Wọ́n ti búrawọlé fún Bassirou Faye, Ààrẹ Senegal tí ọjọ́ orí rẹ̀ kéré jùlọ

Diomaye Faye

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Wọn ti burawọle fun Aarẹ Senegal tuntun, Bassirou Diomaye Faye lẹyin to jawe olubori ninu eto idibo gbogbogbo to waye lorilẹede naa.

Ẹni ọdun mẹrinlelogoji ni Bassirou Diomaye Faye, eyii to mu ko jẹ Aarẹ ti ọjọ ori rẹ kere julọ ninu itan orilẹede naa.

Faye wa lara awọn oloṣelu inu ẹgbẹ alatako ti wọn tu silẹ lọgba ẹwọn lọjọ mẹwaa ṣaaju eto idibo naa.

Ọjọ Ẹti to kọja ni ajọ to n ri si eto idibo ilẹ naa kede pe Faye lo leke tente gbogbo awọn to n du ipo Aarẹ ọhun.

Ọpọ awọn olori orilẹede ni Afrika lo peju sibi ayẹyẹ iburaọle naa ninu eyii ti ọkan lara wọn jẹ Aarẹ Naijiria, Bola Ahmed Tinubu, to jẹ alaga ajọ Ecowas.

Inu ọgba ẹwọn ni wọn ti ṣe ipologno ibo fun Aarẹ tuntun ọhun.

Ọkunrin naa, to jẹ oṣiṣẹ owo ori tẹlẹ ni yoo jẹ Aarẹ karun un ti Senegal yoo ni lati igba to ti gba ominira lọwọ orilẹede France lọdun 1960.

Faye tun ni Aarẹ akọkọ ti yoo sọ ni gbangba pe oun kii ṣe oniyawo kan.

Akọwe ijọba Amẹrika, Antony Blinken ti pe Faye lori aago lati kii ku oriire lọna ati ṣafihan ibaṣepọ to gun rege to wa laarin orilẹede mejeji.

Lara awọn afojusun Faye ni lati fa awọn orilẹede ti ologun ti gbajọba ni Afrika bii Burkina Faso, Mali ati Niger pada sinu ajọ Ecowas.