Bí èèyàn ṣe lè ní àìsàn kíndìnrín tori ààwẹ̀ gbígbà

Aworan awo ati ṣibi

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìséraró kuro nibi jijẹ-mimu ati awọn nnkan ti Oluwa ko fẹ ni a n pe ni aawẹ gbigba.

Eeyan ko ni i jẹun lasiko to ba n gbaawẹ, bẹẹ ni nnkan mimu rẹ paapaa yoo dinku.

Ọlọkan-o-jọkan idi lawọn eeyan n tori ẹ gbaawẹ, lati sunmọ Oluwa si i, lati jẹ ki ara fuyẹ keeyan si dun un wo ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Bi awọn idi yii ṣe dara to,o le di nnkan mi-in gẹgẹ bi Dokita McJinger Ibeneme ṣe ṣalaye.

Awọn dokita sọ pe aawẹ le fa aisan kindinrin, aisan ẹdọ, akoba fun ọpọlọ ati iku paapaa.

Bawo ni aawẹ gbigba ṣe le fa awọn aisan ati iku ?

Dokita McJinger Ibeneme, sọ pe beeyan ko ba jẹun, iṣoro lo jẹ fun ara, nitori ara ko ni i le ṣiṣẹ to yẹ ko ṣe.

“Eroja Glucose ni ara eeyan n lo lati ṣiṣẹ ati fun okun. Ounjẹ lo n mu okun wa fara.”

" Ni gbogba igba teeyan ba ṣi wa laye, iṣẹ lara n ṣe"

" Kindinrin lo n fọ idọti kuro ninu ara, bẹẹ ni ẹdọ naa n ṣiṣẹ tiẹ lọtọ.

Ifun inu wa lo n da aisan pada, oju niṣẹ tiẹ to n ṣe fara.

Gbogbo iṣẹ yii ki i ṣe lasan, ibi ounjẹ ta a ba jẹ ni agbara yoo ti wa.”

"Bii mọto to n lo epo naa ni, bẹẹ ni ara eeyan naa ṣe nilo epo tiẹ".

"Bi eeyan ko ba jẹun, ara yoo mú lara ọra to wa lara ẹni naa lati ni okun. Ohun to kan ṣẹlẹ ni pe ọra ti ara yoo mú yii ko ni i da bii ti eyi to yẹ ko ni."

Kí làwọ̀n dókítà sọ nipa ààwẹ̀ gbígbà?

Awora ọbẹ, fọọki ati aago

Oríṣun àwòrán, Getty image

"Ẹ maṣe ko inira aawẹ gbigba ba awọn eeyan ti wọn ko lokun lara"

Àgbàjù aawẹ ni awọn dokita koro oju si.

Wọn ni beeyan ba n gba aawẹ ju lai jẹun bo ṣe yẹ, yoo ṣakoba fun agọ ara rẹ pẹlu awọn aisan ta a ti sọ siwaju.

Ninu ọrọ Dokita Ibeneme,o ni, ‘’ẹ maṣe ko inira aawẹ gbigba ba awọn eeyan ti wọn ko lokun lara.

‘’Awọn bii arugbo pẹlu awọn ọmọde ti ko ti i yẹ ki wọn gba aawẹ".

Bakan naa lo kilọ pe ki i ṣe pe keeyan maa waa fi gbogbo igba jẹun lai ni odiwọn o.

O ni iwọntun-wọnsi ni gbogbo nnkan laye yii, aṣeju ati aito ohun gbogbo ko daa.