Ìjàmbá ilẹ̀ rírì alágbára wáyé ní Taiwan, ẹ̀mí bọ́, ọ̀pọ̀ farapa

Aworan ile to dawo lẹgbẹ kan ni Taiwan

Oríṣun àwòrán, TVBS

Ilẹ riri alagbara kan ti kọlu apa ila oorun Taiwan lỌjọru ti o si kere tan to ti mu ẹmi eeyan mẹrin lọ.

Ilẹ riri naa to to iwọn 7.4 mu ki aimọye ile dawo ni Hualien ilu to sunmọ aringbungbun ibi ti ilẹ riri naa ti waye.

Awọn oṣiṣẹ adoola ti n gbiyanju lati doola awọn ti iṣẹlẹ yi ṣakoba fun un.

Eyi ni ilẹ riri to lagbara julọ laarin ọdun marundinlọgbọn ti yoo kọlu Taiwan.

O lagbara debi pe wọn gburo bi ilẹ ṣe n mi titi to fi kan awọn agbegbe ti ori oke nla yika ni Taiwan.

Ni olu ilu tii ṣeTaipei, niṣe ni a ri awọn fọnran to ṣafihan bi awọn ile ṣe n mi.

Wu Chien Fu to jẹ ọga agba ileeṣẹ to n dari imọ nipa ilẹ riri ṣalaye pe ‘’ilẹ riri to waye yi sunmọ ori ilẹ ti ko si jin pupọ.Wọn gburo rẹ kaakiri Taiwan ati awọn erekusu to wa layika rẹ’’

Ileeṣẹ panapana ilẹ naa sọ pe eeyan mẹta ti padanu ẹmi wọn ninu aaye ibudo igbafẹ orileedee naa lagbegbe Hualien.

O le ni eeyan aadọta to farapa ti awọn eeyan si ha sinu ile to ri ati awọn aaye miran gẹgẹ bi ileeṣẹ naa ti ṣe sọ.

Aworan afihan agbegbe ti ilẹ riri naa ti waye

Ina mọnamọna dẹnukọlẹ lọpọ agbegbe ni Taiwan

Ni Taipei fọnran fidio lori awọn ileeṣẹ iroyin ṣafihan awọn ile igbe to wo ti wọn si n doola awọn eeyan kuro ninu ile wọn ati ni ile ẹkọ.

Ilẹ riri naa tun mu ṣakoba fawọn ọkọ to si sọ awọn nkan ọja ninu ile itaja danu gẹgẹ bi aworan ti ileeṣẹ iroyin TVBS ṣe fihan.

Jakejado erekusu naa ni wọn kede pe ina mọnamọna ati intanẹẹti ti dẹnukọlẹ gẹgẹ bi NetBlocks to n mojuto oju opo ayelujara ti ṣe kede.

Nkan bi ago mẹjọ ku iṣẹju meji owurọ ni ilẹ riri yi bẹrẹ to si jin ni iwọn kilomita mẹẹdogun le diẹ.

Awọn ilẹ riri to tẹle akọkọ yi bi mẹsan an mi tun waye ti wọn lagbara ni iwọn magnitude 4 tabi ju bẹẹ lọ.

Nkan bi mẹẹli mọkanla ni orisun ilẹ riri yi wa si guusu Hualien gẹgẹ bi ileeṣẹ to n mojuto bi oju ọjọ ilẹ America ti ṣe kede.

Aworan ilẹ riri naa lawọn agbegbe to sunmọ ori oke

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ile ẹgbẹrun marun un ni ilẹ riri ṣe akoba fun ni Taiwan lọ́dún 1999

Hualien sodo si agbegbe ila oorun Taiwan ni agbegbe ibi ti ori oke pọ si.

Awọn eeyan ko pọ lawọn ilu to wa lagbegbe yi.

Bayii ti awọn opopona ati oju irin to so agbegbe naa mọ Taiwan ti dẹnukọlẹ o ṣeeṣe ko ṣe pe baalu lawọn ti yoo ba wa ṣe iṣẹ idoola yoo ba wa.

Loṣu Kẹsan ọdun 1999 ni ilẹ riri kan to lagbara niwọn 7.6 magnitude ẹ ikọlu si Taiwan to si gbẹmi eeyan to fẹẹ to ẹgbẹrun meji abo.

Ile ẹgbẹrun marun un ni ilẹ riri yi ṣe akoba fun.