Falana rọ Adeleke láti tú Morakinyo Sunday tó gba ìdájọ́ ikú lórí ẹ̀sùn jíjí adìyẹ sílẹ̀

Femi Falana/Ademola Adeleke

Oríṣun àwòrán, Femi Falana/Ademola Adeleke

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Agba agbẹjọro to tun jẹ ajafẹtọọ ọmọniyan, Amofin Femi Falana ti rọ Gomina Ademola Adeleke ti ipinlẹ Osun lati foju aanu wo Morakinyo Sunday ti wọn dajọ iku fun pẹlu Segun Olowookere lori ẹsun jiji adiẹ gbe.

Falana sọ pe ko nii bojumu ki Gomina Adeleke fi Olowookere nikan silẹ lasiko to ba n foju aanu wo awọn ẹlẹwọn ki ọdun too pari, lai fi Morakinyo naa silẹ.

Ninu atẹjade ti Falana gbe sita lọjọ Aje, ọsẹ yii, o ni inu oṣu Kẹrin, ọdun 2010 ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun mu awọn ọmọde mẹfa lori ẹsun idigunjale.

Falana sọ pe "Awọn mẹrin—Dare Sunday, ọmọ ọdun mẹẹdogun; Adedeji Samuel ọmọ ọdun mẹẹdogun; Ojo Dare, ọmọ ọdun mẹrindinlogun; ati Adeyemo Akeem toun jẹ ọmọ ọdun mẹrinla —ni wọn fi silẹ lai ni idi."

"Ṣugbọn ṣa, Segun Olowokere ati Morakinyo Sunday ni wọn pada foju wọn ba ile-ẹjọ ninu oṣu Kẹwaa, ọdun 2012 lori ẹsun mẹjọ ọtọọtọ to nii ṣe pẹlu idigunjale.

"Lasiko ẹjọ naa, awọn ọlọpaa sọ fun ile-ẹjọ wi pe awọn mẹrin to ku ti salọ lai gba beeli wọn, sibẹ ko si ẹri to fidi rẹ mulẹ wi pe wọn kede wi pe wọn n wa wọn.

"Agbẹjọro awọn olujẹjọ sọ pe ẹnikeji, Morakinyo Sunday ni aisan ọpọlọ. Ju gbogbo rẹ lọ, onidajọ naa foju fo ọrọ aisan ọpọlọ naa, to si n ba ẹjọ rẹ lọ," Falana lo ṣalaye siwaju bẹ.

Falana tẹsiwaju pe Gomina Adeleke ti foju aanu wo Olowookere, ẹni ti wọn ti fi silẹ lẹwọn, ṣugbọn ṣa, ẹnikeji rẹ, Sunday ṣi wa ni ọgba ẹwọn to wa ni Kirikiri.

"Nigba to jẹ pe Segun Olowokere ati Morakinyo Sunday ni wọn fẹsun kan naa kan, ti wọn si dajọ iku fun wọn, ofin faaye gba itọju kan naa. Abala kejilelogoji ninu iwe ofin Naijiria tako ẹyamẹya ninu itọju araalu

"Awa n rọ Gomina Adeleke lati sun ọwọ aanu rẹ sọdọ Morakinyo Sunday, ko si foju aanu wo oun naa laipẹ lai jinna," Falana pari ọrọ rẹ.

Ki lohun to ṣẹlẹ?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Lati bi ọsẹ meloo kan sẹyin ni ọrọ Olowookere ti n ja rainrain kaakiri ilẹ Naijiria ati agbegbe rẹ lori bi wọn ṣe dajọ iku fun lori ẹsun jiji adiẹ gbe nipinlẹ Osun.

Ọlọpaa kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Tope Balogun ni wọn lawọn mejeeji yii ji adiẹ meji ati ẹyin rẹ gbe ninu oṣu Kọkanla, ọdun 2010 niluu Oyan, ijọba ibilẹ Odo-Otin.

Ọgbọn ọjọ, oṣu kinni, ọdun 2013 ni wọn foju awọn mejeeji ba ile-ẹjọ giga to wa niluu Ikirun, niwaju Onidajọ Jide Falola lori ẹsun idigunjale ati ole jija.

Gẹgẹ bi agbefọba to fẹsun kan awọn mejeeji niwaju ile-ẹjọ ṣe sọ nigba naa, o ni awọn mejeeji tun ji awọn adiẹ ati ẹyin ẹnikan to n jẹ Oguntade Faramade, eyi ti owo rẹ jẹ ẹgbẹrun lọna ogun naira gbe.

Wọn tun lawọn mejeeji digun ja Balogun Taye lole, ti wọn si gba foonu meji lọwọ rẹ, ati pe wọn n gbiyanju lati ja Alaaja Umani Oyewo lole nile rẹ ko to di pe aṣiri wọn tu ni.

Agbefọba naa sọ pe ibọn kan ati awọn ada ni wọn fi digun gba kẹẹgi ororo lọwọ ẹnikan toun naa n jẹ Elizabeth Dare.

Ṣugbọn awọn ẹsun wọnyi ni awọn mejeeji sọ pe awọn ko jẹbi rẹ, bo tilẹ jẹ awọn ọlọpaa sọ pe Olowookere lo funra rẹ ṣe akọsilẹ wi pe oun gba pe oun jẹbi awọn ẹsun naa.

Ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kejila, ọdun 2014 ni Onidajọ Falola paṣẹ pe ki wọn lọ yẹgi fun Olowokere ati Sunday lori ẹsun igbimọpọ lati digunjale; ẹwọn gbere lori ẹsun idigunjale ati ẹwọn ọdun mẹta lori ẹsun ole jija.