Israel-Gaza: Olóòtú ìjọba Israel tako àbá Ààrẹ America láti jẹ́ kí Palestine dá dúró

Benjamin Netanyahu

Oríṣun àwòrán, EPA

Olootu ilẹ Isrẹli, Benjamin Netanyahu, tun ti kọ ọrọ si Aarẹ ilẹ Amẹrika, Joe Biden lẹnu lori aba to da fun un lati da ipinlẹ Palestine silẹ.

Eyi waye lẹyin ọrọ ti awọn olori orilẹ-ede mejeeji yii jọ sọ lori foonu, nibi Aarẹ Amẹrika ti ni aaye ṣi wa fun Netanyahu lati gba aba naa wọle.

Aarẹ Biden ṣalaye, pe bi wọn ba da ipinlẹ Palestine silẹ, ti Isrẹli naa si wa, ojutuu yoo wa si iṣoro wọn, aibalẹ ọkan ọlọdun pipẹ to n da wọn laamu yoo si dopin.

Aarẹ Amẹrika naa tẹsiwaju, pe awọn orilẹ-ede kan naa ṣaa wa lara ajọ Iṣọkan Agbaye, ti wọn ko si da ni ikọ ọmọ ogun tiwọn.

Nigba to n tako eyi lọjọ Satide, ogunjọ oṣu kin-in-ni ọdun 2024 yii, Aarẹ Netanyahu sọ pe ipinnu oun ṣi duro.

O ni lẹyin ti wọn ba doju Hamas bolẹ tan, ilẹ Isrẹli gbọdọ gba agbara eto aabo rẹ pada lorii Gaza.

O ni eyi gbọdọ waye ki Gaza ma baa tun maa dunkooko mọ Isrẹli.

Igbẹsẹ yii tako idaduro orilẹ-ede Palestine.

Bakan naa, loju opo X rẹ lọjọ Satide yii, Aarẹ Isrẹli sọ pe orilẹ-ede oun gbọdọ ri i daju pe agbara eto aabo ko bọ.

O ni o gbọdọ lagbara lori gbogbo agbegbe Iwọ-Oorun (Odo Jọdani), ati gbogbo agbegbe ti wọn mọ si West Bank Territory.

Ṣaa, oju tawọn mi-in fi wo ọrọ naa ni pe o le mu ireti awọn kan pin.

Wọn ni o le fa ija agba meji, ti awọn olori Isrẹli ati Palestine yoo kọju ija sira wọn.

Awọn to ti ti ku latọwọ ikọ Hamas ti to ẹgbẹrun kan ati ọgọrun meji (1, 200), ojilenigba (240) lo wa lahaamọ ogun ti wọn ko rọna jade

Ọpọ awọn afẹhonuhan lo tu jade lọjọ Aiku

afehonuhan

Oríṣun àwòrán, Reuters

Patako to ni akọle oriṣiiriṣii ni awọn olufẹhonu han yii gbe dani, ti wọn n pariwo pe ki Netanyahu fẹnuko sibi kan pẹlu awọn to ko eeyan awọn pamọ, ki wọn tu wọn silẹ, ki wọn too ku sigbekun ogun.

Guusu Gaza lawọn ọmọ ogun Isrẹli doju le bayii, wọn n wa awọn olori Hamas

Awọn olori Hamas ti wọn lo ṣee ṣe ki wọn maa fara pamọ si Guusu Gaza, paapaa lagbege kan ti wọn n pe ni Khan Younis, ni awọn ologun Isrẹli ṣiju si bayii.

Bakan naa ni wọn si ti kọlu ibi kan ti wọn n pe ni Jabalia.

Àkíyèsí: À ti ṣe àtúnṣe kékeré sì ìròyìn yìí