Àwọn ẹ̀bùn mẹ́wàá tí o lè fún àwọn èèyàn lásìkò Kérésìmesì láì pa àpò rẹ lára

Christmas

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Asiko ọdun Keresimesi jẹ asiko ti awọn eeyan maa n ṣajọyo kaakiri agbaye, ti wọn si maa n fi fun ni.

Amọ ṣa, pẹlu bi eto ọrọ aje Naijiria ṣe ri lasiko yii, kii ṣe gbogbo eeyan lo lagbara lati pin ẹbun ti owo rẹ pọ ju bo ṣe yẹ lọ.

Boya o fẹ ra ẹbun fun ara ile rẹ ni, ọrẹ tabi olólùfẹ́ lásìkò ọdún Kérésìmesì yìí, BBC News Yorùbá ṣe àkójọpọ̀ awọn ẹbun mẹwaa ti owo wọn ko pọju ti o le ra fun awọn eeyan rẹ lasiko pọpọṣinṣin ọdun Keresimesiyii.

hampers

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Apẹrẹ ohun jijẹ

Ounjẹ wa lara nnkan to ṣe pataki lasiko ọdun Keresimesi, bẹẹ ilu le, ọpọ ni ko ri owo ra ounjẹ.

Fun idi eyii, o le ra apẹrẹ ohun jijẹ, mimu atawọn nnkan mii ninu rẹ fun awọn ololufẹ rẹ ni owo ti ganpa.

ACE elec

Oríṣun àwòrán, ACE elec

Power Bank

Fun ẹni ti ko ba si lori ipin A lori opo ina ijọba apapọ, ina ọba ko ṣe dede ni Naijiiria. Nitori naa, pẹlu owo ti ko ju N7,00 si N20,000, o le ra batiri ti eeyan le fi gbe ina si ara ẹrọ ibaraẹnisọrọ fun awọn mọlẹbi tabi ololufẹ rẹ.

Awọn ohun elo ara ẹrọ ibaraẹnisọrọ

Ni Naijiria lonii, ṣaṣa ni ẹni ti ko ni ẹrọ ilewọ, bẹẹ, ẹrọ ilewo nilo awọn ohun ti yoo daabo bo ara ati oju rẹ. O le ra irufẹ nnkan bẹẹ fun eeyan ti o ba ṣakiyesi pe pe wọn nilo rẹ. Eyii ko ni na ọ ni owo to pọ ju apo rẹ lọ.

Pẹlu ẹgbẹrun kan si marun un naira, o le awọn nnkan yii fun eeyan.

Book

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Iwe

Lootọ ọpọ ni ko fẹran lati maa ka iwe amọ iwe kika dara pupọ.

Kii ṣe gbogbo igba ni eeyan gbọgdọ maa wo fiimu, fun idi eyii o le ra awọn iwe atọnisọna fun irinajo ọdun tuntun fun ololufẹ rẹ.

Ranti pe ounjẹ yoo tan, aṣọ yoo gbo, amọ iwe wa titi lai.

Blurtooth speaker

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Amohunbugbamu to n lo bluetooth

Eyii yoo wulo fun awọn ọdọ onifaaji, paapaa awọn to ba fẹran ki wọn maa gbọ orin loorekoore.

gamnes

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Oniruru ere ayo

Ayo ti a n sọ nibi kii ṣe eyii ti wọn n ta lori ẹrọ kọmputa bikoṣe eyii ti wọn n ta lori tabili. Irufẹ ayo bẹẹ le ran eeyan lọwọ lati maa ronu daadaa ati lati ni ibaṣepọ to dan mọran pẹlu ẹlomii. Apẹrẹ irufẹ awọn ayo ti a n sọ ni Ludo, Whot, Scrabble, Monopoly, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Gift Cards

Gift Cards wulo pupọ fun ẹni ti o ba ra a fun lati lọ ra ọja lawọn ile itaja igbalode.

Kaka ki o lọ ra nnkan fun eeyan ti ko ni naani iwọ ṣaa ti ra Gift Card ile itaja naa fun wọn ki wọn lọ ra nnkan ti wọn ba n fẹ funra wọn lai san owo kankan nibẹ yatọ si eyii to wa lori kaadi ti o fun wọn.

Ike ti wọn n rọ omi si

Oniruru ike bayii lo wa laye ode oni ti owo rẹ ko ni pa apo rẹ lara.

O tun le kọ orukọ tabi ya aworan si ara irufẹ ike omi ọhun. Eyii yoo wulọ pupọ fun awọn to ni ọmọde lọdọ.

Perfumes

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ipara oloorun didun

Bo tilẹ jẹ pe owo gọbọi ni wọn n ta awọn ipara oloorun didun kan, amọ o le ra eyii ti ọwọ rẹ ka fun ololufẹ rẹ. Pẹlu owo ti ko ju N2,000 si N20,000 o le ra ipara oloorun didun to jọju.

Awọn ohun iṣere tabi iwe ọmọde

Fun awọn ọmọde, awọn nnkan iṣere tabi iwe yoo wulo gidi fun wọn lasiko isinmi yii.