Bobrisky gúnlẹ̀ sílé ẹjọ́ gíga Eko láti kojú ìgbẹ́jọ́ tí EFCC fi kàn-án

Iwaju ile ẹjọ

Oríṣun àwòrán, LEADERSHIP

Idris Okuneye, gbajúmọ̀ akọ tó máa ń ṣe abo tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Bobrisky ti balẹ̀ sí ilé ẹjọ́ gíga ìpínlẹ̀ Eko tó wà ní agbègbè Ikoyi.

Bobrisky ló ń fojú ba ilé ẹjọ́ lórí ẹ̀sùn mẹ́fà tó dá lórí ṣíṣe owó náírà lọ́nà àìtọ́.

Bákan náà ló ń kojú ẹ̀sùn tó dá lórí ọgọ́sàn-án mílíọ̀nù náírà látara ilé iṣẹ́ rẹ̀, BobExpress.

Ní nǹkan bíi aago mẹ́sàn-án àárọ̀ ọjọ́ Ẹtì ni Bobrisky gúnlẹ̀ sí ilé ẹjọ́ nínú ọkọ̀ bọ́ọ̀sì EFCC pẹ̀lú àwọn ọlọ́pàá.

Bobrisky

Oríṣun àwòrán, Bobrisky/INSTAGRAM

Lónìí, ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ Karùn-ún, oṣù Kẹrin ọdún 2024 ni gbajúmọ̀ akọ tó máa ń ṣe bí abo, Idris Olanrewaju Okuneye tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Bobrisky yóò fojú ba ilé ẹjọ́.

Ní ọjọ́rú ni Bobrisky ti wà ní àhámọ́ àjọ tó ń gbógunti ìwà àjẹbánu ní Nàìjíríà, EFCC fẹ́sùn ṣíṣe owó náírà lọ́nà àìtọ́.

Ẹ̀sùn mẹ́fà tó dá lórí ṣíṣe owó náírà lọ́nà àìtọ́ àti àìkéde ohun tí iléeṣẹ́ rẹ̀, BobExpress dá lé lórí ni Bobrisky ń kojú.

Ẹ fojú sọ́nà lórí bí ìgbẹ́jọ́ náà yóò ṣe lọ lórí ìkànnì yìí.

Níbo ni Bobrisky ti rí béèlì Náírà tó ń ṣe kúmọkùmọ níbi ìfilọ́lẹ̀ fíìmù Ajakaju? EFCC ń bèèrè

Bobrisky

Oríṣun àwòrán, @EFCC/X

Àjọ tó ń gbógunti ìwà àjẹbánu ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, EFCC ti fi póró òfin fi gbajúmọ̀ ọkùnrin tó máa ń múra bí obìnrin, Idris Okuneye tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Bobrisky.

Bobrisky gẹ́gẹ́ bí agbẹnusọ EFCC ṣe sọ ti wà ní àhámọ́ láti ọjọ́ Kẹta, oṣù Kẹrin ọdún 2024.

Nígbà tó ń fìdí ìròyìn náà múlẹ̀ fún BBC News Yorùbá, agbẹnusọ EFCC, Dele Oyewale ní ìwà ṣíṣe owó náírà lọ́nà tí kò tọ́ ni àwọn ránṣẹ́ pé Bobrisky fún.

Oyewale ní láti bí ẹnu ọjọ́ mẹ́tà yìí ni àwọn ti ń ṣe àkíyèsí àwọn ìwà tí Bobrisky hù lórí ṣíṣe owó náirà lọ́nà tí kò yẹ, tí àwọn sì kọ̀wé ránṣẹ́ si pé kó yọjú sí ilé iṣẹ́ àwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ Eko.

A foju Bobrisky bale ẹjọ lẹyin iwadi wa - EFCC

Ajọ EFCC ni oun pe Bobrisky, ẹni ọdun mẹtalelọgbọn, lati wa sọ ibi to ti ri owo to n se kumọkumọ naa lasiko ifilọlẹ sinima Ajakaju.

“Se ni Bobrisky gbe beeli owo Naira lọwọ, to si n na nibi sinima Ajakaju ti Eniola Ajao se.

Ifilọlẹ sinima naa si lo waye ni Film One Circle Mall, Lekki, Lagos ni ọjọ Aiku, ọjọ kẹrinlelogun osu kẹta ọdun 2024.

Iwadi wa si tun fihan pe, Bobrisky ti sẹ iru awọn ẹsẹ bayii ni aimọye igba lawn oniruuru ayẹyẹ mii to ti lọ sẹyin.

Idi ree ti ajọ Efcc se kọwe ransẹ si pe ko yọju si wa ni aarọ ọjọru fun ifọrọwanilẹnuwo ati akọsilẹ idahun rẹ.”

Ajọ EFCC wa kede pe oun yoo foju Bobrisky bale ẹjọ lẹyin iwadi oun.

Àkọlé fídíò, Owobo Ogunde: Mo ṣì ń rí bàbá mi Ogunde lójú àlá, ohun tó sọ fún mi ni máà ṣe páta

A ti nawọ́ gán Bobrisky, ó wà ní àhámọ́ wa - EFCC

Bobrisky

Oríṣun àwòrán, Bobrisky/INSTAGRAM

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ó ṣàlàyé pé àwọn ránṣẹ́ pé Bobrisky lẹ́yìn tí fídíò kan ṣe àfihàn bí ó ṣe ń ná owó, tó sì ń jó lórí náírà níbi ayẹyẹ ìfilọ́lẹ̀ fíìmù Ajakaju tí gbajúmọ̀ òṣèré Eniola Ajao.

Ní ilé sinimá Film One Circle Mall tó wà ní Lekki, ìpínlẹ̀ Eko ni ayẹyẹ náà ti wáyé lọ́jọ́ Kẹrìnlélógún, oṣù Kẹta ọdún 2024.

Níbi ayẹyẹ náà ni wọ́n ti fún Bobrisky ní àmì ẹ̀yẹ obìnrin tó múrà dada jùlọ, tó sì gba owó mílíọ̀nù kan náírà.

Ìgbésẹ̀ fífún Bobrisky ní àmì yìí ṣokùnfà awuyewuye lórí ayélujára, tí ọ̀pọ̀ àwọn òṣèrébìnrin àtàwọn míì korò ojú sí ìgbésẹ̀ ọ̀hún.

Ẹ̀wẹ̀, EFCC ní bí Bobrisky ṣe ṣe owó náírà kúmọkùmọ níbi ayẹyẹ náà ni àwọn ránṣẹ́ pè é.

“Bobrisky fúnra rẹ̀ ló wá sí iléeṣẹ́ wa lẹ́yìn tí a ránṣẹ́ pè é, òun ló fi ẹsẹ̀ ara rẹ̀ rìn wá sí iléeṣẹ́ wa ní ìpínlẹ̀ Eko.

“A ṣàlàyé fun pé a ma fi sí àhámọ́, a sì sọ ìdí tó fi máa wà ní àhámọ́ wa fun títí ti di ìgbà ná, ọ̀rọ̀ lórí ṣíṣe owó náírà kúmọkùmọ ni a fi sí àhámọ́ fún.”

Oyewale ṣàlàyé pé ìwádìí ṣì ń tẹ̀síwájú lórí àwón ẹ̀sùn tí Bobrisky wà ní àhámọ́ àwọn fún àti pé ní kété tí ìwádìí bá ti parí ni àwọn máa gbe lọ sí ilé ẹjọ́.

“A máa gbe lọ sí ilé ẹjọ́, à ń ṣe ìwádìí wa lọ́wọ́ ni, ní été tí ìwádìí bá ti parí ni a máa gbe Bobrisky lọ sílé ẹjọ́.”

Ìdí rèé tí ọlọ́pàá kò fi lè mu Bobrisky àtàwọn yòókù rẹ̀ ti wọ́n ń ṣe bíi obìnrin

Aworan Bobrisky ati Alukoro olopaa Naijiria, Olumuyiwa Adejọbi

Oríṣun àwòrán, Bobrisky Instagram, @Princemoye

Ṣaaju ni ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria ti ṣalaye idi ti ko fi le fọwọ ofin mu Idris Okuneye, akọ to n mura bii abo, ti ọ̀pọ̀ eeyan mọ̀ si Bobrisky atawọn yooku rẹ.

Bobrisky jẹ́ ọkunrin latilẹ gẹgẹ bi oun funra rẹ naa ṣe mọ, sugbọn o pẹ to ti n mura bii obinrin.

Bobrisky ni oun ṣiṣẹ abẹ ọyan ati idi, bẹẹ lo ni nnkan ọmọkunrin ko si labẹ oun mọ, afi ti obinrin.

Awọn iṣesi yii ṣajeji nilẹ adulawọ, paapaa ni Naijiria.

Ọpọ eeyan lo si ro pe o yẹ ki wọn ti fi kele ofin gbe Bobrisky atawọn ọkunrin bii tiẹ, ti wọn n ṣe bii obinrin.

Ki ni ọlọpaa sọ pe o ṣẹlẹ, ti wọn ko fi le mu Bobrisky atawọn yoku rẹ?

Agbẹnusọ ọlọpaa pata ni Naijiria, Ọmọọba Olumuyiwa Adejọbi, ṣalaye pe ofin ko le mu Bobrisky atawọn ẹgbẹ rẹ, nitori ọrọ wọn gbẹgẹ gan-an.

Ninu ifọrọwerọ ti Adejọbi ṣe lori Tẹlifiṣan Channels, o ni koda kawọn eeyan maa fẹsun kan wọn pe wọn n bara wọn ṣe ibalopọ akọ sakọ, abi abo si abo, ofin ko le mu wọn nitori ko si ẹri to fidi ẹ mulẹ.

O lawọn ko si le gbe wọn lọ si kootu lori ohun ti ko ni ẹri.

Adejọbi sọ pe, “awọn iṣẹlẹ kan wa to ṣoroo fidi ẹ mulẹ. Mi o sọ pe wọn o pọ ti wọn n huwa yii o.

‘’Bi ẹsun ifipabanilopọ ṣe lagbara to yẹn, ẹni ti wọn ṣe e fun le padanu ẹjọ rẹ bi awọn koko pataki kan ba sọnu ninu iṣẹlẹ naa.

‘’Ẹ tun jẹ ka jọ foju inu wo o, o ko le ka ẹsun si eeyan lẹsẹ, bi o ko ba ni ẹri to fẹsẹ mulẹ nipa rẹ.

‘’Emi o dẹ ti i ri i ka nibi kankan ri pe ẹṣẹ ni ki ọkunrin mura bii obinrin ni Naijiria yii.

‘Ọna kan ṣoṣo ta a le fi mu wọn ree’

Alukoro ọlọpaa Naijiria tẹsiwaju pe bawọn ba fẹẹ fọwọ ofin mu Bobrisky atawọn ẹgbẹ rẹ, afi ko jẹ pe wọn ti n ṣe nnkan mi-in to lodi sofin pẹlu bi wọn ṣe n pe ara wọn.

Adejọbi sọ pe bi wọn ba n huwa mi-in to jẹ iwa ọdaran ninu ofin Naijiria, ti ẹri aridaju si wa fun un, nigba naa nijọba le mu wọn.

Lẹnu ọjọ mẹta yii ni awuyewuye gbalẹ kan lorii Bobrisky, nigba ti wọn fun un ni ami-ẹyẹ obinrin to mura daadaa julọ nibi afihan fiimu kan.

Ọpọ eeyan lo koro oju si eyi, wọn ni Bobrisky ti ki i ṣe obinrin yoo ṣe maa gbade mọ awọn arẹwa obinrin to kun ibi ode naa lọwọ.

Ṣugbọn Bob loun ko ba ẹnikẹni rojọ, obinrin loun, afi ki gbogbo obinrin gba oun gẹgẹ bi ọkan lara wọn.

Yatọ si Bobrisky, awọn mi-in ti wọn tun n ṣe bii obinrin ni: James Brown, Buchi Alexandra,Tobi The Creator ati Onyx Godwin.

Awọn mi-in ni Bryan Nwakoro, Johntel Peters ati Jefferson Ndoma