Àlàyé rèé lórí ìdí tí o ṣe gbọdọ̀ ṣàyẹ̀wò mímu oògùn olóró, tí o bá fẹ́ gba iṣẹ́ ìjọba àpapọ̀

Oríṣun àwòrán, Unodc
Ijọba apapọ ti buwọlu ayẹwo oogun oloro fun gbogbo ẹnikẹni to ba fẹ gba iṣẹ ijọba ni Naijiria.
Ọrọ yii lo jẹyọ ninu atẹjade kan lati ọọfisi akọwe agba si ijọba apapọ, Segun Imohiosen.
Imohiosen ni ayẹwo naa jẹ ọkan lara awọn ọna ti ijọba apapọ fi n gbogun ti lilo oogun oloro ati ipa to n ni lara idgbasoke Naijiria.
"Igbesẹ yii ko ṣeyin bi ijọba ṣe n kọminu lori bi awọn ọdọ ṣe n lo oogun oloro lọna ti ko ba ofin mu"
Imohiosen ṣalaye pe ijọba ti paṣẹ fun gbogbo olori ẹka ijọba lati ri daju pe awọn oṣiṣẹ ti wọn ba fẹ gba wọle gbọdọ ṣe ayẹwo fun oogun oloro.
Imohiosen fi kun pe ijọba ti paṣẹ fun awọn olori ẹka ti ọrọ naa kan lati fọwọsowọpọ pẹlu ajọ to n gbogun ti oogun oloro, NDLEA, fun awọn ayẹwo naa.
Atẹjade naa ni "ikede yii lo ti jade lati ọọfisi akọwe ijọba apappọ si gbogbo awọn ti ọrọ naa kan lọna ati gbogun oogun oloro lilo ati lati gba awọn oṣisẹ ijọba lọwọ awọn iwa ti ko tọ."
O ni eredi igbesẹ yii ko ṣeyin bi ijọba ṣe n kọminu lori bi awọn ọdọ ṣe n lo oogun oloro lọna ti ko ba ofin mu.
Wọn ni igbesẹ ayẹwo naa ni yoo tẹle awọn alakalẹ kan ti ijọba ti kọkọ kede rẹ ninu ọdun 2025.
Awọn ọmọ Naijiria ni o yẹ ki ijọba ṣeyẹwo oogun oloro fawọn oloṣelu ṣaaju iburawọle wọn lẹyin eto idibo
Ti ẹ ko ba gbagbe, ninu oṣu kọkanla ọdun yii ni ileeṣẹ to n ri si wọlewọde ni Naijiria NCS, sọ pe gbogbo awọn oṣiṣẹ tuntun atawọn to ti wa lẹnu iṣẹ tẹlẹ gbọdọ ṣe ayẹwo oogun oloro lọna ati le ṣiṣẹ wọn bo ṣe tọ ati bo ṣe yẹ.
Bakan naa ni aṣẹ kan ti kọkọ jade ninu oṣu Keje pe ki wọn ṣayẹwo awọn akẹkọọ fasiti fun oogun oloro lilo.
Awọn igbesẹ wọnyii n ṣafihan pe ijọba apapọ ko ṣere ninu afojusun rẹ lati gbogun ti oogun oloro lilo ni Naijiria.
Wayi o, awọn ọmọ Naijiria kan ti n beere pe o yẹ ki ijọba maa ṣeyẹwo oogun oloro fun awọn oloṣelu naa, paapaa ṣaaju eto idibo ati ṣaaju iburawọle wọn lẹyin eto idibo.















