Mọ̀ nípa Oba Haastrup tó gbọ́pa àṣẹ gẹ́gẹ́ bí Owa Obokun tuntun ti ilẹ̀ Ijesa

Gómìnà Adeleke ń gbé ọ̀pá àṣẹ lé Owa Obokun tuntun lọ́wọ́
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Gómìnà ìpínlẹ̀ Osun, Ademola Adeleke ti gbé ọ̀pá àṣẹ lé Ọba Adesuyi Haastrup lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí Owa-Obakun ìlú Ijesa.

Ní ọjọ́ Àìkú, ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kejìlá ni ètò ayẹyẹ náà wáyé ní gbọ̀ngàn Obokungbusi ìlú Ilesa, ìpínlẹ̀ Osun.

Ìyànsípò Ọba Haastrup waye lẹ́yìn ìpapòdà Owa Obokun àná, Oba Gabriel Adenle Aromolaran tó darapọ̀ mọ́ àwọn babańlá rẹ̀ lọ́jọ́ kejìlá, oṣù Kẹsàn-án, ọdún 2024 lẹ́yìn tó lo ogójì ọdún lórí ipò.

Gómìnà Adeleke níbi ayẹyẹ náà rọ Oba Haastrup láti lo ìrírí tó ti ní kó tó jọba mú ìdàgbàsókè bá ilẹ̀ Ijesa.

Bákan náà ló rọ àwọn èèyàn ilẹ̀ Ijẹsha láti máa ṣe ìrànwọ́ sí ìdàgbàsókè agbègbè wọn tó sì tún sọ àrídájú rẹ̀ pé ìṣèjọba òun yóò túnbọ́ máa tẹ̀síwajú láti máa ṣe awọn ètò ti yóò mu ìlọsíwájú bá ìpinlẹ̀ Osun lápapọ̀.

Gomina Adeleke ati Owa Obokun tuntun
Owa Obokun tuntun pẹlu ọpa aṣẹ ati iw ẹri lọwọ

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, Owa Obokun tuntun, Oba Adesuyi Haastrup ní òun faramọ́ ṣíṣe ìdásilẹ̀ ilé-ẹ̀kọ́ ẹ̀kọ́ṣẹ́ ọwọ́ sí Ilesa níbi tí àwọn oníṣẹ́ ọwọ́ yóò ti ní àǹfààní lati máa kẹ́kọ̀ọ́, tí yóò sì tún fikún pípèsè nnkan tí àwọn èèyàn nílò.

Oba Haastrup ní òun kò ní fàyè gba àwọn tí wọ́n máa ń gba ilẹ̀ lọ́wọ́ èèyàn, tó sì ń pè fún ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àwọn èèyàn láti mú ìlọsíwajú bá ilẹ̀ Ijesa.

Ó ní àsìkò tí gbogbo àwọn ọmọ ìlú nílò láti fọwọ́sowọ́pọ̀ ni báyìí, to sì kan sáárá sáwọn ọ̀dọ́, pé àsìkò ti tó lát pèsè àwọn ohun ìronilápá fún wọn.

"A máa gbé ètò láti tẹ ọrọ̀ ajé ìlú Ijesa kalẹ̀ látara ètò ọ̀gbìn àti ṣíṣe àtìlẹyìn fún iṣẹ́ ọwọ́ àti iṣẹ́ ọnà."

Lẹ́yìn ètò náà ni Owa Obokun bẹ̀rẹ̀ ètò wíwọ ìpèbí láti fi bẹ̀rẹ̀ orò ìwúyè.

Àtẹ̀jáde kan láti ààfin Owa Obokun ní lẹ́yìn tí Oba Haastrup bá kúrò ní Ipebi ni àwọn máa mú ọjọ́ ìwúyè ńlá láti fi ṣayẹyẹ tó yẹ fún Ọba náà.

Ṣááju ni àwọn ìdílé oyè kan ti ń fapá jánú pé àwọn àfọbajẹ kò tẹ̀lé ìlànà tó ye lórí ìyànsípò Oba Haastrup.

Awọn ara ilu nibi eto ayẹyẹ naa

Ta ni Adesuyi Haastrup?

Haastrup

Oríṣun àwòrán, thepointng

Hasstrup, to ti fi akoko igba kan ri di ipo igbakeji gomina ipinlẹ Osun mu ni yii jọba lẹyin ti Ọba Gabriel Adekunle Aromolaran waja.

Oun ni yoo si jẹ Owa Obokun kọkandinlaadọta.

Haastrup ni igbakeji gomina Isiaka Adeleke laarin ọdun 1992 si ọdun 1993.

Ọjọ kọkandinlgun, oṣu Kẹsan an, ọdun 1948 ni wọn bi Haastrup ni idile Ajimoko ti ilẹ Ijesha.

O kẹkọọ ni Eko Boys High School laarin ọdun 1963 si 1967 ko to tẹsiwaju ni Federal School of Sciences, ipinlẹ Eko laarin ọdun 1968 si 1969.

Lẹyin naa lo lọ kẹkọọ ni fasiti Howard, to wa niluu Washington D.C., nilẹ Amẹrika.