Wo àwọn àwòrán mọ́ṣálááṣí àwòdamiẹnu tó tóbi jùlọ ní Africa tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣí ní Algeria

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Aarẹ orilẹede Algeria, Abdelmadjid Tebboune lo ṣi mọṣalaaṣi to tobi julọ nilẹ Africa ọhun laipẹ yii niluu Algiers ti i ṣe olu ilu orilẹede naa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Mọṣalaaṣi yii lo tobi ṣ'ikẹta lagbaaye lẹyin mọṣalaaṣi to wa ni Mecca ati Medina.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Olujọsin ẹgbẹrun lọna ọgọfa lo le jọsin lẹẹkan naa ninu mọṣalaaṣi ọhun eyi ti wọn pe orukọ ni 'The Great Mosque of Algiers.'

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọdun meje ni wọn fi kọ mọṣalaaṣi yii eyi ti wọn lo bii ẹgbẹrin miliọnu owo dọla lati kọ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Aarẹ ana orilẹede Algeria, Abdelaziz Bouteflika, lo kọ mọṣalaaṣi yii.
Bouteflika kuro lori oye lọdun 2019 lẹyin ti erongba rẹ lati dije fun ipo aarẹ fun saa karun-un fori ṣanpọn nigba tawọn araalu bẹrẹ ifẹhonuhan.











