fawọn akọroyin,alejo pataki,ẹṣọ alaabo ati awọn oṣiṣẹ aarẹ.

Pẹlu gbogbo awọn irinṣẹ to so mọ baalu yi, wọn a maa ṣapejuwe rẹ gẹgẹ bi baalu ologun to le farada ikọlu to ba koju rẹ loju ofurufu.

Bakan naa ni baalu yi kapa lati gba epo sara loju ofurufu eyi to mu ki o le fo fun aimọye wakati, paapa ti iṣẹlẹ pajawiri ba waye.

Baalu naa tun ni ẹrọ ibaraẹnisọrọ to fi mọ ẹrọ foonu marundinlaadọrin ati ẹrọ kọmputa loriṣiriṣi.

Iwaju baalu naa ni aarẹ a maa joko si, ti aaye ijoko awọn akọroyin si wa lapa ẹyin ninu baalu yi.