Ìwọde gbòde ní Israel láti tako ìjọba Netanyahu

Aworan awọn oluwọde ni Israel

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Iyapa ẹnu to wa laarin awọn oloṣelu lorileede Israel tun gberasọ pada.

Wọn ti fi igba kan sinmi diẹ lẹyin ikọlu ti Hamas ṣe si orileede naa lọjọ Keje oṣu Kẹwaa amọ lẹyin oṣu mẹfa bayii, awọn oluwọde ti pada si opopona ilẹ naa.

Ogun to n lọ lọwọ ti wa dabi iwuri lati yẹ aga nidi Netanyahu to jẹ olootu ijọba to pẹ julọ lori oye ni Israel.

Ni Jerusalem niṣe lawọn ọlọpaa n ta omi rirun sara awọn oluwọde to di opopona Begin Boulevard to jẹ ọpopona pataki si agbegbe ariwa guusu marosẹ ilẹ naa.

Awọn oluwọde gbe patako ti wọn fi n beere ikọwefiposilẹ rẹ ati idibo kiakia.

Wọn tun fi ipe ranṣẹ ki wọn tu awọn ọmọ Israeli 130 to wa ni ahamọ ni Gaza silẹ.Wọn ko le darukọ ni pato iye awọn wọnyi to ti ku.

Ohun to si n ka awọn oluwọde laya ni pe bi ogun naa ṣe n tẹsiwaju lawọn mi yoo padanu ẹmi wọn ti wọn ko ba ribi pẹtu saawọ to wa nilẹ yi.

Aworan oluwọde Katia Amorza

Oríṣun àwòrán, Oren Rosenfeld

Ni irọlẹ ọjọ Aiku ẹgbẹgbẹrun awọn oluwọdi lo kora jọ siwaju ile aṣofin Israel.

Katia Amorza ti ọmọ rẹ wa ninu awọn ọmọ ogun to n kopa ninu ogun Gaza ba wa sọrọ.

O ni ‘’Lati ago mẹjọ aarọ ni mo ti wa nibi.Mo si n sọ fun Netanyahu pe ko ni mi lara lati ya tikẹti baalu first class ko gbera kuro lọ sibi toba fẹ lọ ko si ma pada wa mọ’’

"Mo si n sọ fun pe ko gbe gbogbo awọn ti wọn wa ninu ijọba to yan sipo,ijọba to buru julọ taa ni lawujọ wa’’

Rabbi kan kọja lẹgbẹ Katia .

Yehudia Glick lorukọ rẹ o si wa lara awọn to n polongo pe ki wn faaye ijọsin silẹ fawọn juu ni Temple Mount to wa ni Mọsalaṣi Al Aqsa.

Rabbi Glick sọ pe awọn eeyan ti gbagbe pe ọta wọn gidi kii ṣe Netanyahu bi kii ṣe Hamas.

O ni ''Mo lero pe ilumọọka lo jẹ ohun to si n mu inu bi awọn eeyan niyẹn.Mo si lero pe inu wọn ko yọ si pe tohun ti pe awọn n ṣe iwọde laimọye ọdun, Netanyahu si wa lori oye.’’

O wa kesi awọn oluwọde naa lati jade sọ nkan to wa lọkan wọn ṣugbọn ki wọn ma ṣe kọja aala to wa laarin ijọba awarawa ati iwa janduku.

Ojo ni Netanyahu

Ọjọ ti pẹ ti Ọgbẹni Netanyahu ti n tako idasilẹ orileede Palestine.

Awọn alatako rẹ sọ pe atako rẹ to n ṣe si gbogboigbiyanju lati pẹtu saawọ to n lọlọwọ ni Gaza jẹ ọna kan gboogi fun lati maa ri atilẹyin awọn ẹgbẹ Israel ti adisọkan wọn ko fararọ.

Ọkan lara awọn to peju siwaju ile aṣofin Israel taa mọ si Knesset ni David Agmon jẹ.

Ajagunfẹyinti ni to si dari ọfisi olootu ijọba nigba ti wọn kọkọ yan Neytanyahu sipo.

‘’Wahala to wa nilẹ yi lo buru julọ ninu itan lati ọdun 1948.Emi ni olori oṣiṣẹ akọkọ ni ọfisi Netanyahu nigba to depo ni ọdun 1996. Lẹyin oṣu mẹta to dori oye ni mo pinnu lati kọwe fipo silẹ.Mo mọ daada. Ipalara nla lo jẹ fun Israel.’’

‘’Kii ṣe ẹni to le gbe igbesẹ tẹle aṣẹ to ba pa. Ojo ni. Ọrọ lasan lo si mọọ sọ.Mo ri wi pe iyawo rẹ lo n dari rẹ .Lẹyin oṣu mẹta mo sọ fun pe Bibi, amugbalẹgbẹ kọ lo nilo.Ẹni ti yoo rọpo rẹ lo nilo.Mo si fi ijọba rẹ silẹ’’