Ìlú Igboho rèé, níbi tí ọba mẹ́ta ti ń ṣèlú, ta ni ojúlówó ọba láàrin wọn?
Ilu Igboho jẹ ilu nla to tobi sikẹfa nipinlẹ Oyo.
Oniruuru ohun itan abalaye si lo wa nilu Igboho nitori nibẹ ni wọn ko ilu Oyo ikeji lọ.
Amọ bi ilu Igboho ti se pataki si ninu itan Oyo ati ilẹ Yoruba ni apapọ, ede aiyede nipa asaaju ilu naa wa.
Idi ni pe oriade mẹta ọtọọtọ lo n pe ara wọn ni ọba ilu Igboho, ti wọn ko si gba fun ara wọn.
Yoruba bọ, wọn ni ọga meji ko le gbe inu ọkọ kan soso, bi agbo meji ko se le mu omi ninu koto kan.
Awọn mẹtẹẹta naa lo kọ aafin nla fun ara wọn, ti wọn si n se ijọba ni agbegbe wọn gẹgẹ bii alakoso ilu.
Orukọ awọn ọba mẹtẹẹta naa ni Ọba Joel Olalere Olawuwo, tii se Alépàtà ti ilu Igboho.
Ọba keji ni Ọna Onibode tilu Igboho, Ọba Abdulrasheed Jaiyeola nigba ti Ọba kẹta jẹ Onigboho ti ilu Igboho, Ọba Jimoh Oyetola Bolarinwa.

Meji ninu awọn oriade naa, Alepata ti Igboho ati Ona Onigbode si lo ti gbe ẹjọ ipo ọba yii lọ sile ẹjọ, ti awọn ẹjọ naa si de ile ẹjọ to ga julọ nilẹ wa.
Awọn oriade mejeeji yii si lo fidi rẹ mulẹ pe ile ẹjọ to ja julọ naa da awọn lare pe awn ni Ọba ilu Igboho.
Ẹni kẹta wọn, tii se Ọna Onibode n tiẹ ni kii se ile ẹjọ tabi iwe ofin ilẹ wa ni yoo kede ẹni to jẹ ojulowo Ọba ilu Igboho bikose itan adayeba to wa nilẹ.
N jẹ ta wa ni Ọba ilu Igboho gangan laarin Onigboho, Alepata ati Ona Onigbode?
Bawo lo si ti se rrun si fun awn ori ade mtta naa lati maa dari ilu kan soso?
BBC Yoruba de ilu Igboho lati wa idahun si ibeere yii, abọ wa ree gẹgẹ bi ohun ti awọn oriade mẹtẹẹta naa ba wa sọ.

Alaafin lo ran Alepata pada silu Igboho lati maa se olori wọn - Ọba Joel Olalere Olawuwo
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Alépàtà ilu Igboho, Ọba Joel Olalere Olawuwo sọ bi wọn se tẹ ilu Igboho do.
“Nigba ti awọn eeyan ilu Oyo ati Alaafin kuro nilu Oyo akọkọ nitori wahala to n koju wọn.
Babalawo sọ fun wọn pe ibi ti ẹyẹ meji ba ti n ja, ti wọn fi ja lulẹ, ni ki wn tẹdo si.
Wọn si rin titi ti wọn fi ri ẹyẹ meji to n ja, ti wọn si ja lulẹ. Wọn wa wo awọn ẹyẹ naa, ọkan jẹ ẹyẹ Ugbo, ekeji si jẹ ẹyẹ uyo.
Wọn wa gba orukọ ẹyẹ mejeeji pọ, Ugbo ati Uyo, o si di Igboho, eyi ni wn fi sọ ilu ti wọn tẹdo si, to n jẹ Igboho.
Nigba to n sọrọ lori ẹni to jẹ ojulowo ọba ilu Igboho, Alepata ni ko si bi a se le sọ itan ilu Igboho, lai mẹnuba Alaafin Oyo.
“Bi a ba fẹ sọ itan ilu Igboho, a sọ nipa Alaafin Oyo ati Alépàtà nitori Alaafin lo mu Alepata lọwọ lọ si Oyo lẹyin to fi ilu Igboho silẹ.
Nigba to fidi kalẹ si ilu Oyo tan, Alaafin ran Alepata pada si Igboho lati maa lọ se Olori ati Ọba ilu naa, gẹgẹ bi Ọba to n soju Igboho.
"Alepata nile ẹjọ to ga julọ nilẹ wa kede bii ojulowo ọba to n se akoso ilu igboho"
Amọ nigba ti awọn eeyan to jẹ ijoye mi wa n jade lati pe ara wọn ni ọba Igboho, eyi lo mu ki Alepata kọwe si ilu Oyo lọdun 1978, ti wọn si fidi rẹ mulẹ pe ohun ni Ọba Igboho.
Bakan naa, agbekalẹ igbimọ oluwadi, ta mọ si Enquiry waye lati mọ ojulowo ọba ilu Igboho gan ldun 1981.
Ijọba ransẹ pe awọn ilu to sun mọ ilu Igboho lati beere pe ta ni wọn mọ bii Ọba gangan nilu Igboho.
Gbogbo wọn si lo da ijọba lohun pe Alepata ni awọn mọ bii ojulowo ọba nilu Igboho.
Bakan naa, gbogbo iwe ijọba naa lo tọkasi Alépàtà gẹgẹ bii ojulowo ọba ilu Igboho, to si jẹ pe maa n soju ilu naa ninu igbimọ awọn lọbalọba nipinlẹ Oyo.
Alepata naa si ni aarẹ kootu ibilẹ lati aye awọn oyinbo amunisin.”
Alepata wa fikun pe wọn ti gbe ẹjọ Ta ni ojulowo ọba ilu Igboho lọ sile ẹjọ, to si de iwaju ile ẹjọ to ga julọ nilẹ wa, ta mọ si Supreme Court.
O wa kede pe oun Alepata nile ẹjọ to ga julọ nilẹ wa kede gẹgẹ bii ojulowo ọba to n se akoso ilu igboho.

Oyo tabi Alaafin kọ́ lo tẹ ilu Igboho do, awọn eeyan ti n gbe nilu naa, ki Alaafin to wa ba wọn nibẹ - Ọba John Oyetola Bolarinwa
Ọba John Oyetola Bolarinwa tii se Onigboho ti ilu Igboho, lasiko ti ohun n ba BBC Yoruba sọrọ pa itan nipa bi wn se sẹdasilẹ ilu Igboho.
O ni awọn oke to wa lẹyin aafin oun, ti wọn tun n pe ni iho to wa lori oke, ni awọn eeyan n fi n pe ilu Igboho.
“Nigba ti awọn eeyan itẹdo tẹdo sinu iho to wa lawọn oke nla to yi Igboho ka, awọn eeyan to n kọja lọ wa n beere pe:
Awọn wo lo wa ninu igbo oniho yii, igbo oniho ni wọn n pe ilu naa, ibi ti Igboho ti jade ree.”
Amọ Onigboho ko gba pe awọn araalu Oyo tabi Alaafin lo tẹ ilu Igboho do, o ni awọn eeyan Igboho ti n gbe nilu naa, ki Alaafin to wa ba wọn nibẹ
"Onigboho nijọba ipinlẹ Oyo mọ bii ojulowo ọba to n sakoso ilu Igboho"
Bakan naa lo salaye pe oun Onigboho nijọba ipinlẹ Oyo mọ bii ojulowo ọba to n sakoso ilu Igboho.
“Mo kan sadede gba ipe lati ọ dọ ijọba ipinlẹ Oyo pe ki n wa sọgba Secretariat lasiko ti Arabinrin Funmilayo Orisadeyi jẹ Kọmisana ninu isejọba Seyi Makinde.
Wọn ki mi ku oriire nigba ti mo de ibẹ, wọn ni ijọba Oyo ti sedamọ Onigboho gẹgẹ bi Ọba ilu Igboho, ti wn si ti setan lati da gbogbo ẹtọ mi pada fun mi.
Inu mi dun de ẹyin lọjọ naa, ọjọ yii si ni inu mi dun julọ nile aye.
Lọjọ ti awọn osisẹ ijọba naa kede pe awọn n bọ wa silu Igboho lati sedamọ mi, awọn atọhunrinwa ko igi dina lai mọ pe awọn osisẹ naa ti nwọnú ìlú náà ko to di ọjọ naa”
Onigboho naa fidi rẹ mulẹ pe ọrọ ta ni ojulowo ọba ni Igboho ti de iwaju ile ẹjọ to ga julọ nilẹ wa, ti wọn si da oun lare.

Kii se ẹjọ tabi iwe ofin ni wọn fi n mọ ojulowo ọba ilu kan, bikose itan to so mọ isẹdalẹ ilu naa - Ọba Abdulrasheed Jaiyeola
Ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC Yoruba, Ona Onibode ti Igboho, Ọba Abdulrasheed Jaiyeola naa sọrọ lori idasilẹ ilu Igboho.
O ni ọdun 1512 ni Alaafin Ẹ̀gúngúnojú da ilu Igboho silẹ, ti aafin oun si wa lori ibi ti Alaafin naa tẹdo si nigba naa.
O ni kii se ẹjọ tabi iwe ofin orilẹede Naijiria ni wọn fi n mọ ojulowo ọba ilu kan, bikose itan to so mọ isẹdalẹ ilu kan.
Bakan naa lo salaye pe itumọ orukọ oun, Ona Onibode ni ohun ti Alaafin sọ pe “Ọmọ mi ọna bode, eyi ti wọn n pe ni Ọna Onibode lonii.
"Alaafin Oyo gangan lo wa gbe ade le mi lori gẹgẹ bii ojulowo ọba ilu Igboho.”
O ni Alaafin Abípa lo gbe Oyo ile kuro ni Igboho, lọ si Oyo to wa lonii, ko le pada si orirun rẹ
“Awọn ohun isẹnbaye ti a le tọkasi pe emi ni ojulowo ọba ilu Igboho wa nilẹ.
Itan ni wọn fi n tẹ ilu, wọn kii fi ile ẹjọ tẹ ilu tabi ‘Constitution’
Ọja adayeba akọkọ , mọsalasi akọkọ, igi nla, ọja ati igbalẹ, to maa n wa lẹgbẹ aafin ọba ilu kan, lo wa lẹba aafin mi.
Kaa awọn ayaba akọkọ ati ti Alaafin wa ninu aafin mi. To fi mọ ọja isẹnbaye.
Gbogbo iwe ẹjọ ti wọn n gbe kiri kọ lo kan, Alaafin Oyo gangan lo wa gbe ade le mi lori gẹgẹ bii ojulowo ọba ilu Igboho.”
Ona Onibode ni alaafia ilu lo jẹ oun loju, oun si setan lati gba alaafia laaye.













