Òrìṣà ni Jesu Kristi, Ànọ́bì Muhammad àti Eṣu – Ifayemi Elebuibon

Fayemi Elebuibon
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ifayemi Elebuibon, to jẹ Araba Awo ti ilu Osogbo ti ṣalaye ohun ti Esu jẹ.

O ni Eṣu jẹ oriṣa ati Ojisẹ Olodumare bii Jesu Kristi ati Annabi Muhammad ṣe jẹ oriṣa ati Ojisẹ fun Olodumare.

Baba Ifeyemi tun tẹsiwaju wi pe, aṣiṣe ni alufaa Samueli Ajayi Crowther, ẹni to tumọ Bibeli lede Gẹẹṣi si Yoruba ṣe latari bo ṣe pe Esu ni Satani.

O ni "Eṣu jẹ iranṣẹ fun gbogbo eeyan lati le gbe gbogbo ẹbọ ati adura wa lọ si ọdọ Ọlọrun Olodumare lati le jẹ ko ṣe itẹwọgba niwaju Ọlọrun."

Esu

Ifakayode Ifaniyi, ẹni to jẹ Agbongbon Awo ti ilu Osogbo naa tun sọrọ lori oun ti Eṣu jẹ. Ifaniyi sọ pe Esu kii ṣe ẹni ẹkọ tabi ẹni egbe gẹgẹ bi awọn ẹlẹṣin Musulumi ṣe maa n sọ.

Ifakayode fi kun pe Eṣu jẹ oriṣa to ni aanu ju gbogbo oriṣa ti Olodumare da si aye ati si ọrun.

O ni "Eṣu ki se abani wa ọ̀ràn bi a o rí da ti ọpọ eeyan ma n pe e rara.

"Eṣu jẹ arẹmọ ati olotitọ oriṣa, bakan naa si ni o jẹ oriṣa ti o maa n ba eeyan bẹbẹ niwaju Olodumare lọpọ igba ti eeyan ba wa ninu isoro."

Esu

Ẹni to jẹ Olori ẹlẹgun Eṣu ti ilu Osogbo, Ifashola Esuleke ṣalaye fun BBC pe bi gbogbo eeyan ba le gba wi pe, Eṣu kii ṣe Satani, o da oun loju wi pe, orile-ede Naijiria yoo gba alaafia pada.

Ifashola ni idi oriṣa Eṣu ni wọn bi oun si, oriṣa Eṣu naa ni oun n sin lati igba ewe oun titi di asiko yii.

Oni oun ti rinirin ajo lọ si orile-ede aláwọ̀ funfun kaakiri ti oun ko si kabamọ wi pe oun n sin oriṣa Eṣu rara.

Gbogbo ọrọ wọnyii lo waye lasiko ti awọn ọdọ onisẹse ti ipinlẹ Osun n ṣe ajọdun odun Eṣu. Ati lati jẹ ki awọn eeyan mọ ìyàtọ̀ laarin Eṣu ati Satani.