Ọlọ́pàá tó tẹ̀lé Akpabio wá síbi oyè Seyi Tinubu àti Yari ko àgbákò ikú òjijì bí ọkọ̀ agbepo ṣe tẹ̀ ẹ́ lórí mọ́lẹ̀ n'Ibadan

Ìjàm̀bá ọkọ̀ tirela àti ọkada

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Ọ̀fọ̀ ńlá tí ṣẹ lọdọ ààrẹ ilé aṣòfin àgbà nílẹ̀ wa, Godswill Akpabio bí ọlọ́pàá kan tó máa ń wà ọkada ṣáájú àwọn ọkọ to n tó tẹ̀lé ààrẹ ilé aṣòfin àgbà ṣe ko àgbákò ikú òjijì.

Akpabio fúnra rẹ lo kéde ìṣẹ̀lẹ̀ yìí níbi ìjókòó ilé aṣòfin àpapọ̀ to wáyé lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun ana.

Akpabio ṣàlàyé pé òpópónà Márosẹ̀ Ibadan silu Eko ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà tí wáyé lọ́jọ́ Àìkú.

Ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé nígbà tí ọkọ agbepo kan kọlu àwọn ọkọ tó ń tọ lẹ́yìn Akpabio, tó sì pa ọlọ́pàá to máa ń wà ọkada síwájú ọkọ ààrẹ ilé aṣòfin, DSP Hussain Ibrahim.

"Awakọ̀ tanka epo kan kọlu ọlọ́kadà to máa ń ṣáájú ọkọ mi, ó fọ orí rẹ pẹtẹpẹtẹ"

Gẹ́gẹ́ bí Akpabio tí ṣàlàyé, agbegbe to wa nilu Ibadan ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà tí wáyé lẹ́yìn tí wọ́n gbé Akpabio ni pápákọ̀ òfurufú Ibadan to de sí láti lọ síbi ayẹyẹ ìfinijoyè ọmọ ààrẹ, Seyi Tinubu àti Sẹnatọ AbdulAzeez Yari niluu Oyo.

“ A lọ silu Oyo, tí ọkọ̀ sì padà wá gbé mi ni pápákọ̀ òfurufú n’Ibadan.

Àmọ́ O se ni laanu pe awakọ̀ tanka epo kan kọlu ọlọ́kadà to máa ń ṣáájú ọkọ mi, ó fọ orí rẹ pẹtẹpẹtẹ.

A ṣẹ̀ṣẹ̀ sin oku rẹ tán ni bíi isẹju mẹ́ẹ̀dógún sẹ́yìn nipinlẹ Kogi, ìyàwó méjì at ọmọ mẹ́rin lo fi silẹ sáyé lọ.”

"Ẹ̀yin olórí ẹka iléeṣẹ́ ìjọba, mo rọ yín, ẹ bá mi fún méjì nínú àwọn ọmọ olóògbé náà nisẹ ìjọba"

Akpabio bá kéde pé òun yóò fún méjì nínú àwọn ọmọ olóògbé náà ni isẹ ijoba lójú ẹsẹ.

Bákan náà, ó rọ àwọn olórí ẹka isẹ ìjọba àpapọ̀ pé kí wọn fáwọn ọmọ olóògbé náà nisẹ ìjọba.

Àmọ́ o wa fi ọwọ́ gbaya pe bí iléeṣẹ́ ìjọba kankan kò bá gba àwọn ọmọ olóògbé náà ṣíṣẹ́ ìjọba, òun fúnra òun yóò gbà àwọn ọmọ méjèèjì ṣíṣẹ́.

" O ṣe ní laanu pé olóògbé jẹ ẹni tó jara mọ iṣẹ́ àmọ́ dípò kó gba àmì ẹyẹ lẹ́nu isẹ rẹ, ikú lo gba"

Nígbà to n se ìdárò olóògbé náà, ààrẹ ilé aṣòfin àgbà náà ṣàpèjúwe ọlọ́pàá ọlọ́kadà rẹ náà bíi ẹni tó ko ara rẹ ní ìjánu, to si fi ara rẹ jin fún isẹ to yàn láàyò.

Nígbà to n báwọn ẹbí Oloogbe náà sọ̀rọ̀, Akpabio ni ó ṣe ní laanu pé Baba yín jẹ ẹni tó jara mọ iṣẹ́ àmọ́ dípò kó gba àmì ẹyẹ lẹ́nu isẹ rẹ, ikú lo gba.

"Àmọ́ ikú rẹ̀ kò já sí asán, torí ikú náà lọ ń jẹri sì oogun rere to fi silẹ, kí Ọlọ́run bá wà tẹ sì afẹ́fẹ́ rere. "

Bákan náà ni ààrẹ ilé aṣòfin àgbà tún bá ẹbi Oloogbe, ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá àti iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá pátá daro lori ikú Akọni àti akíkanjú ọlọ́pàá tó jáde láyé lásìkò tó wà lẹ́nu ìṣẹ náà.

Ìdásílẹ̀ ìpínlẹ̀ Ibadan ń bọ̀ lọ́nà, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń béèrè fún un - Akpabio ṣèlérí fún ọba Ladoja

Olubadan ti ilẹ Ibadan, Ọba Rashidi Ladoja wọ agbada funfun pẹlu irukẹrẹ lọwọ, nigba ti aarẹ ile aṣofin agba, Sẹnẹtọ Godswill Akpabio, naa wọ agbada funfun, o si de awo soju

Oríṣun àwòrán, Godswill Obot Akpabio/Facebook

Aarẹ ile aṣofin agba l'Abuja, Sẹnẹtọ Godswill Akpabio, ti sọ nipa idasilẹ ipinlẹ Ibadan gẹgẹ bii nnkan to ṣee ṣe ko waye.

Akpabio sọrọ yii lasiko to ṣabẹwo si Olubadan ti ilẹ Ibadan, Ọba Rashidi Ladoja, nile rẹ niluu Ibadan nipinlẹ Oyo.

Aarẹ ile aṣofin ni idasilẹ ipinlẹ Ibadan jẹ ipinlẹ kan ti ọpọ eeyan n beere fun un.

Ṣaaju lasiko iwuye rẹ ni Ọba Ladoja sọ fun Aarẹ Bola Tinubu to wa nibi eto naa wi pe ko ṣiṣẹ lori idasilẹ ipinlẹ Ibadan.

Ladoja rọ Tinubu lati ri pe idasilẹ ipinlẹ Ibadan waye ṣaaju eto idibo aarẹ ọdun 2027.

Lasiko abẹwo rẹ, Akpabio ti Sẹnẹtọ Adamu Aliero, Yahaya Abdulahi, Sharafadeen Ali atawọn sẹnẹtọ mii kọwọọ rin pẹlu rẹ, ṣeleri wi pe awọn aṣofin yoo ṣiṣẹ lori ọrọ naa.

Akpabio ni ''ipinlẹ ti idasilẹ rẹ n bọ lọna ni ipinlẹ Ibadan tori ọpọ eeyan lo ti n beere fun un.''

'Ladoja jẹ ẹni to n wa ilọsiwaju orilẹede rẹ, yoo mu ilọsiwaju ba ipo lọba lọba ni ẹkun iwo oorun guusu Naijiria"

Aarẹ ile igbimọ aṣofin agba ṣapejuwe Ọba Ladoja gẹgẹ bi ibukun nla fun ilẹ Ibadan ati gbogbo ilẹ Yoruba.

O ni ẹni to kaju ẹ ni awọn eeyan Ibadan yan sipo ọba nitori Ladoja ni iriri to pọ gẹgẹ oloṣelu, olokowo to niṣẹ ara rẹ ati oludari ileeṣẹ.

''Ladoja jẹ ẹni to n wa ilọsiwaju orilẹede rẹ, yoo si mu ilọsiwaju ba ipo lọba lọba ni ẹkun iwo oorun guusu orilẹede Naijiria.

Asiko Ladoja yoo mu idagbasoke ati ilọsiwaju ba awọn eeyan ilẹ Ibadan bakan naa.

Ọba Ladoja ti sin Naijiria gẹgẹ bii sẹnẹtọ ati gomina ipinlẹ Oyo tẹlẹ ri.

Gbogbo iriri yii ni yoo wulo fun un ninu iṣẹjọba rẹ gẹgẹ bi Olubadan ilẹ Ibadan.

Àwọn eeyan ti mo jọba le lori ti sọ fun mi pe ki n ja fun idasilẹ ipinlẹ Ibadan - Olubadan

Ninu ọrọ rẹ, Ọba Ladoja dupẹ lọwọ Akpabio fun abẹwo rẹ, o si tun lo anfaani naa lati ran an leti nipa idasilẹ ipinlẹ Ibadan.

Olubadan ni ''awọn eeyan ti mo jọba le lori ti sọ fun mi pe ki n ja fun idasilẹ ipinlẹ Ibadan.

Mo si ti sọ eleyii fun Aarẹ Tinubu lasiko iwuye mi, nnkan yii ni mo tun n sọ lonii bakan naa.

Mo fi asiko yii rọ yin wi pe ki ẹ lo ọfiisi yin gẹgẹ bii sẹnẹtọ lati ri pe idasilẹ ipinlẹ Ibadan wa si imuṣẹ.

Ẹbẹ miran ti mo fẹ bẹ yin ni pe ki ẹ jẹ kofin to rọ mọ ọrọ lọba lọba wa ninu iwe ofin Naijiria.

Mo fẹ ki ẹ ṣiṣẹ lori ọrọ yii ki awọn gomina ma le lagbara lati maa yọ gomina nipo mọ.''